Èèyàn 61 míì tún kò sọ́wọ́ àwọn ajínigbé ní Kaduna

Aworan afihan bata awọn eeyan to wa nilẹ lẹyin ti ajinigbe ko wọn salọ

Oríṣun àwòrán, AFP

Kaka ki ewe agbọn ọrọ ajinigbe yi dẹ, niṣe lo n ẹ si lorileede Naijiria.

Eyi taa tun ri gbọ bayii ni pe awọn ajinigbe ti ko awọn eeyan mọkanlelọgọta si akata wọn ni ijọba ipinlẹ Kajuru ni Kaduna.

Awọn agbebọn yi yabo ilu Buda lalẹ ọjọ Aje ti wọn si ṣina bolẹ gẹgẹ bi awọn olugbe kan ṣalaye fun BBC.

Amọ awọn alaṣẹ ipinlẹ naa tabi awọn ọlọpaa ko yi ti fi ọrọ kankan sita lori iṣẹlẹ yi.

"Obinrin mejilelọgbọn ati ọkunrin mọkandinlọgbọn lo wa lọwọ awọn ajinigbe"

Awọn ara abule naa sọ pe ni nkan bi ago mọkanla aabọ alẹ lawọn agbebọn yi ja wọ ilu ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn.

''Ko si ẹni to le sọ pato iye awọn agbebọn to wa ko awọn ọkunrin obinrin to jẹ mọkanlelọgọta ti wọn ji gbe''

Bẹẹ ni olugbe agbegbe naa kan ṣe ṣalaye fun BBC.

O ni awọn ri wi pe obinrin mejilelọgbọn ati ọkunrin mọkandinlọgbọn lo wa lọwọ awọn ajinigbe yi.

Koda o ṣalaye pe obinrin kan ti ko ti ju ọjọ mẹrin to bimọ naa wa lara awọn ti wọn ji gbe.

''Wọn gbe iya lọ ti wọn si fi ọmọ rẹ kalẹ''

Àkọlé fídíò, Ekiti Driver‘s Corpse: Kehinde dẹ́rẹ́bà ní wọn ká òun léyín ọ̀ọ́kán, òun kò ní alájọsọ mọ́

O sọ pe awọn agbebọn naa gbero lati ko awọn eeyan to ju bẹẹ lọ amọ ọpẹlọpẹ awọn agbofinro iye eeyan naa ko ba ju bẹẹ lọ.

''Awọn agbebọn naa n ko awọn eeyan lọwọ lawọn agbofinro ni Kajuru bẹrẹ si ni koju wọn pẹlu ibọn.''

Ti kii ba ṣe ọpẹlọpẹ awọn ọmọ ogun, a ko ba le ma mọ iye awọn eeyan ti wọn ba ko.

O ni aitete ri awọn pe lori ago ko sẹyin idẹnukọlẹ opo ikansiraẹniti ko se daada.

Ikọlu Kajuru yi n waye lẹyin ọsẹ kan ti awọn agbebọn yabo ilu Kuriga ni ijọba ibilẹ Chikun nibi ti wọn ti ji akẹkọọ 287.

Kaduna wa lara awọn ipinlẹ to n koju iṣẹlẹ ijinigbepawo lati ọwọ awọn agbebọn.

O tako ofin Naijiria ki awọn eeyan maa san owo itusilẹ fawọn ajinigbe.

Ati ijọba ati awọn agbofinro lo jijọ fẹnuko pe sisan owo yi yoo tubọ jẹ ki ijinigbe pe leke si.

Nǹkan yan! Ajínigbé bèèrè N40trn, ọkọ̀ Hilux mọ́kànlá, ọ̀kadà 150 fún ìtúsílẹ̀ àwọn tó wà ní akátá wọn
Aworan afihan ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Getty

Ara meriri mo ri ori ologbo lori atẹ́ ni iroyin eleyi jẹ.

Awọn ajinigbe to gbe awọn eeyan nipinlẹ Kaduna ti sọ pe triliọnu lọna ogoji Naira lawọn fẹ gba lowo idoola ẹmi, ki wọn to tu awọn eeyan to wa ni akata wọn silẹ.

John Yusuf, to jẹ Seriki abule Gonin Gora lo ṣalaye ọrọ yi Lọjọ Aje fun awọn ileeṣẹ iroyin Naijiria kan.

Ni idahun si ibeere wi pe se o ti gburo awọn eeyan rẹ ti wọn jigbe, John Yusuf sọ pe awọn ajinigbe yi pe lootọ amọ nkan ti wọn beere kọja afẹsnusọ.

Yusuf sọ pe lati igba toun ti gbọnju oun fẹẹ le sọ pe oun ko gbọ iye owo ti awọn ajinigbe yi darukọ tii ṣe ogoji triliọnu Naira.

Yatọ si eleyi, o ni awọn ajinigbe naa tun sọ pe awọn fẹ gba ọkọ Hilux mọkanla ati alupupu tuntun aadọjọ.

''Nibo la ti fẹ ri iru owo yi?Koda bi a ba ta gbogbo abule wa a ko le ri ogoji triliọnu Naira.Koda bi Naijiria ti se loun jẹ orileede wọn ko ti gbe aba iṣuna ogoji triliọnu Naira kalẹ ri''

"Inu igbo lawọn ajinigbe n gba wọ ilu wa"

John Yusuf ke gbajare si awọn alaṣẹ to si ni ẹmeeji ọtọọtọ lawọn ajinigbe yi yawọ abule awọn laarin ọsẹ.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye o ni ''eeyan mẹta ni wọn jigbe ni ikọlu akọkọ. ni igba keji eeyan mẹtala ni wn pada wa gbe ti apapọ eeyan ti wọn jigbe si jẹ mẹrindinlogun.''

O ni igbo kiji to yi awọn ka ni ijọba ibilẹ Birnin Gwari jẹ nkan to mu kawọn wa ninu ewu.

O fikun pe o to asiko to yẹ ki wọn ṣe agbekalẹ ibudo awọn ọmọ ogun lati le dẹkun awọn alaburu yi.

''Ẹbẹ laa n b ijọba ki wọn ṣaanu wa.Lati abule wa titi de Birnin Gwariigbo lo kun iwọn kilomita aadọjọ to yi wa ka.''

Bẹẹ naa lo sọ pe igbo yi kanna lo wa laarin awọn ni Gonin Gora titi to fi de ipinlẹ Niger.

"Ijinigbe tun ti n gbera sọ pada ni Naijiria"

Lọjọru ọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Keji ọdun 2024 ni awọn ajinigbe yabo Anguwan Auta ni Gonin Gora ti wọn si pa eeyan meji ti wọn si ji eeyan mẹta gbe.

Ọjọ mẹrin lẹyin iṣẹlẹ yi ni awọn alaburu yi pada si abule naa ti wọn si ji eeyan mẹtala mii.

Aimọye awọn ọdọ abule yi lo di oju ọna marose Kaduna si Abuja to gba Gonin Gora kọja.

Wọn lawọn ṣe bẹ lati fi ẹhonu han si ijọba lori bi aabo ṣe mẹhẹ.

Yatọ si iṣẹlẹ yi, laipẹ yi ni awọn ajinigbe tun ṣoro ni Kaduna ti wọn si ji eeyan aadọjọ gbe.

Pupọ wọn lo jẹ akẹkọọ ti a si gb pe ṣasa ni idile ti ko ni ọmọ ninu awọn ti alaburu yi jigbe.

Awọn ọdẹ ibilẹ ati awọn ikọ ologun ti n gbiyanju lati wa awọn eeyan to wa ni akata ajinigbe yi.