Operation Amotẹkun: Ẹ̀ṣọ́ ilẹ̀ Yorùbá 'Àmọ̀tẹ́kùn' ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ káàkiri ilẹ̀ káàrọ́ọ̀ oò jíire

Awọn gomina ilẹ Yoruba

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dr Kayode Fayemi

Àkọlé àwòrán, Ẹ̀ṣọ́ ilẹ̀ Yorùbá 'Àmọ̀tẹ́kùn' ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ káàkiri ilẹ̀ káàrọ́ọ̀ oò jíire

Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ti kede pe gbogbo eto ti to bayii fun ile iṣẹ eto aabo ilẹ Yoruba ''Amọtẹkun'' lati bẹrẹ.

Fayemi ni ọjọ kẹsan an, oṣu kinni, ọdun 2020 ni eto naa tawọn gomina mẹfa apa gusu orilẹ-ede Naijiria iwọ oorun ṣe agbakalẹ rẹ yoo bẹrẹ kaakiri ilẹ Yoruba.

Gomina Fayemi fi ọrọ ọhun lede ninu ọrọ ọdun tuntun to bawọn eeyan ipinlẹ Ekiti sọ l'Ọjọru, ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2020.

Fayemi ṣalaye pe awọn ẹṣọ 'Amọtẹkun' yoo maa ṣe iranwọ fun awọn agbofinro ni gbogbo ipinlẹ mẹfa nilẹ Yoruba.

Gomina Ekiti ni ijọba ti ṣetan lati rii wi pe eto daabo gbopọn sii nilẹ Yoruba.

O ni lootọọ ni pe iwa ọdaran ko le tan nilẹ patapata, amọ awọn gomina mẹfẹẹfa ti fẹnu ko lati rii wi pe iwa ọdaran dinku kaakiri ilẹ kaarọ o jiire.

Àkọlé fídíò, 2020: Ọdun 2020 yii ko nìí nira fún àwọn tó bá bẹ̀rù Olorun

Ẹwẹ, ẹgbẹ OPC atawọn ẹgbẹ ajijagbara mii nilẹ Yoruba ti kepe awọn gomina yii tẹlẹ pe ki wọn fawọn laṣẹ lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbofinro lati gbogun ti awọn janduku to n da rogbodiyan silẹ nilẹ Yoruba.