Ìbẹ̀rùbojo gbalẹ̀ lẹ́yìn tí táńkà tó gbé epo 50,000 lítà gbókìtì ní Ilorin

Aworan tanka to ṣubu

Ẹni ori yọ o dile, lọrọ da lana ọjọ Abamẹta ọjọ kẹrindinlogun, ọdun 2024 lopopona Asa Dam, Ilorin, ipinlẹ Kwara lẹyin ti tanka epo kan gbokiti.

Iṣẹlẹ naa fa boolọ yaa mi fun awọn olugbe agbegbe naa nitori wọn n bẹru pe tanka ọhun le gbina lojiji nitori epo inu rẹ to n ṣan danu si titi.

Ṣe ni awọn awakọ wa ọna mii gba lati dena ijamba ọkọ nitori epo to danu naa ti fa ki ona maa yọ.

Bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé

Arakunrin kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, ìyẹn Pasitọ Ọjọmu Idowu salaye fun BBC Yoruba pe ọkọ ayọkẹlẹ kan lo jana mọ ọkọ tanka ọhun lẹnu.

O ni eyi lo mu ki dẹrẹba tanka naa tẹ bureki lojiji lori ere ko ma ba kọlu ọkọ ayọkẹlẹ ọhun, sugbọn kaka ki tanka naa duro, ṣe lo gbokiti to si gbe ẹnu soke yakata.

O fi kun-un pe, bi o ba se ti awọn panapana, o ṣeeṣe ki tanka naa gbina nitori epo to n ṣan danu ati bi oorun ṣe mu kankan.

Alukoro ajọ panapana, Hassan Hakeem Adekunle fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu iwe to fi lede.

Aworan tanka to ṣubu
Aworan tanka to ṣubu

O ni deedee ago kan kọja isẹju mẹwaa ọjọ Abamẹta ọjọ kẹrindinlogun osu kẹta ọdun 2024 ni Ileesẹ awọn gba ipe pajawiri wi pe ọkọ tanka epo kan gbokiti lagbegbe ileẹkọ Eucharistic, Asa Dam.

O ni nọmba ọkọ naa jẹ UDD 155 SA, ti iṣẹlẹ naa jẹ ewu fun ẹmi awọn olugbe agbegbe naa.

Alukoro naa ni lọgan ni awọn ikọ awọn gbera lọ si bẹ ti wọn si n fọn omi si tanka naa ati agbegbe naa lati ri pe ina ko ṣẹ yọ.

O ni isẹ naa jẹ aseyọri pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ọlọpaa, Sifu Difensi, ajọ to n ri si abo opopona ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oga agba Ileesẹ panapana, Ọmọba Falade John rọ awọn awakọ tanka ati awọn iyoku lati maa se pẹlẹ loju popo nitori ẹmi ko laarọ.