Mọ̀ nípa Bassirou Diomaye, ọ̀dọ́mọkùnrin tó gba ọgbà ẹ̀wọ̀n di ààrẹ tuntun ní Senegal

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Natasha Booty
- Role, BBC News
Ajọ eleto idibo ni orilẹ-ede Senegal, ti kede ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako, Bassirou Diomaye Faye, gẹgẹ bi aarẹ tuntun ti ilu dibo yan.
Ọjọ Aiku to kọja ni eto idibo aarẹ waye ni Senegal, lẹyin ti Aarẹ Macky Sall ti kọkọ gbiyanju lati sun idibo ọhun siwaju nigba to yẹ ko waye ninu oṣu Keji, eyi to fa iwọde ati ifẹhonuhan laarin awọn araalu, ti eeyan mẹta si ku.
O le ni ida mẹrinlelaadọta ibo ti Faye ni, ti Olootu ijọba nigba kan, Amadou BA, ti ẹgbẹ oṣelu to wa nipo lọwọlọwọ, si ni ida to le diẹ ni marundinlogoji.
Ọgbẹni Faye sọ pe pẹli irẹlẹ ati igbogun ti iwa ibajẹ, ni oun yoo fi dari orilẹede Senegal.
Bakan naa lo ni oun yoo mojuto airiṣẹ ṣe laarin awọn ọd, to fi mọ ọwọngogo ọja.

Taa ni Bassirou Diomaye Faye, ẹni ọdun mẹrinlelogoji to di aarẹ ni Senegal?
Idagbasoke Bassirou Diomaye Faye ninu oṣelu ni o jẹ ohun iyalẹnu fun ọpọ.
O lo ọpọ oṣu lọgba ẹwọn pẹlu afọbajẹ, Ousmane Sonko, ti awọn mejeeji si kuro lọgba ẹwọn ni o ku ọsẹ kan ti eto idibo aarẹ fẹ waye.
Ni bayii, 'Ọ̀gbẹ́ni Clean', orukọ ti awọn eeyan tun n pe, gbọdọ bẹrẹ iṣẹ lati mu gbogbo ileri to ṣe wa si imusẹ fun araalu.
Ọjọ Aje ni Bassirou Diomaye Faye ṣe ayẹyẹ ọjọ bi ọdun mẹrinlelogoji.
Ọpọ igba ni Faye ma n ṣe iranti akoko to lo ni ilu rẹ, Ndiaganiao, nibi to ni oun ma n lọ ni gbogbo ọjọ Aiku lati sisẹ lori oko rẹ.
Ifẹ ati ọwọ to ni fun igbeaye abule rẹ ṣe ọpọlọpọ anfaani fun un ninu sise oṣelu.
“Ko ṣe minisita ri, ko bawọn da si nnkan, fun idi iye ọpọ awọn eeyan lo ti bu ẹnu atẹ lu iriri rẹ nipa oṣelu,” Alioune Tine sọ fun BBC.
Gbigbe ogun ti di isẹ, ifiyajẹni ati iwa ibajẹ lo lewaju ninu awọn erongba ijọba Faye.
Nigba to n sisẹ pẹlu ẹka okoowo, nibi to ti n gba owo ori, oun ati Sonko da igbimọ silẹ lati koju iwa ibajẹ silẹ.
Afẹfẹ gaasi, eporọbi, pipa ẹja ati ipese aabo ni ijọba gbọdọ ṣe amojuto lati le pese igbeaye to rọrun fun awọn eeyan Senegal, Faye salaye.
Aarẹ tuntun ti wọn sẹsẹ dibo yan ni oun yoo ṣe atunṣe si owo CFA lati le fi ẹgbẹ kẹgbẹ pẹlu owo Euro.
Faye fẹ paarọ rẹ pẹlu owo Senegal tuntun tabi owo tuntun fun orilẹede iwọ oorun ni Afrika, bo tilẹ jẹ pe ko le rọrun.
“Yoo ni lati koju awọn nnkan, paapa nipa owo iṣuna sugbọn mo ri pe o ni ọpọlọpọ erongba ,” Olootu ijọba tẹlẹri, Aminata Toure to wa ninu ijọba Aarẹ to fẹ kogba wọle Macky Sall, sọ fun BBC
Pipese isẹ fun awọn ọdọ ati ominira fun ẹka idajọ ni o jẹ nnkan mii ti Faye ṣe ileri pe oun yoo ṣe fun araalu – eyi ti Ms Toure sọ pe Aarẹ Sall kọ lati kọ bi ara si.
Toure nikan kọ lo kede atilẹyin fun aarẹ tuntun to jẹ ọdọ, Aarẹ tẹlẹ, Abdoulaye Wade naa ṣe bẹẹ ni o ku ọjọ meji ti eto idibo yoo waye.
Ayipada nla ree fun Faye, ẹni to lo oṣu mọkanla lọgba ẹwọn fun awọn ẹsun kan ati ọpọlọpọ ọdun ko to wa bọ ori ipo.

Oríṣun àwòrán, AFP
'Emi ni Bassirou'
Bassirou Diomaye Faye ni wọn kede ni oṣu keji gẹgẹ bii oludije, to rọpọ Ousmane Sonko.
“Mo ni lati sọ pe o kuju osuwọn ju mi lọ,” Sonko sọ pẹlu iwuri.
Awọn ọkunrin mejeeji lo jọ da ẹgbẹ oṣelu Pastef silẹ.
Awọn mejeeji jẹ osisẹ to n gba owo ori, ti wọn si jọ lo asiko lọgba ẹwọn lori ẹsun ti wọn ni o lọwọ oṣelu ninu.
Sonko ni ile ẹjọ ni o jẹbi ẹsun meji, eyi to tumọ si pe ko le kopa ninu eto idibo, to fi fun Faye laaye lati dije.
“Emi ni Bassirou,” Sonko sọ fun awọn alatilẹyin laipẹ.
Ohun to waye yii lo fa ti ọpọ alatako fi n sapaejuwe Faye gẹgẹ bii “Aarẹ to ṣeesi de ipo.”
Sugbọn Tine gbagbọ pe awọn okunrin mejeeji yoo mu ayipada si sise ijọba tuntun.
“Boya wọn yoo sisẹ papọ lati koju awọn iṣoro ti awọn olori ilu n koju.
“Sonko jẹ olori nla, ti ko ṣe fidi rẹ janlẹ, olori Pastef, akọni sugbọn awọn mejeeji naa ni a le pe ni akọni.
Nigba kan ri, Faye ko fẹ ni nkankan ṣe pẹlu oṣelu. “Ko si mi lọkan ,” O sọ ni ọdun 2019.















