Kókó méje nípa ìgbé ayé Olubadan Olalekan Balogun tó wàjà

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde
Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe Kabiyesi Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Moshood Olalekan Balogun ti waja.
Ile iwosan nla Fasiti ti Ilu Ibadan UCH ni baba dakẹ si lẹyin ti wọn lọ gba itọju fun ailera diẹ.
Lọwọlọwọ taa n ṣe akojọ iroyin yii ni ipalẹmọ ti n tẹsiwaju lati sin Olubadan ni ilana ẹlẹsin musulumi ni ago mẹrin ọsan ọjọ Ẹti.
Bi eleyi ṣe n waye la ni ki a jẹ ki a la ara wa lọyẹ, nipa iru ẹni ti Olubadan jẹ ṣaaju ko to de ori ipo ati lasiko to wa lori oye gẹgẹ bi Kabiyesi ti ilẹ Ibadan.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde
Oloṣelu to pada gun ori aleefa gẹgẹ bi Olubadan
Ọpọ to mọ Kabiyesi Lekan Balogun lo mọ ọ gẹgẹ bii oloṣelu to fi igbakan ri jẹ sẹnetọ lorilẹede Naijiria.
Amọ ṣa o tun jẹ gbajumọ oniṣowo to si n joko gẹgẹ bii ọmọ igbimọ iṣakoso ọpọlọpọ awọn ileeṣẹ okoowo nlanla lorilẹ-ede Naijiria ati loke okun paapaa.
Awọn to baa ṣe ri ṣo pe lẹka wiwa epo rọbi, iṣẹ ọgbin, karakata, iṣakoso ati irinajo afẹ iyan Kabiyesi ko ṣe ko ni kekere ṣaaju ko to dori ipo Olubadan.
Koda o fi igba kan ri ṣe alakaso lọpọlọpọ ẹka ni ileeṣẹ epo rọbi Shell Petroleum Development Company.
Oba Lekan Balogun fi igba kan ri ṣe oluwadi agba ni Fasiti Ahmadu Bello, ABU to wa nilu Zaria.
Lekan Balogun tun jẹ oludari nileeṣẹ iwe iroyin Triumph Newspapers to wa ni Kano; Olootu iwe iroyin oloṣooṣu -The Nigeria Pathfinder pẹlu.
O tun figba kan jẹ olubadamọran nipa akoso lawọn ileeṣẹ bii Leyland, Exite Battery ati Nigerian Breweries.
Gbajumọ onkọwe, ẹlẹyinju aanu ati akọṣẹmọṣẹ ni.
O kẹkọọ gba oye imọ ijinlẹ ọmọwe, ni ẹkọ imọ akoso ilu Public Administration ni Fasiti Columbus International Universit.
Omo Balogun gboye keji Masters degree ni imọ nipa akoso ilu ati awujọ, Public and Social Adminsitration ni Brunel University.
Bẹẹ lo gboye ijinlẹ akọkọ Bsc ni imọ nipa ọrọ aje, Economics ni Fasiti Manchester University, gbogbo rẹ nilu Gẹẹsi.
Ipa rẹ lagbo oṣelu
Lojuna oṣelu, Oloye Lekan Balogun ti figba kan ri gbe igba ibo fun aarẹ lẹgbẹ oṣelu SDP.
O si tun figba kan ri gbe igba ibo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP, bakan naa lo si tun ti di sẹnetọ ri pẹlu.
Nigba to wa ni ile aṣofin apapọ gẹgẹ bii Sẹnetọ to n ṣoju ipinlẹ Ọyọ.
Sẹnetọ Lakan Balogun jẹ alaga igbimọ tẹẹkoto lori aato Naijiria.
O si tun jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn igbimọ tẹẹkoto lori iṣuna, abo ati ọtẹlẹmuyẹ, ọrọ ọlọpaa ati Ologun oriilẹ nile aṣofin agba Naijiria.
Iṣakoso rẹ gẹgẹ bi Olubadan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde
Ọjọ Kọkanla oṣu Kẹta ọdun 2022 ni Gomina Seyi Makinde gbe ọpa aṣẹ fun Oba Mashood Lekan Balogun gẹgẹ bi Olubadan kejilelogoji ti ilẹ Ibadan,.
Kabiyesi alayeluwa, Oba Dr. Moshood Lekan Balogun Alli Okunmade Keji de ori oye lẹni ọdun mọkandinlọgọrin.
Laarin igba to wa lori aleefa, ailera ati jijẹ agba ko jẹ ki araalu foju ri Olubadan pupọ.
Lẹyin awọn ayẹyẹ kookan ti Olubadan ti n yọju fẹẹrẹfẹ si araalu,ọpọ ni ko foju ri Olubadan gẹgẹ bi wọn yoo ti ṣe fẹ.
Amọ lasiko rẹ naa ilu tuba o tuṣẹ paapa laarin awọn oloye.
Lasiko rẹ ni atunṣe ba eto oye jijẹ to mu ki awọn oloye nilu Ibadan gba ade gẹgẹ bi ọba ni agbegbe koowa wọn.
Irọwọrọsẹ ni eto yi fi waye ti ko si mu wahala kankan wa.















