IranWar:Tump ní ní kíákíá lAmẹ́ríkà yóò kọlù Iran tí wọ́n bá ṣé ikọlù nkán ìní àwọn

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ Amẹrika Donald Trump ti fi ikilọ ranṣẹ si orileede Iran pe bi wọn ba doju ija kọ awọn,ọna mejileelaadọta ni awọn yoo gba kọlu wọn pada.
Ikilọ yi ti Donald Trump fi sita loju opo Twitter ko sẹyin bi Iran ti ṣe ni awọn yoo gbẹsan iku ọgagun awọn ti Amẹrika pa.
Ọgbẹni Trump sọ pe niṣe ni Iran n leri tantan pe awọn yoo kọlu awọn nkan ini Amẹrika kan lati fi gbẹsan iku Soleimani ṣugbọn bi wọn ba dan wo pẹnrẹ,awọn nkan ini to jẹ Iran logun lawọn yoo ṣe ikọlu si.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ninu ọrọ rẹ o ni iye awọn nkan ini Iran tawọn yoo doju ija kọ yi ṣe deede iye ọmọ Amẹrika ti wọn fi si igbekun ni Iran nigba kan ri.
Trump ni awọn ko ni jafara lati kọlu Iran ti wọn ba fi le doju ija kọ awọn eeyan Amẹrika tabi nkan ini wọn.

Oríṣun àwòrán, @realDonaldTrump
Trump ni America ṣẹṣẹ ra awọn ohun eelo ogun didara tuntun ni,
O ni awọn ko nii roo lẹẹmeji ki wọn to yẹ iṣẹ awọn ohun eelo ogun tuntun yii wo lara Iran.
Ẹwẹ, oku ọgagun agba Iran ti Amẹrika pa Qasem Soleiman ti balẹ lorileede naa ṣaju isinku rẹ.
Ijọba Iran kede eto isinku ọlọjọ mẹta lati daro ọgagun yi ti wọn ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi akọni nla loju ija.













