Wo ọ̀nà tí iléeṣẹ́ ológun America fẹ́ gbà kó oúnjẹ lọ sí Gaza

Oríṣun àwòrán, US Army
- Author, Bernd Debusmann Jr
- Role, BBC News, Washington
Erongba orilẹede America lati maa ṣe iranwọ ounjẹ fun awọn araalu nipa lilo atẹgun lori omi okun yoo koju iṣoro eto abo.
Ọmogun America to le ni ẹgbẹrun kan lo ṣetan lati kopa nínu eto yii.
Lati le ṣe eleyii, America n ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ aladani kan, Fogbow, ti awọn ajagunfẹyinti kan n ṣe agbatẹru rẹ.
Ohun ti America fẹ ṣe ni lati maa fun eeyan miliọnu meji lounjẹ lojoojumọ ni Gaza, lẹyin ti ajọ UN sọ pe iyan le bẹ silẹ laipẹ yii.
Ohun ti a mọ nipa eto ti America fẹ ṣe ni Gaza ree.
Bawo ni America ṣe fẹ ṣe atẹgun lori omi?
Gẹgẹ bi ileeṣẹ ijọba Pentagon ṣe sọ, ẹka meji ni atẹgun yii maa ni - ikinni ni aye to tẹ to si ni oriṣiriṣi ipele ati ọna meji pẹlu atẹgun.
Awọn ọkọ oju-omi akẹru yoo maa n ja ẹru si ori aye to wa lori atẹgun yii.
Níbẹ si ni wọn yoo maa ja ounjẹ si tawon ọkọ akẹru yoo si maa ko ounjẹ naa lọ sí Gaza.
America n ṣegbe lẹyin orilẹede Israel, o si ti kede ẹgbẹ Hamas gẹgẹ bi ẹgbẹ agbesunmomi.
Iru ile atẹgun ori omi, JLOTS, ti America fẹ ṣe yii jẹ iru eyi ti ileeṣẹ ọm'ogun America ti ṣe tẹlẹ ri ni Kuwait, Somalia, Haiti ati Aarin gbungbun America fun iranwọ araalu lasiko ogun.
Koda, ileeṣẹ ologun lo irufẹ JLOTS yii ni Australia loṣu Keje ọdun to kọja.

Ajagunfẹyinti Mark Cancian sọ fun BBC pe ohun ti ileeṣẹ ologun fẹ ni lati ni ibudokọ oju omi to n ṣiṣẹ.
Amọ, o ni o maa n saba nira nitori edeaiyede ati ija to maa n ṣẹlẹ lasiko ogun.
Idi gan an niyii yi tii atẹgun ori omi JLOTS ṣe maa n wulo.
Ki lo n jẹ Fogbow, ipa wo ni yoo ko?
Ọgagun Sam Mundy to n ṣiṣẹ tẹlẹ pẹlu ìkọ Marine Corps lo n dari Fogbow.
O si ti ṣaaju awọn ọmogun lẹkun Middle East ri.
Ọgagun Mick Mulroy ti ajọ CIA tẹlẹ naa n ṣiṣẹ pọ pẹlu rẹ.
A o tii mọ ẹkunrẹrẹ ohun ti wọn fẹ ṣe, amọ, enikan to mọ nipa erongba won sọ fun BBC pe Fogbow ni yoo maa ṣeto ti iranwọ yoo ṣe maa de Gaza lati ori omi.
Fogbow naa si n wa iranwọ owo, wọn si ti kan si awọn ijọba ilẹ Yuroopu kan ati ni ẹkun Middle East lori erongba wọn.
Ki ni ọna abayọ si ọrọ eto abo to mẹhẹ?
Awọn onimọ nipa eto abo sọ pe aṣeyọri eto iranwọ ti America fẹ ṣe ni Gaza da lori eto abo.
Ajagunfẹyinti Mark Montgomery sọ pe eto abo to f'ẹsẹ múlẹ gbọdọ wa lori okun ati leti okun bakan naa.
Ẹwẹ, eeyan meji to mọ nipa erongba Fogbow sọ fun BBC pe ileeṣẹ ọm'ogun Israel yoo gbe igi dina awọn araalu lati maa lọ si eti okun fun iranwọ.
Wọn ni awọn eeyan Palestine ti wọn ko ni nnkan ija oloro lara ni yoo maa wa nidi pinpin ounjẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fogbow yoo kan maa ṣagbatẹru eto iranwọ ounjẹ ni, kii ṣe awọn ni wọn maa pin ounjẹ naa fun araalu.
Ọgbẹni Montgomery ni awọn eeyan yoo gba itọni lori ibi ti ounjẹ yoo maa gba wọle.
O ni wọn maa ni lati wa nibẹ lati le ri pe "bi o ti yẹ ki a ṣe e ni a n ṣe e.
Ti ẹni ti yoo wa lori omi kii ba ṣe ọmogun America, o ni lati ajagunfẹyinti ọmọ America."
Ipa wo ni fifi ọkọ oju-omi ko ounjẹ wọ Gaza yoo ni?
Gẹgẹ bi ileeṣẹ ologun America ṣe sọ, kiko ounjẹ wọle nipasẹ ategun ori omi tumọ si pe eeyan miliọnu meji ni yoo maa ri ounjẹ jẹ lojoojumọ ni Gaza.
Ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni agbẹnusọ ijọba, Matthew Miller sọ pe ijọba n gbero lati maa lo ori omi lati ṣe iranwọ fawọn eeyan ni Gaza.
Amọ, o ni awọn ọkọ tirela to n ko ounjẹ wọle naa ko ni dawọ iṣẹ duro.

Ọna to ya julọ lati mu iranwọ de Gaza si ni ori ilẹ.
Awọn ẹgbẹ alaanu at'awọn oṣiṣẹ orilẹ ede America sọ pe fifi ọkọ oju-omi ko ounjẹ lọ sí Gaza lo le jẹ ki ounjẹ kari awọn eeyan.
Ọgbẹni Montgomery ni awọn gbọdọ wa ọna lati wa ojutuu si iṣoro to n koju awọn eeyan Gaza laarin ọjọ marunlelogoji si asiko yii.
Ohun ti BBC mọ ni pe Fogbow fẹ gbẹ eti okun nibi ti wọn fẹ ṣe ile atẹgun si nibi ti wọn yoo maa ja ounjẹ si t'awọn ọkọ nla yoo si maa lanfaani lati ko ounjẹ lọ fawọn araalu.
Ni bayii, ọkọ ojuomi nla ti orilẹ ede Spain ti o ko igba tọunnu ounjẹ ti ṣetan lati wa lati orilẹ ede Cyprus.















