Fásitì BOUESTI jáwè ẹ lọ gbélé yín fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó na akẹgbẹ́ wọn, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

BOUESTI

Oríṣun àwòrán, Mistura ADEJUWON/Precious OLANREWAJU

Awọn alaṣe fasiti Bamidele Olumilua to wa niluu Ikere-Ekiti, BOUESTI, ti jawe ẹ lọ gbele yin fun akẹkọọ meji lori ẹsun pe wọn din dundun iya fun akẹgbẹ wọn kan.

Ṣaaju ni fidio bi wọn ṣe n fiya jẹ akẹgbẹ wọn naa, Gloria Ajayi ti oun naa jẹ akẹkọọ fa ori ayelujara ya.

Fidio ọhun ṣafihan bi ẹni ti ọrọ naa ṣi mọ lori, Opemiposi Precious Bolaji ṣe n na Gloria ninu ọgba ile wọn lagbagbe fasiti ọhun.

A gbọ pe akẹkọọ imọ Mass Communicaiton ni gbogbo awọn akẹkọọ naa jẹ.

A ti le awọn to fiya jẹ akẹgbẹ wọn lọna aitọ kuro nile ẹkọ wa – BOUESTI

Ẹwẹ, ninu atẹjade kan ti alukoro ile ẹkọ ọhun, Temitope Akinbisoye fi lede, o ni awọn ko faye gba irufẹ iwa bẹẹ, awọn si ti fi iya to tọ jẹ awọn ti ọrọ ọhun ṣi mọ lori.

O ni “gẹgẹ bii ofin ile ẹkọ wa, awọn akẹkọọ to wa ninu fidio naa ti farahan niwaju igbimọ to n da seria fun awọn to ba ṣe labẹ ofin wa lọjọ kẹfa, oṣu Karun un, ọdun 2024 fun iwadii, a si ti fi esi iwadii to awọn alaṣẹ leti.

“Awọn alaṣẹ fasiti wa koro oju si iwa ipa si ẹnikẹni lati ọwọ eyikeyin akẹkọọ nitori iwa bẹẹ lodi si ohun ti ile ẹkọ wa duro fun.

“Omidan Opemiposi Precious BOLAJI to ni nọmba iforukọsilẹ 10232, to jẹ akẹkọọ imọ Mass Communication ti a ri to n fi igi na akẹgbẹ rẹ ninu fidio naa, to si tun dunkoo mọ lori ẹsun pe o da ibaṣepoọ oun ati ọrẹkunrin oun ru ki ṣe ọmọ ile ẹkọ wa mọ nitori a ti jawe lọ gbele ẹ fun lati akoko yii lọ.

“Omidan Genesis OSARO, pẹlu nọmba iforukọsilẹ 10257 ni ẹka imọ Mass Commmunication naa kii ṣe akẹkọọ wa mọ lati akoko yii lọ nitori a ti jawe lọ gbele ẹ fun latari pe oun lo pese ẹgba ti wọn fi na Gloria Ajayi.

“Ni ti Omidan Gloria Ajayi, ko ni jiya kankan nitori ko gbe ọwọ soke lasiko ti wọn n da ajọ iya fun.

Alukoro ile ẹkọ sọ siwaju si pe awọn tun ti fa awọn meji mii Mistura Eniola ADEJUWON ati Precious Oluwapelumi OLANREWAJU leti nitori wọn ko na Gloria ṣugbọn awọn lo ka iṣẹlẹ naa silẹ pẹlu foonu wọn.

Lẹyin naa lo rọ ẹnikẹni to ba n la irufẹ ijiya tabi idunkokomọni bẹẹ kọja nile ẹkọ ọhun ko fi to awọn alaṣẹ leti.

A ti bẹrẹ iwadii – Ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti

Wayi o, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti sọ pe awọn mọ nipa iṣẹlẹ idunkokomọni ati ifiyajẹni naa, awọn si ti bẹrẹ iwadii.

Ninu atẹjade ti alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu fi lede, o ni kọmiṣọna ọlọpaa Akinwale Kunle Adeniran ti paṣẹ ki wọn ṣiṣe papọ pẹlu awọn alaṣẹ fasiti naa ki gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ le foju wina ofin.

Ọlọpaa pari ọrọ rẹ pe ki awọn araalu maṣẹ fi ofin sọwọ ara wọn, ki wọn si gba ileesẹ naa laaye lati ṣe iwadii iṣẹlẹ ọhun bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.