Wo àwọn ohun tó ń mú ìjínigbé peléke si ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, AFP
Jíjí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn gbé ti tún bẹ̀rẹ̀ padà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Láàárín ọ̀sẹ̀ kan, àwọn agbébọn tí wọ́n ń ṣọṣẹ́ nínú igbó ní ẹkùn àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ló ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀kadà láti fi jí ọ̀pọ̀ èèyà gbé lọ ní ibi méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Ní ọjọ́rú ni ìròyìn jáde ní ìlú kékeré kan ní ìpínlẹ̀ Borno pé àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí alákatakítí ẹ̀sìn Islam yawọ ibùdó tí àwọn èèyàn tí kò nílé lórí mọ́ ti ń ṣàtìpó tí wọ́n sì jí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin àti ọmọdé tó ń wá igi ìdáná gbé lọ.
Ó tó ọjọ́ mélòó kan kí ìròyìn náà tó jáde nítorí kò sí ẹ̀rọ ayélujára ní agbègbè náà mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti bà á jẹ́.
Ní ọjọ́ kejì rẹ̀, ìyẹn ọjọ́bọ̀ ni àwọn agbébọn mìíràn tún lọ jí àwọn ọmọdé 280 tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́jọ sí ọdún mẹ́ẹ̀dógún tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní ìpínlẹ̀ Kaduna. Àwọn olùkọ́ náà wà lára àwọn tí wọ́n jí gbé náà lọ sínú igbó.
Àwọn ìròyìn kan ń sọ pé ikọ̀ alákatakítí ẹsin kan ní orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ansaru group tó ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lí al-Qaeda ló wà nídìí ìkọlù náà.
Láti bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn, irú ìjínigbé ọ̀pọ̀ èèyàn báyìí ti lọ sílẹ̀ lẹ́yìn tí ìjínigbé bẹ́ẹ̀ wáyé ní Nàìjíríà fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí ikọ̀ Boko Haram jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tí wọ́n fẹ́ẹ̀ tó 300 gbé ilé ẹ̀kọ́ Chibok ní oṣù Kerin ọdún 2014.
Ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ìjínigbé ọlọ́pọ̀ èèyàn tún ti bẹ̀rẹ̀.
Jíjí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní ìpínlẹ̀ Kaduna ni ìjínigbé tó pọ̀ jùlọ ní ilé ẹ̀kọ́ láti ọdún 2021.
Kí ló fà á tí ìjínigbé tó ń fi ẹ̀mí àwọn ọmọ Nàìjíríà sínú ewu tún gbérasọ báyìí?
A ò lè sọ pé ohun kan pàtó rè é tó fa bí ìjínigbé tí kò jọ ara wọn yìí ṣe wáyé lásìkò kan náà àmọ́ ohun kan tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìṣòro ìjínigbé kò ì tíì kásẹ̀ nílẹ̀.
Bí ìjínigbé náà ṣe wáyé lásìkò tí àwẹ̀ Ramadan ṣe ń bọ̀ lọ́nà le jẹ́ ohun kan pàtàkì tí ó lè jẹ́ okùnfà rẹ̀.
Àwọn tó ti móribọ́ ní àkàtà àwọn ajínigbé sẹ́yìn sọ bí àwọn ajínigbé náà ṣe máa ń pa á ní dandan fún wọn láti máa dáná fún wọn àti láti báwọn ṣe iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ̀ẹ́.
Ìjínigbé láti fi bèèrè owó jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ lẹ́nu ọjọ́ mélòó kan ní orilẹ̀ èdè Nàìjíríà, tó sì jẹ́ pé àwọn ajínigbé máa ń tú àwọn tí wọ́n bá jígbé sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá gba owó náà tán.
Sísan owó ìtúsílẹ̀ kúrò ní àkàtà àwọn àjínigbá jẹ́ ohun tó lòdì sí òfin Nàìjíríà.
Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ SBM Intelligence ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀, èèyàn 4,700 ni àwọn ajínigbé ti jígbé láti ìgbà ààrẹ Bola Tinubu ti gba ipò nínú oṣù Karùn-ún ọdún 2023.
Ìjínigbé láti fi bèèrè owó ti di òwò fún àwọn kan láti fi rí kó owó jọ látàrí àìrajaja ètò ọrọ̀ ajé tó ń bá orílẹ̀ èdè yìí fínra.
Yàtọ̀ sí owó, àwọn ajínigbé máa ń bèèrè fún oúnjẹ, ọ̀kadà, èpò bẹntiro, ọtí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ láti fi tú àwọn èèyàn tí wọ́n bá jígbé sílẹ̀.
William Linder, òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì CIA tó tún jẹ́ olórí iléeṣẹ́ 14 North sọ fún BBC pé ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà tó dẹnu kọlẹ̀ wà lára àwọn nǹkan tó ń fàyè gba ìjínigbé.
Tí Alex Vines tó jẹ́ adarí ètì ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní Chatham House náà sì gbà pé bí gbogbo àwọn nǹkan ṣe ń gbówó lórí ní Nàìjíríà láti bíi oṣù mẹ́fà sẹ́yìn lè fa kí ìjínigbé tún peléke si.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ó ní àwọn ìkọlù tó ń wáyé lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni ó ṣe forí rẹ̀ sọ ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà àti bí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò kò ṣe rí àwọn ajínigbé náà ká lọ́wọ́ kò.
Bí àwọn àgbẹ̀ kò ṣe lè dáko bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ látàrí ìkọlù àti ìjínigbé tí wọ́n ń ṣe sí wọn ní oko wọn wà lára àwọn nǹkan tó mú kí owó oúnjẹ gbẹ́nu sókè ní Nàìjíríà .
Vines ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbègbè yìí ni àwọn agbébọn ti gba ìlú mọ́ ìjọba àtàwọn adarí ìlú lọ́wọ́, tí wọ́n sì máa ń gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn lọ́nà àìtọ́.
Ó wòye pè nígbà tí àwọn agbébọn yìí kò ti rí owó gbà lọ́wọ́ àwọn ajínigbé náà, ó ṣeéṣe kí wọ́n sọ ara wọn di ajínigbé láti fi máa gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn.
Bákan náà ni bí odò Lake Chad ṣe ń súnra kì ní ojoojúmọ́, tí Sahara Desert sì ń fẹ̀ si ń fa ọ̀gbẹlẹ̀, tí àwọn ilẹ̀ kò sí lọ́ràá tó láti fi gbin oúnjẹ tó.
Linder ní èyí wà lára àwọn nǹkan tó fa wàhálà pàápàá ní ẹkùn árèwá. “Èyí wà lára àwọn nǹkan tó ń fa kí àwọn èèyàn máa wá ọ̀nà tí owó yóò máa gbà wọlé fún wọn lọ́nà mìíràn tí ìjínigbé sì wà lára wọn.”
Àwọn agbébọn yìí tún ń lo àǹfàní pé àwọn ẹnubodè Nàìjíríà kò ní ààbò tó péye àti pé ọ̀pọ̀ àwọn inú igbó tó wà ní ẹnubodè ni àwọn ọ̀daràn náà ń lò láti fi ara pamọ́ sí.
Bulama Bukarti tó jẹ́ onímọ̀ nípa aáwọ̀ ní iléeṣẹ́ Tony Blair Institute for Global Change ní Nàìjíríà nílò láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè tó yi ká.
Ó ní tí kò bá sí àgbọ́yé àti àjọsọ láàárín Niger, Cameroon, Chad àtàwọn míì, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí yóò túnbọ̀ tẹ̀síwájú ní Nàìjíríà.
Ó fi kun pé ìjọba Nàìjíríà nílò láti máa fi àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ lórí ìjínigbé báyìí jófin kí ó lè jẹ́ ẹ̀kọ́ fún àwọn mìíràn.















