Iran plane crash: Ẹ wo ìgbà mẹ́jọ tí wọ́n fi àdó olóró já bàálù akérò lulẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn olori orilẹede lagbaaye ti n sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe awọn ọmogun Iran lo ṣaṣiṣe fi ado oloro ja baalu akero ninu eyi ti eeyan mẹrindinlọgọsan ti jẹ Ọlọrun nipe niluu Tehran l'Ọjọru.
Eyi ni igba mẹjọ ọtọọtọ tawọn ologun fi ado oloro ja baalu akero lulẹ lagbaaye.
Baalu akero Malaysia lọdun 2014:
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keje ọdun 2014 ni wọn yin ado oloro fun ọkọ baalu akero MH17 to gbera niluu Amsterdam lọ si Kuala Lumpur ni Malaysia.
Lapa ila oorun Ukraine ni iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ eleyi to ṣekupa eeyan meji din ni ọdunrun un.
Eeyan meje to n ba ilẹ iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ orilẹede Russia ṣiṣẹ pọ ni wọn fẹsun kan pe wọn ṣiṣẹ laabi naa.

Oríṣun àwòrán, Various
Baalu akero Siberia lọdun 2001:
Baalu akero Siberia yii gbera lati Tel Aviv, lorilẹede Israel, o n lọ si Novosibirsk ni Russia ki wọn to fi ado oloro jaa bọ sinu okun lọjọ kẹrin oṣu kẹwaa ọdun 2001.
Gbogbo eeyan mejidinlọgọrin to wa ninu rẹ lo d'oloogbe.
Ileeṣẹ ologun Ukraine kọkọ sọ pe awọn ko mọwọ mẹsẹ, ṣugbọn nigba to ya wọn ni aṣiṣe lawọn ọmogun fi ja baalu naa lulẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Baalu akero Transair mẹta Georgia lọdun 1993:
Eeyan mẹrindinlogoje gbẹmii min nigba tawọn ọmogun ọlọtẹ yin ado oloro fun baalu mẹta Tupolev ti orilẹede Georgia lọdun 1993.
Baalu akero T-134 to gbera lati orilẹede Russia ni wọn kọkọ ja lọjọ kọkalelogun oṣu kẹsan an ti gbogbo ero inu rẹ si ku.
Ọjọ keji ni wọn tun fi ado oloro ja baalu T-154 nigba to n ba ni papakọ ofurufu Sukhumi ti eeyan mejidinlaadọfa si ku ninu rẹ.
Bakan naa, gbogbo ero to wa ninu baalu akero miiran niluu Sukhumi dero ọrun lẹyin ti wọn yin ado oloro lu.
Baalu akero Iran lọdun 1988:

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Baalu akero Iran kan, A300 to n lọ si Dubai ja lulẹ lẹyin ti ado oloro ba a loju ofurufu lagbegbe ''Gulf'' lọjọ kẹta oṣu keje ọdun 1988.
Ọmogun ilẹ Amẹrika kan lo fi ado oloro ja baalu naa lulẹ ninu neyi ti gbogbo awọn eeyan to din mẹwaa lọdunrun un si dagbere faye.
Iran ni iwa ọdaran ni ọmogun naa hu, ṣugbọn orilẹede Amẹrika sọ pe aṣiṣe ni.
Baalu akero Korea lọdun 1983:
Eeyan mọkandinlaadọrinle lugba lo ṣagbako iku ojiji lẹyin tawọn alajangbila kan yin ado oloro mọ baalu akero orilẹede Korea lọjọ kiinni ọdun 1983.
Aṣisẹ lawọn oọmogun Soviet Union lawọn ṣe nigba ti wọn yin ado oloro mọ baalu naa to n rinrin ajo lati ilu New York lọ si Seoul ni South Korea.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Baalu akero Rhodesia 825 ati 827:
Awọn ọmogun Guerrilla ni Rhodesia to ti di orilẹede Zimbabwe bayii fi ado oloro ja baalu meji lulẹ lasiko ogun abẹle lọdun 1978 ati 1979.
Eeyan mejidinlogun kọkọ mori bọ ninu awọn merindinlọgọta to wa ninu baalu naa lọjọ kẹta oṣu kẹsan an ọdun 1978 , ṣugbọn awọn ọmogun ọlọtẹ pada yinbọn pa mẹwaa ninu wọn.
Bakan naa ni ado oloro tun ba baalu akero 827 lọjọ kejila oṣu keji ọdun 1979 nibi ti mọkandinlọgọta to wa ninu baalu ọhun ti d'oloogbe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Baalu akero Libya114:
Awọn ọmogun Isreal ti wọn wa lẹkun aṣalẹ Sinai fi ado oloro ja baalu baalu akero Libya 114, 727-200 lọjọ kọkanlelogun oṣu keji, ọdun 1973.
Eeyan marun ati awakọ baalu kan lo mori bọ ninu eeyan to le mẹta laadọfa to wa ninu rẹ.
Baalu Cathay Pacific Airways C-54:
Eeyan mẹwaa lo ku ninu ijamba ọkọ ofurufu Cathay Pacific C-54 tawọn ọmogun orilẹede China fi ado oloro ja lulẹ lọjọ kẹtalelogun oṣu keje ọdun 1954.
Orilẹede China ni awọn ọmogun ilẹ naa ro pe baalu awọn ọta ni lo jẹ ki wọn fi ado oloro ja a lulẹ.
Èyí ni fídíò bí wọ́n ṣe ní Iran ló kọlu bàálù Ukraine tó já ní Tehran
Awọn ẹri kan n fihan pe o ṣeeṣe ko jẹ pe irinṣẹ ijagun oloro (missile) to jẹ ti orilẹede Iran lo ja baalu orilẹede Ukraine to ja lulẹ nitosi Tehran.
Awọn alaṣẹ orilẹede Canada ati UK si ti n pe fun iwadii to jinlẹ lori ijamba naa, to pa eniyan mẹrindinlọgọrin to wa ninu rẹ.
Ijamba baalu naa waye lẹyin wakati diẹ ti orilẹede Iran fi nkan ijagun oloro ti wọn maa n lo loju ofurufu kọlu ibudo ologun meji ti awọn ọmọ ilẹ America n gbe ni Iraq.

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images
Awọn ileeṣẹ iroyin nilẹ America n sọ pe akoko ti ijamba baalu naa waye n tọka si pe o ṣeesẹ ki wọn ro pe baalu ijagun America ni, paapa bi Iran ṣe n gbaradi pe o ṣeeṣe ki America gbẹsan kikọlu ti Iran kọlu ibudo awọn ọmọ ogun rẹ.
Ileeṣẹ iroyin CBS jabọ pe awọn iwadii abẹnu l'America sọ pe satalaiti ri ina nkan ijagun oloro 'missile' meji, lẹyin naa si ni ibugbamu waye loju ofurufu.
Bakan naa, ileeṣẹ iroyin Newsweek sọ pe olu ileeṣẹ ologun America ati Ọga agba kan nileeṣẹ oluwadi nilẹ America, to fi mọ oṣiṣẹ oluwadi abẹnu kan ni Iraq, sọ pe awọn gbagbọ pe nkan ijagun 'Tor missile' ti wọn ṣe ni Russia lo kọlu baalu orilẹ-ede Ukraine naa.

Oríṣun àwòrán, AFP
Fidio kan ti ileeṣẹ iroyin New York Times ri gba fi han pe 'missile' kan kọja l'oju ofurufu ni Tehran, to si bu gbamu bo ṣe fi ara kan baalu naa. Ko to iṣẹju kan lẹyin eyi ni baalu naa gbina.

Oríṣun àwòrán, AFP
Taa ni yoo ṣe iwadii baalu to ja ọhun?
Ṣaaju ni orilẹede Iran ti kọkọ sọ pe oun ko ni yọnda apoti dudu, 'Black box' to maa n ṣe akọsilẹ ohun gbogbo to ba ṣẹlẹ ninu baalu, fun ileeṣẹ Boeing to ṣe baalu naa tabi ilẹ Amẹrika.
Amọ, ọkan lara awọn alaṣẹ ni Iran sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe awọn ti kọwe pe ilẹ America lati kopa ninu iwadii ijamba naa. Bakan naa ni ileeṣẹ Boeing, ati ajọ to n mojuto aabo lasiko irinajo ni orilẹ-ede Canada naa yoo kopa.















