Mi ò ní tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni lórí èrò láti sún ètò ìdìbò sípò Ààrẹ síwájú

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Senegal, Macky Sall ti ní òun kò kábàámọ̀ kankan pé òun gbèrò láti sún ètò ìdìbò sípò Ààrẹ orílẹ̀ èdè náà síwájú.
Nígbà tó ń bá ikọ̀ ìròyìn BBC sọ̀rọ̀, Sall ní òun kò déédé pinnu láti sún ètò ìdìbò náà síwájú, pé ìfẹnukò àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ lórí ètò ìdìbò náà ni ìpinnu náà.
Ìgbésẹ̀ yìí ló ti ń fa ìfẹ̀hónúhàn káàkiri orílẹ̀ èdè Senegal.
"Mi ò ní tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. Mi ò ṣe ohun tó burú. Mò ń bá a yín sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ, gbogbo ìgbésẹ̀ tí mo gbé ló wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin àti ìlànà orílẹ̀ èdè wa," Ààrẹ Macky Sall sọ.
Èrò Ààrẹ láti fi ọjọ́ kún ọjọ́ tí ètò ìdìbò náà, èyí tó fa ìfẹ̀hónúhàn tó lágbára, ni ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè náà yí padà.
Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kẹta ni ètò ìdìbò náà yóò wáyé lẹ́yìn tí èrò láti sun sí oṣù Kejìlá ọdún kò kẹ́sẹ járí.
Àwọn lámèyítọ́ ń fẹ̀sùn kan Ààrẹ Sall pé ó fẹ́ fi ọgbọ́n sún sáà rẹ̀ lórí ipò síwájú si ni.
Àmọ́ Sall tẹnu mọ pé òun kò ní lo ọjọ́ kan lékún sáà òun kódà bí kò bá sí ẹni tó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò tí yóò wáyé lọ́jọ́ Àìkú.
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni olórí ẹgbẹ́ alátakò, Ousmane Sonko àti olùdíje sípò Ààrẹ ní ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀, Bassirou Diomaye Faye jáde kúrò ní ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ Ààrẹ bojú àánú wò wọ́n.
Sall jiyàn pé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn Sonko àti Faye, tó gbé wọn dé ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ọ̀rọ̀ òṣèlú nínú.
Ààrẹ Sall ń fi ipò sílẹ̀ lẹ́yìn tó lo sáà méjì ní ọ́fíìsì gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ.
Amadou Ba, ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́ta ni ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀, Benno Bokk Yakaar (BBY) fà kalẹ̀ láti fi rọ́pò Sall.















