Wo ilé ẹ̀kọ́ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ń jòkó kàwé lábẹ́ igi ní Kwara

Àkọlé fídíò, Wo ilé ẹ̀kọ́ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ń jòkó kàwé lábẹ́ igi ní Kwara

Àwọn òbí, alágbàtọ́ àti olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ LGEA to wa lagbegba Kankan, ní ìjọba ìbílẹ̀ Asa, ìpínlẹ̀ Kwara, ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún àtúnṣe ilé ẹ̀kọ́ náà.

Ìlú Kankan, Gbago, Igboede àti Budo Isale ń ṣe àmúlò ilẹ ẹ̀kọ́ náà.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí kò ṣe sí yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn àga tó dára ní ilé ẹ̀kọ́ náà.

Ilẹ̀ẹ́lẹ̀ àti abẹ́ igi ni ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń jókòó sí láti kẹ́kọ̀ọ́.

Kankan

Oríṣun àwòrán, bbc

Kankan

Oríṣun àwòrán, bbc

Bákan náà ni ọmọ ṣe ṣorí ní ilé ẹ̀kọ́ Apa-Onimalu àti àwọn agbègbè míì tó yiká.

Olori ile ẹkọ naa, Babatunde Iyabo ṣalaye fun BBC Yoruba pe apapọ akẹkọọ 165 lo wa nile ẹkọ naa amọ o ṣeni laanu pe pupọ ninu wọn ni ko ni ijoko.

Gẹgẹ bii ohun ti a ri nibẹ, ọpọ awọn akẹkọọ lo n kawe lori iyẹpẹ nilẹ, nigba ti awọn mii joko sabe igi lati kọ iwe wọn.

Adari ile ẹkọ ọhun sọ fun BBC pe gbogbo igba ti ojo ba ti bẹrẹ lo maa n pa awọn akẹkọọ ati olukọ papọ.

Arabinrin naa wa ke si ijọba ipinlẹ Kwara lati da si ọrọ awọn akẹkọọ naa ki aye le dẹrun fun awọn ọmọ to n kẹkọọ nibẹ.

Ọkan lara awọn to ti jade nile ẹkọ naa lọpọ ọdun sẹyin sọ pe nnkan bii ọdun 1977 ni wọn ti da ile ẹkọ naa silẹ, ile ẹkọ ọhun ko ni itẹsiwaju kankan lati ọdun naa wa.

Lẹyin naa ni wọn rawọn ẹbẹ si ijọba ko ṣiju aanu wo awọn, ko si tun ile ẹkọ naa ṣe.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti BBC Yoruba ba bọ nile ẹkọ Kankan.