‘Gbèsè bí i N20million ni ìṣubú Naira kó mi sí, kódà mo ta ilé àti dúkía’

Ọrọ kanlẹ, kan baale, to ba ya yoo kan jẹjẹ mi ni mo jokoo mi.
Bẹẹ gan-an ni nnkan ri fun awọn eeyan to n gbe ni orilẹ-ede Benin Republic, paapaa awọn to n gbe, to si n ṣe owo ni awọn ilu to wa ni ẹnubode orilẹ-ede naa pẹlu Naijiria.
Benin Republic jẹ ọkan lara awọn orilẹede to yi Naijiria ka, ti ọrọ aje si so awọn mejeeji papọ.
Koda, kekere kọ ni awọn ọmọ Naijiria to n gbe ni Benin Republic.
Ileeṣẹ iroyin BBC ṣe abẹwo si orilẹ-ede naa, to si ba awọn eeyan sọr ni awọn ilu bii
Awọn oniṣowo bii irẹsi, nnkan mimu, ati bẹẹ bẹẹ lọ sọrọ lori wahala ati idaamu ti owo Naira ti Naijiria n na, ṣe ja walẹ mu ba ọrọ aje ati igbeaye wọn.
Lara awọn to ba wa sọrọ, Ọgbẹni Mepagbe Brasil, sọ pe ṣaaju kii Naira to sọ iyi rẹ nu, oun ma n ta to igba apo irẹsi lojumọ, ṣugbọn ni bayii, agidi ni oun fi n ta ogoji.
Bakan naa ni Arabinrin Balikis Oguntoyin, to jẹ oniṣowo nnkan mimu ẹlẹrindodo, sọ pe oun kii jẹ ki owo Naira ti awọn onibaara ba fi ra ọja lọwọ oun lo kọja iṣẹju marun-un.
O ni kiakia ni oun ma n paarọ rẹ si CFA.
“To ba ju iṣẹju marun-un lọ, gbese ni ma a jẹ.
Ẹlomiran to jẹ oniṣowo paṣi-paarọ owo, Ọgbẹni Alao Abdullateef, sọ pe niṣe ni oun ta ile ati awọn dukia miran lati san gbese ti Naira ko oun si.
O ni 140CFA ni eeyan o fi gba 350,000 Naira.
Ni ilu Owode-Apa, to jẹ ilu to kangun si Benin Republic ni Naijiria, awọn oniṣowo sọ pe ko si ọm naijiria to n ra ọja lọwọ awọn mọ.
Wọn ni Benin ni ọpọ awọn onibaara awọn ti n wa bayii.
Bakan naa ni wọn sọ pe awọn to n gbe ni orilẹede ọhun lo n jẹ anfaani iṣubu Naira julọ, nitori pe owo CFA kekere ni wọn fi n gba obitibi Naira, ti wọn ba wa ra nnkan.





