Inú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ ni mo ti gba ìpè orin ẹ̀mí kíkọ-Akintibu Yetunde

Àkọlé fídíò, Inú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ ni mo ti gba ìpè orin ẹ̀mí kíkọ-Akintibu Yetunde
Inú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ ni mo ti gba ìpè orin ẹ̀mí kíkọ-Akintibu Yetunde

Gbajugbaja olori ẹmi, Akintibu Yetunde ni ijamba ọkọ mẹrin ọtọtọ ni oun ni, ti wọn si ṣekoba nla fun bi o ṣe di ẹni ti ko le fi ẹsẹ mejeeji rẹ rin mọ.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, Akintibu ni ọdun 2008 ni oun kọkọ ijamba ọkọ akọkọ, eyi to kan egun ẹyin rẹ.

O ni awọn obi oun sapa lati ri pe oun fẹsẹ rin pada sugbọn ko si agbara owo lasiko naa.

“A ko ri oluranlọwọ, ara mi bẹrẹ si ni ra ni ile iwosan, ara mi bẹrẹ si ni jẹrẹ mọ ibẹ.

“De bi pe idin n jade lara mi, ti awọn dokita ti sọ pe nnkan ti yoo pa ni eleyi.”

O tẹsiwaju pe igba ti iṣẹlẹ naa kọkọ ṣẹlẹ, o ni oun banujẹ pupọ, to si jẹ nnkan to fa irẹwẹsi ọkan fun un.

O ni oun ti oun ti n fi ẹsẹ rin tẹlẹ wa di ẹni ti ko le fẹsẹ rin mọ.

“Yetunde wa di ẹni to ti ko le rin, pẹlu bi mo ṣe maa n ṣe akitiyan kaakiri, mo wa di ẹni to n lo kẹkẹ.

“Mo ro pe n ko le ba ẹgbẹ pe lia mọ pe emi yoo ba ẹgbẹ pe, ma tun ju ẹgbẹ lọ.”

Akintibu ni kọ rọrun ki eeyan ma kọ orin lori ijoko sugbọn oun ni ore ọfẹ Ọlọrun.

“Igba ti mo kọkọ bẹrẹ iṣẹ orin lori kẹkẹ yii, ọdun kinni, ikeji, o kọkọ jẹ nnkan ibanujẹ fun mi, nnkan inira sugbọn igba to ya, mo ri pe nnkan to n fun mi laayọ ju gan ni iṣẹ orin kikọ.

“Inu mi maa n dun ki ma kọrin nitori o rọ mi lọrun gan bi mo ṣe wa lori kẹkẹ lati kọrin.”

Aworan

Oríṣun àwòrán, Akintibu Yetunde