Kí ni àjọṣepọ̀ tó wà láàrín Iyemọja, Ẹ̀fẹ̀ àti Gẹ̀lẹ̀dẹ́ tó fi di òun tí gbogbo àgbàyé ń pé wò nílùú Ibara

Àkọlé fídíò, Kí ni àjọṣepọ̀ tó wà láàrín Iyemọja, Ẹ̀fẹ̀ àti Gẹ̀lẹ̀dẹ́ tí gbogbo àgbàyé ń pé wò
Kí ni àjọṣepọ̀ tó wà láàrín Iyemọja, Ẹ̀fẹ̀ àti Gẹ̀lẹ̀dẹ́ tó fi di òun tí gbogbo àgbàyé ń pé wò nílùú Ibara
Aworan ajodun naa

Ọdun Gẹlẹdẹ Ẹfẹ ati Yemọja jẹ ọdun pataki ni ilu Abẹokuta.

Ọpọlọpọ awọn eeyan kaakiri agbaye lo si maa n wa si ibẹ.

Igbagbọ awọn to n ṣe ajọdun yii ni peohunkohun ti eeyan ba beere lasiko ajọdun naa lo maa n wa si imuṣẹ.

Iyalaje ilu Ibara, Oloye Bọlanle Tinubu ṣalaye fun BBC pe abiyamọ ni Iyemọja ilu Ibara to si jẹ wi pe awọn ẹdun ọkan awọn to ba wa si idi rẹ ni o maa n ṣe.

O ni lara eewọ ati awọn ohun ti Iyemọja ko fẹ ni ẹgbin ati iwọsi.

Aṣọ funfun si ni awọn to n bọ ọ maa n saba n wọ lasiko ti wọn ba n ṣe ọdun rẹ.

Ki ni ajọṣepọ , Iyemọja, Ẹfẹ ati Gẹlẹdẹ?

Aworan ere oriṣa naa

Gẹgẹbi ọrọ ti ọkan lara awọn to wa fun ọdun yii sọ, tọkọ tiyawo ni Ẹfẹ ati Gẹlẹdẹ. Oju ọmọ lo pọn wọn de ọdọ Iyemọja. Nibẹ ni wọn si ti jẹjẹ fun Iyemọja pe bi o ba le ṣe e ti awọn ri ọmọ bi, nigbakugba ti wọn ba n ṣe ọdun rẹ, ọkọ oun ni yoo maa kọrin ti oun yoo si maa jo.

Gẹlẹdẹ bimọ, gẹgẹbi adehun, nigbakugba ti wọn ba wa n ṣe ọdun Iyemọja, Ẹfẹ to jẹ ọkọ Gẹlẹdẹ yoo maa kọrin, Gẹlẹdẹ iyawo rẹ yoo si maa jo.

“Orin ti Ẹfẹ ba wa da yẹn ni wọn yoo maa kọ tẹle Gẹlẹdẹ kaakiri ti yoo fi jo fun ọjọ meje ni ilu Bara.”

Lẹyin eyi ni awọn agbaagba yoo gbe ifa janlẹ lati mọ boya ijo naa ti to abi ki wọn tẹsiwaju.