Ṣé lóòtọ́ ni alága NURTW ìpínlẹ̀ Oyo tẹ́lẹ̀ Lateef Akinsola ‘Tokyo’ jáde láyé?

lhaji Lateef Akinsola Tokyo

Oríṣun àwòrán, Mogaji Sikiru Oluwafemi

Alaga ẹgbẹ awọn awakọ, NURTW ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Lateef Akinsola ti ọpọ mọ si Tokyo ti sọ pe irọ ni iroyin to gbode pe oun ti jade laye.

Tokyo funra lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan lori redio abẹle Fresh FM niluu Ibadan laarọ oni ọjọ Aiku.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, alaafia ni oun wa, oun ko tii ku bẹẹ ni mimi kankan ko mi oun.

Ninu ifọrọwerọ naa lo ti dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ atawọn eeyan ipinlẹ Oyo fun bi wọn ṣe n pe oun lori aago lẹyin iroyin iku oun.

O ni iroyin ẹlẹjẹ naa ba awọn mọlẹbi oun ninu jẹ pupọ, o tun rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati tẹsiwaju ninu ṣiṣe atilẹyin fun ijọba gomina Seyi Makinde.

Ki lo mṣẹlẹ ṣaaju?

Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ gbode lọjọ Abamẹta pe ọkunrin ọhun ti fi aye silẹ.

Lẹyin iroyin naa nia gbọ pe ọpọ awọn ololufẹ rẹ yabo ile rẹ to wa lagbegbe Akobo, niluu Ibadan, lati ba awọn mọlẹbi rẹ kẹdun.

Ko pẹ lẹyin naa ti ọkan lara awọn ọmọ rẹ ọkunrin kede pe iroyin ẹlẹjẹ pọnbele ni iroyin ọhun.

Amọ kaka ti yoo fi sọ ẹkunrẹrẹ ipo ti baba rẹ wa, niṣe lo pin fidio kan nibi ti gbajugbaja olorin fuji, Wasiu Ayinde Marshal ti n ki Tokyo.

Ninu fidio naa ni Wasiu ti n sọ pe alaafia ni Tokyo, to jẹ ọkan gboogi lara awọn ololufẹ rẹ wa.

Ẹwẹ, ẹgbẹ NURTW Oyo ko fi atẹjade kankan lede nipa iroyin naa lọjọ Abamẹta.

A gbọ pe ọkan lara awọn olugbe agbegbe Akobo, ti ile Tokyo wa lo fi iroyin naa lede pe o ti jade laye, eyii to mu ki awọn ololufẹ rẹ ya bo ile rẹ.

Lẹyin iroyin naa ni ọpọ araalu bẹrẹ si n sọ eronga wọn nipa ẹni ti ọkunrin ọhun jẹ.