Ṣé lóòtọ́ ni òṣèré tíátà Tunbosun Odunsi ń bèrè ìrànlọ́wọ́ lórí ayélujára?

Tunbosun Odunsi

Oríṣun àwòrán, @baba,amoye

Agba oṣere tiata Yoruba, Olatubosun Odunsi ti sọ pe oun ko fi igba kankan tọrọ owo tabi iranlọwọ lọwọ awọn ololufẹ oun lori ayelujara.

Ọrọ yii lo jade lẹyin ti fidio kan, nibi to ti n bẹbẹ fun iranlọwọ ti gba igboro kan.

Odunsi ti wa sọ pe ẹnikan lo mọọmọ lo fidio naa lati tabuku orukọ oun.

Agba oṣere ọhun, to gbajumọ fun bo ṣe maa sunkun ninu ere ṣalaye pe awọn kan to ṣe ifọwọwerọ fun oun nibi ti wọn ti n ya fiimi lo mọọmọ lo abala kan ninu ifọwọwerọ naa lati jẹ ki awọn araalu gbagbọ pe oun n tọrọ owo.

Odunsi fi kun pe inu oun ko dun si fidio ibi ti oun ti n bere iranlọwọ naa, bẹẹ lawọn ọmọ oun koro oju si fidio ọuhn.

O ni “Mo wa ni Idiroko nibi ti a ti n ya fiiimu, nibẹ lawọn kan bii mẹrin si marun un ti wa ṣe ifọwerọ fun mi, wọn si ni ki n ṣalaye bi mo ṣe maa n ṣe ninu fiimu.

“Ọpọlọpọ ohun to ba mi sọ pọ gan ni, amọ ohun ti mo maa ri ni pe ohun ti wọn gbe jade ni ibi ti mo ti n sọ pe ẹṣaanu mi o, ẹ fun mi lowo.”

Oṣere naa ni gbogbo awọn ọmọ oun lo n pe oun lori aago lori fidio naa nitori pe oun ko ṣaisan ti yoo mu ki oun maa tọrọ owo lori ayelujara.

“Mi o ṣaisan, emi ree, ara mi da.

“O ni oun fẹ ki wọn ranmilọwọ, kii wa ṣe ki n ma sunkun ki awọn le ranmilọwọ.”

“Bi mo ṣe wa yii, mi o ṣaisan, ki awọn eeyan ma ri mi gẹgẹ bii onibara o, agba oṣere ni mi.”

O pari ọrọ rẹ pe ifọwerọ lasan ni oun ṣe amọ ẹni to ṣe ifọrọwerọ naa mọọmọ abala kan nibẹ ti oun ti n sunkun lati ba orukọ oun jẹ, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.