Ìjọba àpapọ̀ fòfin de abẹ́rẹ́ tí wọ́n kó wọlé láti òkè òkun láwọn ilé ìwòsàn Nàìjíríà

Needle

Oríṣun àwòrán, getty images

Ijọba apapọ ti fofin de lilo abẹrẹ ti wọn ko wọle lati oke okun lawọn ile iwosan ijọba ni Naijiria.

Ọrọ yii lo jẹyọ ninu atẹjade kan ti minisita abẹle fun eto ilera, Dokita Tunji Alusa fi lede.

Ijọba ti wa paṣẹ fun gbogbo awọn adari ile iwosan, CMDs ati MDs lati maa ra abẹrẹ ti wọn ṣe ni Naijiria nikan.

Atẹjade naa fi kun abẹrẹ ti wọn yoo maa ra gbọgọ jẹ lati ọwọ awọn ileeṣẹ ti ajọ NAFDAC fontẹ lu.

Tunji Alausa ni igbesẹ naa ko ṣẹyin afojusun ijọba apapọ lati ṣatilẹyin fun awọn ileeṣẹ abẹle ni Naijiria.

Ẹwẹ, ijọba tun ti ke si NAFDAC lati dẹkun ati maa fontẹ lu awọn abẹrẹ ti wọn n ko wọle lati oke okun, ko tun fopin si fifun awọn eeyan ati ileeṣẹ ni iwe aṣẹ kiko abẹrẹ wọle lati ilẹ okere.

Alausa ni kii ṣe iṣoro kekere lawọn ileeṣẹ to n ṣe abẹrẹ naa labẹle n dojukọ.

O ni pupọ ninu awọn ileeẹ to n ṣe abẹrẹ ọhun ni Naijiria lo ti kogba wọle latari awọn ayederu abẹrẹ ti awọn oniṣowo kan n ko wọle lati oke okun.

Dokita Alausa sọ siwaju si pe “Aarẹ ti paṣẹ pe gbogbo nnkan wọnyi gbọdọ dopin.

“A ti fẹnuko pe a ni lati gbe igbesẹ akọni lọna ati yanju iṣoro naa ni kankan.

“Fun idi eyii, a ti paṣẹ fun NAFDAC lati dẹkun ati maa fun awọn eeyan laṣẹ ati maa ko abẹrẹ wọle lati oke okun.

“Ajọ naa tun gbọdọ fofin de gbogbo awọn ileeṣẹ to n ko abẹrẹ wọle lati akoko yii lọ.”