Ohun tá a mọ̀ lórí ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn onímọ́tò ní Ogun rèé

Oríṣun àwòrán, Others
Níṣe ni ọ̀rọ̀ di ẹni orí yọ ó dilé nígbà tí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn onímọ́tò ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Ìròyìn ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ onímọ́tò National Union of Road Transport Workers (NURTW) àti Ogun State Parks Management (OGSPAM) ló ń bá ara wọn fa wàhálà.
Ní àwọn ibùdókọ̀ bíi Lafenwa, Obantoko, Brewery, Ita-Oshin, Odeda àti Kuto ní ìlú Abeokuta, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ogun ni ìjà náà ti wáyé.
Ní ọdún 2021 ni ìjọba ìpínlẹ̀ dá ẹgbẹ́ OGSPAM sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ NURTW ní ìpínlẹ̀ náà.
Àmọ́ nígbà tó di oṣù Kẹwàá ọdún 2023, ìjọba gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tí wọ́n fi de NURTW, tí wọ́n sì ní kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ padà nípa gbígba owó fún ìjọba ní gáréèjì.
Ohun tó fa ìkọlù tó wáyé lọ́jọ́ Ajé gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé Kọmíṣọ́nà fún ètò ìrìnnà ìpínlẹ̀ Ogun, Gbenga Dairo ni kí àwọn adarí ikọ̀ OGSPAM má ja tíkẹ́ẹ̀tì fún àwọn ọlọ́kọ̀ mọ́ àti pé NURTW gba àkóso náà.
Ìgbésẹ̀ yìí ni kò tẹ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OGSPAM lọ́rùn tí wọ́n sì yawọ àwọn gáréèjì lọ́kan-ò-jọ̀kan pẹ̀lú àwọn ohun ìjà lọ́wọ́.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abiodun Alamutu ni àwọn pẹ̀ẹ̀tù sí aáwọ̀ náà àti pé àwọn ti kó àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò sí gbogbo gáréèjì.
Alamutu kò sí èèyàn kankan tó kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí àwọn ìròyìn kan ṣe ń gbe kiri.
Ó ní àwọn ọlọ́pàá ti wà káàkiri láti ri pé ààbò tó péye wà káàkiri ìlú.















