Ogun Suicide: Ẹ̀lẹ́sìn Islam àti tìbílẹ̀ fìjà pẹ́ẹ́ta lórí ìsìnkú ẹni tó pokùnso

Okun ti wọn fi n pokunso

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn adari ẹsin Musulumi ati ẹlẹsin Ibilẹ gbena wo oju ara wọn lẹyin ti Arakunrin kan gba ẹmi ara rẹ ni Sagamu ni ipinlẹ Ogun.

Arakunrin to doloogbe naa, Muhammed Jamiu to jẹ atunnaṣe (electrician) to si ni ọmọ kan, ni wọn ba ninu yara rẹ to pokunso ni agbegbe Yakubu Habibu, Agura, Sabo, Sagamu.

Iwadii fihan pe, ẹlẹsin Musulumi ni ọkunrin naa, amọ awọn ẹlẹsin ibilẹ wa gbe oku rẹ lẹyin ti iroyin iku rẹ jade sita.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ẹlẹsin ibilẹ naa ni wọn gbọdọ ṣe ẹbọ ati etutu fun oku naa, ki iku naa ma ba jẹ akunfa.

Amọ, Imam Mosalasi Aduragbemi ni Agura Sabo salaye pe, olufọkansin ni ọkunrin naa, ti iku rẹ si ya awọn lẹnu.

Imam ni awọn ẹlẹsin ibilẹ ko laṣẹ lori oku rẹ, bi o tilẹ je pe o pa ara rẹ, amọ wọn ko ri iwe idagbere faye ni ibi to ku si.

Àkọlé fídíò, Oladapo Adu: Nàíjíríà já mi kulẹ̀ torí wọn kò wá gbé mi

Aṣẹyinwa-aṣẹyinbọ, Imaamu ni awọn ẹlẹsin ibilẹ beere owo, sugbọn awọn ko fun wọn, ati wi pe awọn ti sin okunrin naa ni ilana ẹsin Musulumi.

Olori awọn ẹlẹsin ibilẹ Osugbo-Remo in Sagamu, Ifasola Opeodu sọ wi pe, lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, ti o si sọ idi ti awọn fi kọkọ gba oku naa.

Opeodu ni awọn fẹ sin oku naa gẹgẹ bi ilana ti awọn ma n gba sin ẹni to ba pa ara rẹ, nitori ẹbọ ati oro ti o yẹ ki wọn ṣe ki iru rẹ ma ba tun wa ye mọ.

Àkọlé fídíò, Kemi Dairo: Iṣẹ́ abẹ nínú ọpọlọ àti ẹ̀rọ ni mo fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ báyìí

O fikun wi pe, awọn fi oku naa silẹ lẹyin ti Ọba ilu naa dasi iṣẹlẹ naa, ti wọn si fun awọn ni owo, ki awọn to fun awọn Musulumi laaye lati lọ sin.

Amọ, Agbẹnusọ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ni ko si ẹni to gbe ọrọ naa wa si ile iṣẹ ọlọpaa ni agbegbe naa.

Agbebọn pa ọmọ ogun mejila

Aworanm ọmọ ogun orilẹẹde Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ikọlu laarin awọn ọmọ ogun orilẹẹde Naijiria ati awọn agbebọn lariwa Naijiria ki se oun ajoji.

Awọn ọmọ ogun mejila la gbo pe awọn agbebọn seku pa nigba ti wọn kọlu wọn ni abule Konmpanin Doka ni ijọba ibile Birnin- Gwari, nilu Kaduna.

Bakaana ni wọn ni ọmọ ogun mẹrin farapa ninu isẹlẹ naa to waye lalẹ ọjọ isẹgun.

BBC Yoruba gbiyanju lati ba agbẹnuso fun ile isẹ ọmọ ogun ori ilẹ ọgagun John Chukwu sọrọ sugbọn o ni oun ko ti le fesi sọrọ naa.

Awọn kan ti ọrọ naa soju wọn ni awọn agbebọn naa doju ija kọ ibudo awọn ọmọ ogun to wa ni Doka, lagbegbe kan to wa laarin Funtua ati Birnin Gwari, ti wọn si pa awọn ọmo ogun to wa nibe.

Sugbọn ijọba ipinle Kaduna ti fesi sọrọ naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ninu atejade kan ti agbẹnuso fun Gomina Ahmed El Rufai, Samuel Aruwan fi sọwọ si awọn akọroyin,o ni Gomina El Rufai ti bọ kanje lori isele naa o si pe fun, to si pe fun ifọwọsowọpọ pelu awọn eleto aabo lati koju iwa janduku.