Awakọ̀ Kórópe kú sórí ‘steering’ ní Ilorin, ariwo sọ

Oríṣun àwòrán, getty images
Inu ibanujẹ ati ọfọ ni mọlẹbi Lukman, to n fi ọkọ na ọgba Fasiti Ilọrin, niluu Ilorin, wa bayii.
Dẹrẹba naa lo ku lojiji lasiko to n gbe awọn akẹkọọ fasiti Ilorin lati agbegbe Tankẹ lọ si inu ọgba ileẹkọ ọhun.
BBC Yoruba gbọ pe lọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii ni iṣẹlẹ buruku naa ṣẹ nigba ti Lukman n wa ọkọ Korope lọ inu ọgba Fasiti Ilọrin lati agbegbe Tankẹ, to si deede dori kodo ti ko le dari ọkọ naa mọ.
Ki wọn to ṣẹju pẹ ọkunrin naa ti ku patapata.
Bi awakọ naa ṣe dagbere faye
Ọkan lara awọn ero to gbe, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe oun ni oun da ọkọ naa duro.
Nigba to n ṣọrọ gba tori WhatsApp, o ni lati agbegbe Tankẹ Sanrab ni oloogbe ọhun ti gbe awọn to si n gbe awọn lọ si inu ọgba ile ẹkọ ati pe iwaju ni oun joko si.
O ni ṣadede loun ri pe dẹrẹba ti mori lọlẹ lori ere, eyi to mu ki ọkọ maa wọ inu igbo lọ ṣugbọn oun sare tẹ ijanu ọkọ naa to si duro bo tilẹ jẹ pe aya awọn ti ja nigba tawọn ri pe ọkọ ti ya kuro loju ọna.
O ni “Ẹni to wa lẹgbẹ mi lo pe akiyesi mi, to n pariwo baba-baba lera wọn, mo sare fẹṣẹ tẹ ijanu ọkọ, ọkọ naa si duro.
"Wọn sare gbe dẹrẹba naa lọ si ile iwosan nibi ti wọn fidi rẹ mulẹ pe o ti dagbere faye, gbogbo ohun to ṣẹlẹ ko ju ọgbọn iṣẹju lọ.”
Ọkan lara awọn dẹrẹba akẹgbẹ rẹ, Sulyman Malik, Ọjọbọ lo ki oun nipa ijamba ọkọ toun ni laipẹ laimọ pe iku oun funra rẹ gann ti sunmọ etile.
Malik ni wọn ti sin oku ọkunrin naa bayii ni ilana ẹṣin Musulumi.
O fi kun ṣe lara rẹ le koko ti eeyan kan o le sọ pe yoo ku ni ọgbọn ọdun si asiko yii.
Nigba to n ṣọrọ, adari ẹka to n gbe iroyin jade ni Fasiti Ilọrin, Ọgbẹni Kunle Akọgun fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si juwe iṣẹlẹ ọhun gẹgẹ bii eyi to gba omi loju ẹni.
O ni iṣẹlẹ naa mu wa ranti pe, “asan laye.”














