Ogun Cholera: Ọdọọdún ni àrùn onígbá-méjì máa n ṣọṣẹ́ ní Nàìjíríà -NCDC

Àkọlé fídíò, Ogun Cholera: Ọdọọdún ni àrùn onígbá-méjì máa n ṣọṣẹ́ ní Nàìjíríà-NCDC

Arun onigba-meji ni awọn miran n pe ni arun maa ya igbẹ ọọrin- ko-tun-maa-bi.

Ajọ to n mojuto itankalẹ aarun ni Naijiria, NCDC fidiẹ mulẹ pe ọdọọdun lo n ṣẹlẹ.

Bayii, ijọba ipinlẹ Ogun ti kede pe o ti bẹ silẹ nibẹ ni eyi to ti mu ẹmi eniyan marun un lọ.

Dokita Ayinde Akinsanya to jẹ akọwe agba fun ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun to n ri si eto ilera ṣalaye fawọn akọroyin ni ọjọ Ẹti pe, Obinrin kan ni iṣẹlẹ akọkọ ti wọn kẹfin.

O ni obinrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa ra irẹsi ati omi tutu ni ọja Kutọ to ti n ta ọja ṣugbọn Abule Ọtun ni Lafẹnwa to n gbe ni wọn ti sare gbee lọ sile iwosan

ogun

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Ọdọọdún ni àrùn onígbá-méjì máa n ṣọṣẹ́ ní Nàìjíríà -NCDC

Wọn ni iṣẹlẹ arun onigba-meji yii ti ba eniyan mejila ni ipinlẹ Ogun ni eyi to ti mu ẹmi ẹni marun un lọ ti awọn to ku n gba itọju nile iwosan.

Dokita Ayinde ni iwadii n lọ lọwọ ati igbesẹ lati dẹkun itankalẹ arun naa ni ipinlẹ Ogun.

Ki arun yii ma baa maa gba ẹbọ lọwọ koowa ni BBC Yoruba ṣe lọ ṣe iwadii ilanilọyẹ ninu fọnran yii ki onikaluku le gbogun ti iwa idọti ni agbegbe wa.

Kete ti o ba ti kẹfin arun yii ni agbegbe rẹ ni ki ẹni naa ti tete gba ile iwosan lọ fun itọju to peye.