Naira Marley: Ilé ẹjọ́ ní Naira Marley ń rìn ní bèbè ẹ̀wọ̀n lọ́dún 2020 bí kò bá fara hàn lórí ẹ̀sùn ìjọ́kọ̀gbé

Oríṣun àwòrán, NAira Marley/instagram
Afaimọ ki Naira Marley, gbajugbaja olorin takasufe ti irawọ rẹ n tan lọwọ bayii o maa bẹrẹ ọdun 2020 pẹlu ẹwọn.
Ile ẹjọ Majisireeti agba kan lagbagbe Tinubu nipinlẹ Eko lo paṣẹ pe bi Naira Marley ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Azeez Fashọla, ko ba fi ara han niwaju kootu naa ni ọjọ kẹrinla oṣu kini ọdun 2020, ẹwọn lo fi n ṣere.
- Iná sọ ní ọjà Kara l'Eko l'ọ́dún ku ọ̀la
- Odunlade Adekola, Femi Adebayo: Ìdí tí áwọn obìnrin ṣe máa ń kú fún ẹ̀wà àti ìdúró ọmọkùnrin wọn
- Àwọn fóònù wọ̀nyìí kò ní lè ṣe WhatsApp láti ọdún 2020
- 'Ilé aṣòfin àgbà l'Abuja leè dà wó lulẹ̀ láì ṣe àtúnṣe rẹ̀ ní kíákíá o'
- 'Ẹ̀ ń fi ẹ̀wọ̀n run imú o' Ẹ̀yin Olóyè Ibadan mọ́kànlélógún tẹ ń pe ara yin lọ́ba
- Bàbá akẹ́kọ̀ọ́bìnrin LASU tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti pásítọ̀ fi ṣ'òògùn owó ń bèèrè fún ìdájọ́ òdodo
Naira Marley n jẹjọ ijọkọgbe niwaju adajọ majisireeti Tajudeen Elias pẹlu awọn mọlẹbi rẹ, Idris Fashola, babatunde Fashola ati Kunle Obere.
Adajọ naa kilọ fun gbajugbaja olorin naa lati fara han ni ọjọ naa aṣẹ ẹ lọ gbe wa ni wiwọ ni dide (Bench warrant) loun yoo pa fawọn agbofinro lori rẹ.
Ni ọjọ Iṣẹgun ni ile ẹjọ paṣẹ naa nibi itẹsiwaju igbẹjọ ẹsun jiji ọkọ gbe ti wọn fi kan an.
Ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kejila ọdun 2019 ni wọn kọkọ gbe wọn lọ siwaju ile ẹjọ naa, ṣugbọn Naira Marley ko ysju sile ẹjọ.
Ni ọjọ naa, awọn afunrasi mẹta toku ni awọn ko jẹbi ọrọ ẹsun naa.








