Ìyàwó àti ọmọ tí mo pàdánù lọ́wọ́ ààrùn onígbá méjì ló ṣòkùnfà ìdánilẹ́kọ̀ tí mò bẹ̀rẹ̀ f'aráàlú-Abubakar Wakala

Àkọlé fídíò, Mọ̀lẹ́bí tí mo pàdánù lọ́wọ́ ààrùn onígbá méjì ló ṣòkùnfà ìdánilẹ́kọ̀ tí mò bẹ̀rẹ̀
Ìyàwó àti ọmọ tí mo pàdánù lọ́wọ́ ààrùn onígbá méjì ló ṣòkùnfà ìdánilẹ́kọ̀ tí mò bẹ̀rẹ̀ f'aráàlú-Abubakar Wakala

Agbẹ ẹni ọgọrin ọdun ni Abubakar Wakala to si n gbe ni ilu Kinder ni ipinlẹ Sokoto.

Lọdun 2021 ni ibanujẹ dori agba rẹ kodo lẹyin to padanu ọmọ akọbi rẹ ati iyawo rẹ.

Iku awọn mejeeji yi lasiko ojo da ọgbẹ nla si ọkan Abubakar.

Ṣadede ni ọmọ rẹ ọkunrin yi bẹrẹ si ni yagbẹ gbuuru tio si n bi bakan naa.

Apẹrẹ ohun to ṣe si ni aarun onigba meji.

Ki wọn to gbe de ile iwosan ẹmi bọ lara rẹ.

Iru apẹrẹ yi naa lo farahan lara iyawo rẹ ti wọn si fura pe onigba meji lo mu ẹmi tiẹ naa lọ.

Ni abule ti wọn n gbe ọpọ a maa ṣe ibẹrẹ ni ita gbangba ti ko si fi tara tara si omi ibuwẹ bumu to peye nibẹ.

Tohun ti pe wọn ni ile igbọnsẹ ni ile wọn, Abubakar loun fura pe ai si imọtoto to peye ṣokunfa kiko aarun onigba meji ti o si mu ẹmi awọn ololufẹ rẹ lọ.

Fun idi eyi lo bẹrẹ ipolongo lọwọ ara rẹ to si n gba awọn ara abule rẹ niyanju lati ṣe amojuto aaye igbọnsẹ wọn ati imọtoto to peye.

Abubakar sọ pe ko wu oun lati ri ki idile miran kagbako ibanujkẹ iru eleyi to de ba oun yi.

O ni tori rẹ loun ṣe gbe igba ipolongo ati idanilẹ fun awọn araalu to ku lori aburu aarun onigba meji.

‘’Nigba mii ti mo ba da wa laarin oru, niṣe ni mo maa ma ronu nipa iyawo mii ati akọbi ọmọ mi.O maa n ba ọkan mi jẹ pupọ.Nibi ọjọ ori mi de bayii, mi o le fẹ iyawo mii mọ. Akọbi ọmọ mi ti yoo si ṣe itọju mi loun naa ti fo sanlẹ ku yi.’’