Alápatà fi ìbínú lu ìyàwó rẹ̀ pa ní Ogun

Oríṣun àwòrán, Ogun State Police Command
Alápata kan ti orúkọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Sina Kasali ti wọ ihámọ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó lu ìyàwó rẹ̀ pa ní Agbado, Ijọba Ibílẹ̀ Ifo ní Ìpínlẹ̀ Ogun.
Nọọsi ni wọ́n pé ìyàwó rẹ̀ náà Sherifat tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní Ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ wipe Kasali jẹ́wọ́ wípé òótọ́ ni oun lu ìyàwó oun ni ọjọ́ Àbámẹ́ta tó kọ́já lórí ẹ̀sùn pé òun wó àwọ̀tẹ́lẹ̀ àṣẹ́wó kan to jẹ́ alábàágbé wọn.
Wọ́n fi ẹ̀sùn kan Kasali wípé ó lù ìyàwó rẹ̀ títí tó fi dákú. Ọlọ́pàá ní Kasali ko jẹ́ ki Sherifat lọ gba ìtọ́jú lẹ́yin ìjà náà.
Àwọn alábàágbé Kasali ní nígbà tí wọ́n ri pé arábìnrin náà ti kú, wọ́n so arákùnrin náà mọlẹ̀ titi ti wọ́n fi pe ọlọ́pàá tó wá mu.
A gbọ́ pé wọ́n ti jẹ́ tọkọtaya fún ọdún mẹ́wàá kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó ṣẹlẹ̀.









