Year 2020: Iléri Àarẹ Buhari fún ọdún 2020 rèé

Buhari

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Iléri Àarẹ Buhari fún ọdún 2020 rèé

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti tún fi dá àwọn ọmọ Naijiria lóju pé didun lọsan ọdun 2020 a so fun wọn.

O ni pe kò si ǹkan ti òun fẹ́ lọ mu níle ìjọba lọ́dun 2023 bakan náà ni òun ko ni gbé ìgba ìdìbo kankan lọ́jọ́ iwaju sùgbọ́n òun yóò ri i dáju pé ètò ìṣèjọba àwa ara wa fi ẹsẹ̀ mulẹ̀ dáradára lórilẹ̀-èdè Naijiria.

Buhari ni òun ni ìgbàgbọ́ gidigidi nínú ètò ìjọba alágbádá ati pe òun si ṣetan láti mu u dúró ṣiṣin ni ìwọ̀-òòrun ilẹ̀ Afrika.

Ààrẹ sọ èyí di mímọ nínú ìwé to ko rànṣẹ́ si àwọn ọmọ Naijiria fún ìkíni ọdun tuntun lọ́jọ́rú.

"Ń ó sọkalẹ lórí aléefa lọ́dun 2023, ń o si ni ráàye láti dupo kankan lọ́jọ́ iwáju. Sùgbọ́n mo ti pinnu lati rọ okun sápá ìjọba awa-ara wa.

Àkọlé fídíò, 2020: Oloye Awurela Ifaleke ti wúré ọdún ìgbéga fún kóówá

Ààrẹ Buhari wa tọka si àwọn ètò amayédẹrun ti yóò gùnlé lọ́dun 2020 láti koju gbogbo kùdiẹ-kudiẹ̀ to n ba orilẹ̀-èdè Naijiria fínra.

Aarẹ Buhari dárukọ àwọn òpópónà mẹ́tadinláàdọta kan ti yóò pari láàrin ọdun 2020/2021 to fi mọ àwọn ọ̀na to já si pápákọ ijá ẹrù ojú omi.

Àkọlé fídíò, 'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

Oníruuru àwọn afara to fi mọ ti 2nd Niger Bridge, àṣe pari ilé igbé ọlọpọ yanturu lagbegbe mẹ́tàlá lábẹ ètò ijọba apapọ to n kọle ọlọpọ̀ yanturu fun ará ilú.

Síṣé àfilọlẹ̀ pápákọ̀ òfurufu Eko, Kano, Maiduguri, ati Enugu lọ́dun yìí (2020)

Àkọlé fídíò, 'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'

Síṣe àfilọ́lẹ̀ lílo ẹrọ fun iṣẹ́ ọ̀gbìn nigbèríko, èyí ti yoo kalekako àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ẹẹdẹgbẹrin (700) láàrin ọdun mẹ́ta

Ààrẹ ni ìjọba òun yóò dáwọlé sísé ojú irin Ibadan-Abjua -Kano- Kaduna láarin osù mẹ́ta àkókó ọdun yìí.

Bákan náà ló fi kún un pé ìjọba yóò ṣe àfilọlẹ̀ ojú raluwe Lagos-Ibadan àti Itakpe-Warri.