BBC 100 Women: Obìnrin tí o lasẹ lórí kí ọkùnrin fẹ ìyàwó kejì

Aworan Nenney Shushaidah

Oríṣun àwòrán, Joshua Paul for the BBC

Àkọlé àwòrán, Agbára mi lè fún ọkunrin Malaysia laaye lati fẹ iyawo keji
    • Author, Lati ọwọ Heather Chen
    • Role, BBC News, Shah Alam, Selangor, Malaysia

Ti wọn ba n sọrọ Sharia leti ọpọ eeyan, ohun to maa n wa si ọkan wọn ni ẹgba tabi ijiya to lagbara.

Ṣugbọn lọdọ obinrin adajọ Sharia akọkọ lorilẹ-ede Malaysia ọrọ yii ko ri bẹẹ.

O ni lọdọ toun Sharia ati ipo ti oun dimu gẹgẹ bi adajọ wa láti dáàbò bo àwọn obìnrin ni.

Aworan ile ẹjọ Shariah

Oríṣun àwòrán, Joshua Paul for the BBC

Àkọlé àwòrán, Awọm musulumi lo po ju lọ lorile-ede Malaysia

Ejọ maarun un ni adajọ Nenney Shushaidah maa n da lojumọ kan ti wọn a si maa n gbe ẹjọ to to ọgọ́rin wa si iwaju rẹ lọsẹ.

Lorile-ede Malaysia ti wọn ti n lo ofin Sharia pẹlu ọfin ilẹ Malaysia pa pọ, ọpọlọpọ eeyan a ma lo ofin Sharia lati yanju aawọ tabi awọn ejọ to jẹ mọ ọrọ lọkọlaya.

Ki baa jẹ ẹjọ to nii ṣe pẹlu owo, adajo Nenney Shushaidah ma n dajọ lori gbogbo wọn.

Àkọlé fídíò, Yaa Asantewaa: Ti ẹyin ọkunrin Ashanti kò bá tẹsiwaju, awa obinrin yóò lọ
Àkọlé fídíò, 'Obinrin jẹ amuludun'

Iru ẹjọ wo ni ó n dá?

Aworan Nenney Shushaidah

Oríṣun àwòrán, Joshua Paul for the BBC

Àkọlé àwòrán, 'Aṣọ Adajọ ti mo wọ yi a ma ran mi leti ojuṣe nla ti mo ni gẹgẹ bi adajọ Sharia'

Amọ ṣa, dida ẹjọ to nii ṣe pẹlu gbigba ọmọ sọdọ laarin lọkọ laya ti wọn ba pinya tabi ki ọkunrin fẹ ju iyawo kan lọ jẹ eleyi ti Adajọ Shushaidah ni imọ nipa rẹ daadaa.

Lorile-ede Malaysia ofin faaye gba ki ọkunrin fẹ to iyawo mẹrin ni ibamu pẹlu ẹsin Islam.

Adajo Shushaidah so pe o ni awọn idi kan ti adajọ gbọdọ wo ki o to le gba ọkunrin laaye lati fẹ iyawo meji tabi ju bẹẹ lọ.

Akẹkọọ kan to n ka Quran ni ile kewu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn alatako ni wọn a ma lo ofin Sharia nilokulo

''Otọọtọ ni iha ti ọrọ a máa kọ si onikaluku''

O tẹsiwaju pe ''a ko le sọ pe ofin Sharia gbe awọn ọkunrin ju awọn obinrin lọ ... Mo fẹ yi ero awọn eeyan pada wi pe Sharia wa lati fi iya jẹ awọn obinrin ni''

''Gbogbo ẹni to ba fẹ fẹ iyawo miran gbọdọ yoju fun ara wọn ni iwaju ile ẹjọ adajọ Shushaida.''

''Mo maa n fẹ gbọ ọrọ lẹnu gbogbo awọn ti ọrọ kan.

Mo muu ni dandan pe ki n ba obinrin naa sọrọ lati mọ boya o faramọ ki ọkọ rẹ fẹ iyawo keji. Ti mo ba kẹfin wi pe ko wu obinrin naa ki ọkọ rẹ fẹyawo keji, mi o ni gba ọkọ naa laaye lati fẹ iyawo miran.''

Aworan Okunrin to fẹ́ iyawo mẹrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Islamu faaye gba okunrin lati niyawo mẹrin to ba wuu

O ni ''obinrin ni mi, mo si mọ bo ti ṣe ri lara ti obinrin ko ba fẹ ki ọkọ rẹ fẹ iyawo mii. Ṣugbọn ofin wa faaye gba ki ọkunrin fẹ iyawo miran ti o si fawọn ofin de bi eeyan ṣe ma fẹ iyawo ọhun.''

Shushaidah tẹnumọ pe ''okunrin gbọdọ ni idi to fẹsẹrinlẹ ki o to le ni ohun fẹ fẹ iyawo mi''

O gbọdọ fi ẹri han wi pe o le toju iyawo akọkọ ati eleekeji to fẹ gbe wole. A ko faaye gba ki o ma le gbọ bukata ẹnikankan ninu wọn.

Aworan Nenney Shushaidah

Oríṣun àwòrán, Joshua Paul for the BBC

Àkọlé àwòrán, Nenney Shushaidah ati awọn oṣiṣe ile ẹjọ rẹ. A fẹ ki awọn obinrin mii lọ kọ imọ nipa ofin Sharia

Adajọ Shushaidah fi kun un wi pe awọn iyawo mi a maa faramọ ki ọkọ wọn fẹ iyawo keji.

O ṣakawe iṣẹlẹ kan to nii ṣe pẹlu arabinrin kan ti aarẹ n daamu rẹ debi wi pe ko le bimo.

''Obinrin naa ni ifẹ ọkọ rẹ to bẹẹ gẹẹ ti o si ni oun gba ki ọkọ oun fẹ iyawo keji.''

''Mo gba ọkọ naa laye nitori idi yi''

Àkọlé fídíò, Tani otutu ma n mu ju laarin Ọkunrin ati Obinrin?
Àkọlé fídíò, #Queen Dihya: Obinrin tó gbógun tàwọn agbésùnmọ̀mí ni Algeria

Kini Sharia?

  • Sharia ni ilana ofin awọn musulumi to n tẹle aṣẹ́ lati inu iwe mimọ al Quran ati ọrọ Anabi Muhammad ti wọn n pe ni Hadith.
  • Lorile-ede Malaysia, ọtọọtọ ni bi wọn ti ṣe n lo Sharia lawọn ipinlẹ to wa nibẹ
Presentational grey line

Adajọ Shushaidah ma n gbaruku ti ẹsin rẹ ti o si ni a ma ṣe deede.

Amọ awọn alatako ati ajafẹtọ eeyan kan a ma bẹnu atẹ lu bi wọn ti ṣe n lo Sharia.

Alasẹ awọn ajafẹtọ-ọmọniyan lagbegbe Asia, Phil Robertson, sọ fun BBC 100 Women wi pe ''awa ko lodi sofin Sharia ni igba ti ko ba ti máa dẹyẹ si awọn obinrin, awọn eeyan lakọ si akọ tabi abo si abo tabi awọn eleya kankan.''

Nenney Shushaidah

Oríṣun àwòrán, Joshua Paul for the BBC

''Amọ wahala to wa pẹlu Sharia ni Malaysia ni wi pe nnkan ti o n ṣe gẹlẹ ni yẹn, ofin Sharia ti wọn n lo máa n dẹyẹ si awọn ti a kà silẹ yii''.

O ni ẹsin kii ṣẹ nnkan ti ''eeyan gbọdọ dimu lati ma fi tapa si ẹtọ ọmọniyan ti ofin agbaye la kalẹ''

O mu apẹrẹ iṣẹlẹ kan ti o nii ṣe pẹlu awọn obinrin kan ti wọn fẹ gbiyanju lati ni aṣepo laarin ara wọn ti ile ẹjọ Sharia si lodi si ẹyi pẹlu ijiya fun wọn.

Adajọ Shusaidah ko sọrọ nipa iṣẹlẹ yi amọ o ni nina eeyan lẹgba labẹ Sharia a ma jẹ ẹkọ fun ẹ́lẹṣẹ́ lati dẹkun hihu iru iwa bẹẹ mọ.

Àkọlé fídíò, Obinrin Akansẹ: Ẹsẹ kiku bi ojo kọ mi lati di alagbara
line
100 Women logo

Ki ni 100 Women?

BBC 100 Women jẹ ọna ti BBC fi máa n ṣe ayẹsi fun awọn obinrin ti o lamilaaka lagbaye ti a si máa n gbiyanju lati ṣọ itan wọn.

Ọdun yi jẹ eleyi to jẹ ọdun to lamilaaka fun jija fun ẹtọ obinrin. Fun idi eyi, a fẹ fi eto Ọgọrun obinrin 2018 lati fi ta awọn obinrin ji ki wọn si le sọ nipa iriri wọn.

Ẹ kan si wa loju opo ayelujara Facebook, Instagram ati Twitter ki ẹ si lo hashtag #BBC100women

Àkọlé fídíò, Awọn Obinrin Dahomey: Awọn obinrin ilẹ Afirika ti wọn yii itan pada re e
Àkọlé fídíò, Àwọn ọkùnrin sọ èrò wọn lórí àríyànjiyàn ẹni tó ni ọyàn obìnrin láàrin bàbá àti ọmọ.
Àkọlé fídíò, Ìgbésí ayé àwọn ọmọdébìnrin wọ̀nyìí di ọ̀tun láti 2008