Tinubu ṣèlérí àmì-ẹ̀yẹ ìdálọ́lá àti ẹ̀yẹ ìkẹyìn fáwọn ológun tí wọ́n pa ní Delta

Aare Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale

Aarẹ Bọla Tinubu ti ṣẹleri pe iku awọn ṣọja mẹrindinlogun to sun loju ija ni Okuama, nijọba ibilẹ Guusu Ugheli, ipinlẹ Delta lọsẹ to kọja ko ni i ja s’asan.

Aṣiwaju sọ pe Naijiria yoo fun awọn ologun naa ni ami-ẹyẹ idalọla, yoo si tun gbe eto isinku ẹ̀yẹ ikẹyin ti yoo waye fun wọn.

Aarẹ sọrọ yii lasiko to n ṣinu aawẹ lalẹ Ọjọru, ogunjọ oṣu kẹta 2024 yii, nile ijọba, niluu Abuja.

O ni iranlọwọ ni awọn ologun naa fẹẹ lọọ ṣe fawọn ti wọn nilo rẹ, ti wọn si ṣe bẹẹ dẹni ọ̀run.

’’Ẹ jẹ ka ṣe ohun ti yoo fi han pe a ba wọn kẹdun, a si mọ riri ifi-ẹmi-ẹni jin doju iku ti wọn ṣe fun orilẹ-ede Naijiria.

“ A ki gbogbo awọn ọkunrin atobinrin ninu iṣẹ ologun, a si ba wọn kẹdun.

‘’Mo maa too ṣe awọn ikede mi-in to ba kan, ṣugbọn wọn gbọdọ ni eto isinku ẹlẹyẹ ikẹyin to tọ si wọn pẹlu ami ẹmi idalọla orilẹ-ede yii na.”

Ninu ọrọ tiẹ, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Delta, Olufẹmi Abaniwọnda, sọ pe ileeṣẹ ologun ko ti i fun awọn ọlọpaa laaye lati wọ Okuama ti wahala naa ti ṣẹlẹ.

O ni gbogbo ilu naa ti di ahoro tan, ibẹ da bii agọ idakẹrọrọ ni.

Wo ìbéèrè márùn ún tí àwọn èèyàn ń bèrè nípa ìkọlù ọmọ ogun Najiria àti ìdáhùn rẹ̀

Niger Delta

Oríṣun àwòrán, getty images

Aarẹ ile igbimọ aṣofin Naijiria, Godswill Akpabio ti sọ pe awọn ajagunta lo ṣekupa awọn ọmọ ogun Naijiria nipinlẹ Delta, kii ṣe araalu.

Akpabio lo sọrọ naa niluu Abuja lasiko ti awọn asọfin n jiroro lori iṣẹlẹ ọhun.

Ṣaaju ni aṣofin Edeh Dafinone, to n ṣoju aringbungbun Delta ti kọkọ ni o yẹ ki wọn ko ohun iranwọ ṣọwọ si awọn ti ọrọ naa kan.

Ileeṣẹ ọmọ ogun ni ṣe lawọn to pa awọn ologun naa pa wọn ni ipakupa ti wọn tun yọ ọkan wọn.

Ọpọ ibeere lawọn araalu n bere bayii lori iṣẹlẹ naa, lara rẹ ni pe ta ni awọn ologun naa, awọn wo wo lo pa wọn, ati bẹe bẹẹ lọ.

Awọn ọmọ ẹgbẹ wo lo pa awọn ọmọ ogun naa?

Bo tilẹ jẹ pe ile aṣofin ni o ṣeeṣe ki awọn to pa awọn ologun naa jẹ ajagunta, ileeṣẹ ọmọ ogun ko gba ọrọ naa gbọ wọle rara.

Lootọ ni ileeṣe ọmọ ogun sọ pe oun ko ni gbẹsan ikọlu naa ṣugbọn o ti ti gbogbo ọna to wọ ilu ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Awọn wo ni ologun to ba ikọlu naa lọ?

Orukọ awọn ologun naa ati oye wọn ree:

  • Lt Col AH Ali, the Command Officer, 181 Amphibious Battalion, Nigerian Army,
  • Major SD Shafa (N/13976),
  • Major DE Obi (N/14395),
  • Captain U Zakari (N/16348),
  • Staff Sergeant Yahaya Saidu (#3NA/36/2974),
  • Corporal Yahaya Danbaba (1ONA/65/7274),
  • Corporal Kabiru Bashir (11NA/66/9853),
  • Lance Corporal Bulus Haruna (16NA/TS/5844),
  • Lance Coraporal Sole Opeyemi (17NA/760719),
  • Lance Corporal Bello Anas (17NA/76/290),
  • Lance Corporal Hamman Peter (NA/T82653),
  • Lance Corporal Ibrahim Abdullahi (18NA/77/1191),
  • Private Alhaji Isah (17NA/76/6079),
  • Private Clement Francis (19NA/78/0911),
  • Private Abubakar Ali (19NA/78/2162),
  • Private Ibrahim Adamu (19NA/78/6079),
  • Private Adamu Ibrahim (21NA/80/4795)

Ki ni awọn ọmọ ogun to ku lọ ṣe nilu naa?

Iroyin ni ija kan lo waye laarin ilu Okuama ati Okoloba ti wọn lọ yanju.

Gẹgẹ bii atẹjade ileeṣẹ ọmọ ogun, ilu Okuoma ni wọn lọ lati lọ da alaafia pada nibẹ ki wọn to kọlu wọn.

Ki lo fa ija laarin ilu Okuama ati Okoloba

Lati inu oṣu Kinni, ọdun 2024 ni ija ti n waye laarin ilu mejeji.

Iroyin ni ọrọ ilẹ lo fa ija laarin wọn latari bi awọn eeyan ilu kan ṣe n yẹ ara awọn ilu keji wo lori omi.

Ṣe araalu ba ikọlu ọhun lọ?

Ileeṣẹ ọmọ ogun ni araalu kan ṣoṣo lo ku lasiko rogbodiyan naa amọ ọpọ eeyan lo gbagbọ pe awọn to ku ju bẹẹ lọ.

Ki ni ohun to kan bayi?

Ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Delta lo ti ṣeleri pe awọn yoo ṣewadii iṣẹlẹ naa, ti gbogbo awọn to si lọwọ ninu iku awọn ọmọ ogun Naijiria lọna aitọ yoo foju wina ofin.

Àwọn èèyàn Niger Delta kọ́ ló ṣekúpa àwọn sọ́jà 16 ní Okuama - Akpabio

Awọn sọja to ku

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X

Adari ile aṣofin agba l’Abuja, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio ti sọ pe kii ṣe awọn eeyan ẹkun Niger Delta lo ṣekupa awọn sọja mẹrindinlogun niluu Okuama ni ijọba ibilẹ guusu Ugheli nipinlẹ Delta.

Akpabio sọrọ yii nigba tawọn aṣofin n jiroro lọjọ Iṣẹgun lori iṣẹlẹ iṣekupani awọn sọja to n lọ pẹtu si ija laarin ilu meji nipinlẹ Delta kawọn eeyan kan to dawọn lọna ti wọn si pa wọn.

Ileeṣẹ ologun ti sọ ṣaaju pe awọn ọdọ ilu Okuama lo ṣiṣẹ laabi ọhun, amọ, wọn ni iwadii si n lọ lọwọ lati mu gbogbo awọn to ṣiṣẹ naa.

Sẹnẹtọ Abdulaziz Yar’adua ti ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Katsina lo daba wi pe ki ijọba ṣe iwadii to muna doko lati mu awọn to ṣekupa awọn sọja naa.

Gbogbo awọn sẹnẹtọ lo bẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ naa, amọ, Akpabio sọ fun wọn pe ki wọn maa ti gbagbọ pe awọn eeyan Niger Delta lo pa awọn sọja naa.

‘’Awọn eeyan Niger Delta bọwọ fawọn ẹṣo eleto abo, idi niyi ti a fi gbọdọ ṣe iwadii lati mawọn to wa nidii iṣẹlẹ yii.

O ṣeeṣe ko jẹ wi pe awọn agbenipa lati ilẹ okeere lawọn to ṣiṣẹ laabi yii.

Ki i ṣe wi pe asiko ogun ni a wa, ko si ilu to maa pa iye awọn sọja yii.

A gbọdọ mọ awọn to ṣiṣẹ yii ki wọn si jiya ẹṣẹ wọn’’ Akapabio lo sọ bẹẹ.

A ò ní gbẹ̀san sọ́jà 16 tí wọ́n pa ní Delta, àmọ́... - iléeṣẹ́ ọmogun

Aworan awọn sọja

Oríṣun àwòrán, Nigerian army/X

Ileeṣẹ ọmogun Naijiria ti sọ pe awọn ko ni gbẹsan ṣoja mẹrindinlogun tawọn eeyan kan ṣekupa nipinlẹ Delta lọsẹ to kọja, amọ, awọn maa ri daju pe awọn to ṣiṣẹ laabi yii yoo foju wina ofin.

Alukoro ileeṣẹ ọmogun Naijiria, Ọgagun agba Onyema Nwachukwu, sọ ninu atẹjade to fi sita loju opo X wọn pe kawọn eeyan maa ṣiṣẹ wọn lọ lai bẹru niwọn igba ti wọn ko ba ti wa lara awọn to dẹmi awọn sọja legbodo.

Ọgagun Nwachukwu ni iṣekupani awọn sọja mẹrindinlogun ti wọn n lọ pẹtu si ija laarin ilu Okuama ati Okoloba ni ijọba ibilẹ guusu Ugheli nipinlẹ Delta buru jai, eyi to si yẹ ki gbogbo eeyan bu ẹnu ẹtẹ lu.

‘’Alaafia ati aabo awọn eeyan ẹkun Niger-Delta lawọn sọja ti wọn pa ni ifanna-fanṣu yii n lepa tawọn ọdọ ilu Okuama fi ṣekupa pa wọn.

Awọn ọdọ yii tun ṣa oku awọn sọja naa ni iṣakuṣa, eyi to bani lọkan jẹ gan an.

Ṣugbọn o ṣeni laanu pe afurasi lawọn eeyan ilu Okuama gan an ninu iṣẹlẹ iṣekupani yii,’’ Ọgagun Nwachukwu ṣalaye.

O ni niṣe lawọn eeyan ilu Okuama n parọ fawọn akọroyin lori ohun to ṣẹlẹ dipo ki wọn fọwọ sowọpọ pẹlu ileeṣẹ ọmogun lati fọwọ ofin mu awọn to wa nidi iṣẹlẹ laabi yii.

Ọgagun Nwachukwu ni eyi tumọ si pe awọn eeyan ilu yii mọ si iṣekupani awọn sọja tawọn ọdọ sẹkupa.

Alukoro ileeṣẹ ọmogun sọ pe ko si iru irọ tawọn eeyan Okuama le pa fawọn akọroyin to le da iwadii to n lọ lọwọ duro.

Ẹwẹ, ọgagba ileeṣẹ ọmogun ni Naijiria, Ọgagun Toareed Lagbaja naa tun ṣeleri wi pe ko si ibi tawọn to ṣekupa awọn sọja mẹrindinlogun naa le fara pamọ si ti ọwọ ofin ko ni to.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sáwọn tó pa ṣọ́jà mẹ́rìndínlógún ní Delta

Nigeria Army

Oríṣun àwòrán, getty images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Bọla Tinubu, ti ṣeleri pe awọn eeyan to pa ṣoja mẹrindinlogun nipinlẹ Delta lọsẹ to kọja yii ko ni i lọ lai jiya iwa ika ti wọn hu.

Ninu atẹjade ti Aarẹ fi sita nirọlẹ ọjọ Aiku ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹta 2024 lo ti ṣapejuwe ipaniyan naa bii iwa ika ti ko si idi kan fun lati waye.

Aarẹ Tinubu koro oju si bi ologun mẹrindinlogun to lọọ pẹtu saawọ ṣe pade iku ojiji.

O ni ojo lawọn to pa wọn, ṣugbọn ọwọ yoo ba wọn, wọn yoo si jiya labẹ ofin.

‘’Gẹgẹ bi olori orilẹ-ede,mo ba gbogbo ọmọ Naijiria kẹdun iku awọn ologun to ṣubu loju ija yii, ko si idi kankan fun wọn lati ku iku ti wọn ku yii rara.

‘’Awọn ṣọja to ku ni Okuama yii ti darapọ mawọn akọni ọkunrin atobinrin ninu ologun ti wọn ku nigba ti wọn sin ilẹ baba wọn.

‘’A ko gbọdọ gbagbe wọn, pataki ni iṣẹ tawọn ologun n ṣe lorilẹ-ede.

‘’Mo ba ẹbi atawọn alajọṣiṣẹpọ awọn to doloogbe yii kẹdun. Ileeṣẹ ologun ti n gbe igesẹ lori iṣẹlẹ yii, awọn ojo to ṣeku pa wọn ko ni i lọ lai jiya’’

Bakan naa ni atẹjade Aarẹ Tinubu yii ti fun ti olu ileeṣẹ ologun ilẹ wa laṣẹ lati wa awọn apaayan naa jade pẹlu gbogbo agbara wọn.

Aare Bola Ahmed Tinubu

Ki lohun to fa iku ṣọja pupọ ati araalu kan?

Awon ologun

Oríṣun àwòrán, Getty

Ọjọbọ, ọjọ kẹrinla oṣu kẹta 2024 ni rogbodiyan kan bẹ silẹ laarin awọn ọdọ agbegbe Okhuama ati Okoloba, nijọba ibilẹ Guusu Ugheli, nipinlẹ Delta.

Awọn ṣọja gbera lati 63 Brigade lati lọọ pẹtu si rogbodiyan naa, ṣugbọn awọn ti wọn fẹẹ gbe nija ti dena de wọn, wọn si mu wọn balẹ lojiji doju iku.

Olori ogun kan, Méjọ̀ meji, Kaputeeni kan, awọn ọmọ ogun mejila ati araalu kan ni wọn pa ninu ikọlu naa.

Ki lohun ti ileeṣẹ ologun wi nipa iṣẹlẹ yii?

Ọga ologun, Christopher Musa, ti paṣẹ pe ki iwadii to lọọrin bẹrẹ lori iku awọn eeyan to pade iku ojiji yii.

Bakan naa lo paṣẹ pe ki wọn maa mu ẹnikẹni to ba lọwọ ninu ipaniyan naa.

O fi kun un pe bawọn araalu ba le fa awọn to ṣiṣẹ ibi naa jade, ko si wahala.

Ai le foju wọn han lo le ko idaamu ba gbogbo wọn.

Ileeṣẹ ologun lawọn ti mu awọn eeyan kan lori isẹlẹ ọhun, igbesẹ si ti bẹrẹ lati tu aṣiri to wa nidii ikọlu naa gan-an.

Ijọba ipinlẹ Delta naa sọrọ

Ninu ọrọ tiẹ, Gomina ipinlẹ Delta, Sheriff Oborevwori, ṣeleri lati wa awọn to pa ṣọja wọnyi jade, o ni wọn yoo si jiya to tọ si wọn pẹlu.

Gomina Oborevwori loun ba awọn ẹbi awọn ologun naa kẹdun, o ki wọn ku atẹmọra.