Obìnrin ọmọ Naijiria tí ọ̀gá rẹ̀ fi ṣòwò ẹrú, fipá bá lòpọ̀ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, sọ ìrírí rẹ̀ fún BBC

Oríṣun àwòrán, getty images
Nigba ti Rose fi Naijiria silẹ lọ silẹ Gẹẹsi, o ni ireti igbe aye tuntun nibẹ.
Gẹgẹ bii akọbi ninu awọn ọmọ marun un ti baba rẹ bi, o ni lati wa ọna ti yoo fi gbọ bukata ara rẹ ati idile rẹ lẹyin ti ọja ti baba rẹ n ta run, ti baba rẹ ọhun ko si le tẹsiwaju lati ran nile ẹkọ mọ.
Idi ree to fi gba lati lọ silẹ Gẹẹsi lẹyin ti ẹnikan nile ijọsin wọn sọ fun pe aye wa fun lati lọ silẹ Gẹẹsi nibi ti yoo ti maa ba idile kan tọju ọmọ.
Wọn sọ fun pe mọlẹbi ti yoo ba tọju ọmọ naa ni yoo gbe bukata ile ẹkọ rẹ lọhun ti wọn yoo si tun maa fun ni owo oṣu.
Lẹyin naa lo tẹkọ leti lọ si UK pẹlu iwe irinna oloṣu mẹfa.
Nigba to kọkọ pade mọlẹbi ti yoo ba tọju ọmọ, oni wọn kọkọ ṣe daadaa si oun, amọ lẹyin naa lo ṣakiyesi pe ohun ti oun ba pade yatọ si ohun ti wọn sọ fun oun ni Naijiria.
Rose, ti a fi orukọ bo laṣiri sọ pe tọkọtaya naa mu oun lọ sile ounjẹ wọn, nibi ti oun ti n dana lati aago meje aarọ si marun un irọlẹ.
Ọjọ mẹfa ninu ọjọ meje aarin ọsẹ ni Rose fi n ṣiṣẹ, lọjọ kẹjọ to yẹ ko sinnmi, iṣẹ ile lo maa n fi akoko naa ṣe.
O ni oun ṣiṣẹ bẹẹ fun odidi ọdun kan gbako, lai gba owo oṣu ati lai si ireti kankan pe oun yoo lọ ile ẹkọ.
“Igbe aye inira ni mo gbe”
Gẹgẹ bii ohun ti Rose sọ fun BBC, ko si aye fun lati pe awọn obi rẹ.
O ni “Ti mo ba pe iya mi to si bi mi lere wipe bawo lọhun, ni ṣe ni mo maa parọ fun un pe alaafia ni o wa.”
Nnkan tubọ buru si lasiko ajakalẹ arun Corona latari pe awọn oṣiṣẹ ile ounjẹ naa fi iṣẹ silẹ, to si ku Rose nikan lati maa dana ni gbogbo oru titi di idaji.
Lẹyin ti obinrin to n ṣiṣẹ fun pada si Naijiria, o ni iya oun le kenka si.
“Ọkọ obinrin naa fi iya jẹ mi lọpọ ọna, o maa n bami sun, o tun maa n na mi, bẹẹ lo maa n sọrọ kobakungbe si mi.
“Aimoye igba lo fi ipa ba mi lopọ ti mi o si le ṣalaye fun ẹnikẹni.”
Lẹyinorẹyin, ẹnikan to ṣalaye ọrọ naa fun nile ounjẹ to ti n ṣiṣẹ lo fun ni igboya lati fi ọrọ ọhun to awọn agbofinro leti.
Ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba, Salvation Army, lo doola Rose, ti wọn si fun ni igbe aye tuntun gẹgẹ bii aṣatipo nilẹ naa bayii.
Lati ọdun 2011 ni Salvation Army ti n ṣe iranwọ fun awọn eeyan ti awon kan fi n ṣowo ẹru igbalode.
O le ni eeyan 22,000 ti Salvation Army ti gba silẹ loko ẹru lati ọdun naa wa.
O si ti le ni 3,500 eeyan ti ajọ naa ti gba silẹ loko ẹru igbalode nilẹ Gẹẹsi.














