Covid-19 in Ondo: Dókítá mìí dágbére fáyé lẹ́yìn tó lùgbàdì àrùn Covid-19 ní Ondo

Oríṣun àwòrán, Others
Arun Covid-19 tun ti mu Dokita miran lọ nilu Akure.
Dokita Michael Adeyeri, to jẹ oludari ile iwosan Shekinah Hospital ladugbo Alagbaka nilu Akure, la gbọ pe o padanu ẹmi rẹ lọwọ arun yii .
Gẹgẹ bi ohun ti akọwe ẹgbẹ awọn dokita oniṣegun oyinbo nipinlẹ Ondo, Dokita Olasakinju Tunde ṣe fidi rẹ mulẹ fun BBC, mọjumọ Ọjọbọ ni onimọ iṣegun yii dagbere faye.
''O ṣeni laanu pe a tun ti padanu dokita mii sọwọ arun Covid-19, mojumọ oni ni a gbọ pe wọn ṣe alaisi''
Dokita Adeyeri ti fi igba kan jẹ dokita to n tọju alakoso ologun fun ipinlẹ Ondo tẹlẹ ri, oloogbe Ibe Onyearugbulem.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọwọja iku awọn oṣiṣẹ ilera lati ọwọ arun Covid- 19 lẹnu ọjọ mẹta yii n peleke si ni Ondo.
Laipẹ yi ni Covid-19 mu Kọmisana feto ilera ipinlẹ Ondo, Dokita Wahab Adegbenro lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Iléesẹ́ rẹ́kọ́ọ̀dù tí mo ti bẹ̀bẹ̀ láti kọrin, padà di tèmi lónìí - Ebenezer Obey
- Ọ̀pá epo NNPC bú gbàmú ní Benin, òṣìṣẹ́ méje kàgbákò ikú òjijì
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ ní Ivory Coast, Olóòtú ìjọba, Amadou Gon Coulibaly jáde láye
- Tó o bá fẹ́ wọ bàálù lásìkò yìí, wo òfin tuntun tó tẹ̀lé
Nigba ti BBC Yoruba kan sile oloogbe Adeyeri nilu Akure, a ri awọn olubanikẹdun ti wọn ti ya bo ile naa lati daro ẹni re to lọ.
Aya, awọn ọmọ ati ọpọ ẹbi oloogbe naa lo ti de sibẹ, ti gbogbo agbegbe naa si kan gogo.
Ọkan ninu awọn ẹbi oloogbe to ba wa sọrọ salaye pe, Ọjọbọ ni dokita naa sọ fun iyawo rẹ pe o dabi ẹni pe oun ti ko arun Coronavirus.
Kia kia lo si gba ile iwosan FMC ti wọn ti n tọju awọn alarun naa lọ, amọ ẹpa ko boro mọ, lẹ yin wakati diẹ to debẹ ni ẹlẹmi gbaa.
Lọwọ lọwọ ta n sọrọ yii, awọn dokita ti daṣẹ silẹ lawọn ile iwosan ijọba nitori pe, aini asọ aabo to peye (PPE) lati fi koju arun Covid -19.
Yatọ si ile iwosan ti wọn ti n tọju ajakalẹ arun IDH nilu Akure, awọn dokita ko tọju alaisan lawọn ile iwosan ijọba.
Akọwe ẹgbẹ awọn dokita onisegun ni Ondo, Dokita Olasakinju fi to BBC leti wi pe, awọn ko ti ribi yanju ọrọ pẹlu ijọba lori iyanṣẹlodi to n waye yi.

Nigba ti BBC beere lọwọ rẹ nipa iroyin to gbode pe awọn dokita ko tọju awọn alarun Covid-19 ni IDH mọ, o sọ pe ''ohun ko le dahun ibeere yi nitori ohun ko mọ nkan to n ṣẹlẹ nibẹ bayi''
Ìjọba Akeredolu kò ní omi àánú lójú, a kò tọ́jú alárùn Coronavirus mọ́ - Dókítá Ondo
Awọn dokita onisegun oyinbo to n sisẹ nile iwosan ti wọn ti n tọju ajakalẹ arun, IDH nilu Akure, nipinlẹ Ondo to n wo isẹ wọn niran.
Ile iwosan IDH yii si ni wọn ti n tọju awọn alarun Coronavirus, ti wsn si ni igbesẹ awọn naa ko sẹyin bi ọwọja itankalẹ arun Covid-19 se n gbilẹ si nipinlẹ naa.
Lọwọ-lọwọ bayii, awọn dokita ọhun ko se itọju kankan fun awọn eeyan to ni arun Coronavirus mọ nile iwosan naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bí àwọn adarí ìjọba ṣe ń kó Coronavirus, ń kọ wá lóminú - Ìjọba àpapọ̀
- Àkójọ́pọ̀ àwòrán rèé lórí bí ìwọlé akẹ́kọ̀ọ́ ṣe lọ sí ní Oyo
- Bí Hushpuppi ṣe tiraka rèé l‘Eko, kí ọlà ‘òjijì’ tó dé
- Akẹ́kọ̀ọ́ wọlé padà, ìjọba Oyo kò pèsè ìbòmú lòdì sí ìlérí rẹ̀
- Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀sìn àti ẹ̀yà ṣe fa ogun abẹ́lé Biafra
- Kàkà k‘éwé àgbọn dẹ̀ lágbo òṣèlú l‘Ondo, akọ̀wé ìjọba tún kọ̀wé fipò sílẹ̀
- Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀sìn àti ẹ̀yà ṣe fa ogun abẹ́lé Biafra
Awọn dokita naa wa n fi ika gun gomina Rotimi Akeredolu nimu lori ọwọ yẹpẹrẹ ti wọn lo fi mu itankalẹ arun naa.
Lara ohun ti ẹgbẹ awọn dokita nipinlẹ Ondo si mẹnuba ti wọn fi n yan isẹ lodi naa ni pe titi di akoko yii, wọn ko tii fi ẹnu ọrọ jona lori owo osu to kere julọ ati atunse rẹ, eyi tawọn ti kii se dokita nile iwosan ti n jẹ anfaani rẹ.
Wọn ni awọn ti sọ fawọn dokita naa nipinlẹ Ondo lati mọ isẹ loju bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ Kẹfa osu Keje nitori aisi omi aanu loju ijọba gomina Akeredolu.
Ìjọba Ondo, inú fìfo la fi ń ṣiṣẹ́, ẹ ṣan ọ̀pọ̀ owó oṣù tẹ jẹ wa - Àwọn dókítà fárígá
Awọn dokita ile iwosan ẹkọsẹ isegun to n yansẹ lodi ti n fẹhonu han ninu ọgba ile iwosan naa to wa nilu Akure, tii se olu ilu ipinlẹ.
Deede aago mẹsan aarọ lawọn dokita ti oju wọn ko rẹrin naa ti pejọ sibẹ, ti wọn si gbe oniruuru akọle lọwọ, ninu eyi ti wọn kọ awọn ohun to n jẹ wọn lọkan si.
Lara awọn ẹdun ọkan wọn ti wọn kọ sara awọn akọle naa ni pe " A n beere fun ohun ti a sisẹ fun, Inu fifo la fi n sisẹ, ti a ko si mọ igba ti ounjẹ miran yoo wa, Dokita ti ebi n wa jẹ ewu fun awujọ, ẹtọ wa ni owo osu wa, kii se ẹbun, ẹ jọwọ, ẹ san owo osu ti ẹ jẹ wa, ki lo de tile iwosan tiwa yatọ , ati bẹẹ bẹẹ lọ."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n fi àwọn tó pa àkẹ́kọ̀ọ́ LASU sí ẹ̀wọ̀n
- Bí àwọn ọ̀tá mi bá jẹ ilá àti ẹ̀bà tán, itẹ́ òkú ní wọn yóò ti fọwọ́ - Bobrisky
- Èyí ni fídíò bí wọ́n ṣe ní Iran ló kọlu bàálù Ukraine tó já ní Tehran
- Ilé Asòfin US dìbò láti dín agbára Ààrẹ Trump kù lórí Iran
- Ọlọpàá f'ọ̀bẹ la ará ilú nífun nílùú Eko.
- Harry àti Megan: Ọbabinrin rọ àwọn òṣìṣẹ́ láàfin láti wá ojútú si ìpinu wọ́n
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ, Alaga fun igbimọ to wa feto iroyin labẹ ẹgbẹ awọn dokita, ẹka tile iwosan naa, Taiwo Olagbe salaye pe, wọn jẹ awọn dokita naa ni owo to to osu mẹfa, marun, mẹrin ati mẹta, eyi to wa lọwọ igba ti onitọun ba wọ isẹ.

Dokita Olagbe fikun pe lẹyin spọ ẹbẹ si awọn alasẹ ati iwọde lọ si ọọfisi gomina, gbogbo ileri ti akọwe ijọba ipinlẹ naa, Ifedayo Abegunde ati oludamọran gomina feto ilera se, lo ja si pabo.
Awọn dokita naa wa n rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Ondo labẹ gomina Rotimi Akeredolu, to fi ms gbogbo ọmọ Naijiria lati bawọn kesi awọn alasẹ ile iwosan naa pe ki wọn jẹ owo ti wọn jẹ wọn.
Wayi o, Kọmisana feto ilera nipinlẹ Ondo, Dokita Wahab Adegbenro ti wa fi ọwọ idaniloju sọya fawọn dokita naa pe, wọn yoo maa ri alaati gba lati ile ifowopamọ wọn pe owo osu ti wọ apo asunwọn owo wọn.















