Yoruba Films: Iṣẹ́ amòfin tí mo kọ́ ni Fáṣítì kò mú owó wọlé fún mi bíi iṣẹ́ tíátà - Femi Adebayo

Adebayo

Oríṣun àwòrán, @Loveranger18

Gbajumọ osere tíátà, Femi Adebayo tí sísọ lójú rẹ pé, isẹ agbẹjọro tí òun kọ nílé ìwé Fáṣítì kò mú owó wá fún òun, bíi isẹ tíátà.

Femi, ẹni tó ṣàlàyé bẹẹ lásìkò to ń kópa lórí ètò ileesẹ BBC Yoruba kan, tun fikun pé òun kò kabamọ pé òun fi iṣẹ agbejoro silẹ, máa ṣíṣẹ tíátà.

"Kò to di pé mo dara pọ mọ iṣẹ́ tíátà, láàrin odidi ọdún méjì tí mo fi ṣiṣẹ́ amofin, mo ń gba ẹgbẹ̀rún mẹẹdogun náírà losu, nígbà tí mo sì ń rí ẹgbẹ̀rún marundinlaadọta laarin ọjọ́ mẹ́rin nínú isẹ tíátà."

Àmọ́ Femi, tí ọ̀pọ̀ olólùfẹ́ rẹ tún ń pè ní Jelili Oniso wá yàn pé, òun kó tíì fi iṣẹ agbejoro sílè, nítorí òun sì ń gbèrò láti lọ gba òye ọmọwe nípa imọ òfin nílé ẹ̀kọ́ Fáṣítì, erongba òun sì ni lati maa kọ àwọn amofin nisẹ

Lórí èrò àwọn èèyàn pé òfin Nàìjíríà àti ẹ̀ka èto ìdájọ́ wá fún olówó nìkan, tí idajọ sì ń fi iya jẹ àwọn mẹkunnu, Femi ni èyí kò rí bẹ́ẹ̀ nítorí ilé ẹjọ́ di ojú ni, tó sì ń fi etí gbọ ẹjọ́, bẹ́ẹ̀ lo ni ida láti ṣèdájọ́ fún ẹni tó bá jẹbi, bóyá olówó ni àbí mẹkunnu.

Jelili Oniso wá gba àwọn aráàlú nímọ̀ràn láti máa ṣèwádìí nípa àṣeyọrí agbejoro kan ni ẹnu isẹ, kí wọn tó máa gbé ẹjọ́ fún láti dènà ijakulẹ.

Adebayo

Oríṣun àwòrán, others

Nígbà tó ń ṣàlàyé bo se dára pọ mọ eto òṣèlú, Femi ni ìjọba Abdulfatai Ahmed tó kogba wọlé ni Kwara, lo yàn òun sì ipò Oludanimọran, tí òun si rí ìpè náà, bíi ọ̀nà láti súnmọ́ àwọn mẹkunnu ni.

"Eto oselu Nàìjíríà lágbára pupọ, tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ boo bá ọ pá, boo bá o bù lẹsẹ wá, sugbon ìjọba tó wà lóde báyìí tí dènà irú ìwà yìí, tí kò sì tún faaye silẹ fún ajẹbanu.

Bákan lo fikùn pé, oselu kò pá isẹ tíátà tí òun ń ṣe lára nítorí pé, Ọlọ́run fún òun ní aya tó di ilé mú dáadáa, tí Gomina tí òun sì bá ṣíṣẹ náà fún òun ní ààyè láti máa lọ síbi ère tíátà, ni àwọn ọjọ́ kan.

Àkọlé fídíò, Wo ìdí tí àwọn orílẹ̀èdè fi ń dẹwọ òfin kónílé-ó-gbélé Coronavirus

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé àwọn osere tíátà ṣe máa ń tètè dàrú, Jelili Oniso ṣàlàyé pé, "ẹni tí yóò bá jẹ ọkọ àbí ìyàwó gbajumọ gbọdọ ni ìfaradà púpọ̀ nítorí tí gbogbo ayé ni ọkọ àti aya tó ń pè ní tiẹ̀ nìkan, kí wọn sì máa bẹ Ọlọ́run pé kí onitohun má sìṣe .

" Ọ̀pọ̀ àbùkù lo máa ń bá ilumọọka àmọ́ ọpọ ìgbéyàwó lo ń dàrú yàtọ̀ sí ti àwọn onitiata. Ohun tó já ju ni pé tá bá fẹ́ gbajumọ lọkọ àbí láyà, a gbọ́dọ̀ ṣe sùúrù gidigidi."

Femi, ẹni tó kọ orin Sakara lórí ayélujára lásìkò ígbélé Covid-19 yìí ni, òun kò ní ẹ̀bùn orin kíkọ, àmọ́ osere gidi yẹ kó leè dibọn, kò sì farajọ ẹni tó ń sìn jẹ́.

O wá rọ àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ láti se ère tíátà, pé kí wọ́n lọ sí orí ayelujara àmọ́ ó ni òun gan ni ileesẹ tó ń kọ àwọn èèyàn ní iṣẹ́ tíátà.

Adebayo

Oríṣun àwòrán, others

Femi, to tí lo ọdún marundinlogoji lẹ́nu iṣẹ́ tíátà, tún pàrọwà sawon èèyàn láti ṣe ìwádìí kíkún kí wọn tó dárapọ mọ iléèwé tíátà kan.

O wa sísọ lójú rẹ pé, "ẹgbẹ́ àwọn osere tíátà, Tanpan, tí ń gbé igbesẹ láti maa fún àwọn iléèwé

náà niwe àṣẹ, kí wọn má bàa yapa kúrò ní ìdí ìlànà tó tọ́."

Femi ni òun máa ń fi iṣẹ àgbẹ̀ pawọda n'ilu Ilorin, lẹ́yìn iṣẹ́ tíátà, tí òun sì ń sìn àwọn ohun ọ̀sìn pẹ̀lú, tí òun sì tún máa ń bá àwọn èèyàn ta ilẹ̀ tàbí ra ilé, èyí tí kò ní jẹ́ kí wọn bọ sọwọ alagbeda.

O wa gba àwọn aráàlú láti gba agbẹjọro, lásìkò tí wọn ba fẹ́ tá àbí ra ilẹ̀ ati ile, kò leè bá wọn ṣe ìwádìí nípa dúkìá náà lábẹ́ òfin, tí wọn yóò sì gba ojúlówó ìwé ilẹ̀ àbí ilé náà.

Femi, nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè lórí bí àwọn osere tíátà ṣe máa ń safihan ibalopọ àti wiwọ aṣọ iwọkuwọ ninu sinima, ṣàlàyé pé ẹgbẹ́ Tanpan tí ń ṣíṣẹ pelu àjọ ti ìjọba gbé kalẹ fún akoso sinima, láti dẹkùn irú ìwà aidaa báyìí.

Àkọlé fídíò, Báwo ni èèyàn ṣe le mọ pé òun ti ní àrùn Coronavirus?

Femi tún ṣàlàyé pé, lára ìpènija tí òun koju bíi osere tíátà ni pé, òun kò leè gbé ayé ara òun mọ nítorí pé òun ti di gbajumọ, tí òun kò sì leè ṣe bo se wù òun.

Femi, tíì ṣe ọmọ àgbà ọjẹ osere tíátà, Adebayo Salami, wá fìdí rẹ múlẹ̀ pé, orúkọ Baba òun là ọ̀nà pupọ fún òun nínú isẹ tíátà nítorí láti kékeré òun ti ń kó isẹ tíátà lára wọn.

"Ọpẹ bàbà mi lára mi, ti ìṣẹ̀lẹ̀ kan bá wáyé, tàbí táwọn oniroyin bá kọ nkan ti kii se òótọ́ nípa mi, ní máa béèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ wọn, bí kii bá sì ṣe ìtọ́sọ́nà bàbà mi, afaimọ kí n má tí kọsẹ̀ nínú isẹ tíátà."

Àkọlé fídíò, Ẹsẹ̀ bàtà, èso kukumba ni wọ́n fi ń já àbálé àwọn ọmọ Nàìjíríà ní Libya

Femi, ẹni tó ṣe àlàyé lórí ohun tó fa tí òun fi ṣe fíìmù Jelili ní, "mo rí pé ìlú kan gógó , táwọn èèyàn ń rìn tikanra-tikanra pẹ̀lú aìdùnnú, lo mú kí n fi ṣe sinima tó jẹ́ awada, láti pa àwọn èèyàn ní ẹrin, tí mo sì gbọ́ nílé ìwòsàn UCH pé, fíìmù náà pá àwọn aláìsàn ni ẹrin púpọ̀, tó sì tètè mú kí ara wọn yà."

Femi Adebayo wá kadi ọ̀rọ̀ rẹ nilẹ pé, ẹgbẹ́ àwọn osere tíátà tí ń gbé ìgbésẹ láti kan sì àwọn onileesẹ ibaraenisọrọ láti máa fún àwọn nínú owó tí àwọn èèyàn fi ń rà káàdì gùn ìlò ojú òpó ayélujára, taa mọ sì data, èyí tí wọn fi ń wo fíìmù lórí ayélujára.

Yoruba Films: Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá ọkùnrin tí ó rẹwà

Gabriel Afọlayan, Gfresh

Oríṣun àwòrán, Gabriel Afolayan

Àkọlé àwòrán, Gabriel Afọlayan, Gfresh

Oniruuru ni awọn oṣere tiata ni ilẹ Yoruba.

Pẹlu bi o ṣe jẹ pe eka ere ori itage lorilẹ-ede Naijiria, ti a mọ si Nollywood ni awọn onwoye ti kede gẹgẹ bii ileeṣẹ tiata ti o n goke ju lọ lorilẹ-ede agbaye, ẹka ere tiata ilẹ Yoruba, Yollywood si jẹ ọkan lara awọn ti o gbe e soke.

Ọdunlade ati Fẹmi adebayo

Oríṣun àwòrán, odunlade adekola

Àkọlé àwòrán, Ẹwà àwọn òṣèré ọkùnrin wọ̀nyí leè mú kí obìnrin maa pariwo 'bi eleyi o jẹ ọkọ ẹni ko saa ti jẹ ale ẹni'

Lara awọn oṣere yii ni a ti ri awọn ọkunrin oloṣere ti wọn jẹ ọdọ, ti aye n fẹ, ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, ti ẹwa wọn lee sọ obinrin maa pariwo 'bi eleyi o jẹ ọkọ ẹni ko saa ti jẹ ale ẹni'.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọdunlade Adekola

Oríṣun àwòrán, Odunlade Adekola

Àkọlé àwòrán, Ọdunlade Adekola

Odunlade Adekọla:

Odunlade Adekọla ni a lee pe ni irawọ ti o n tan lagbo ere tiata Yoruba bayii.

Ko si si tọmọde tagba ti ko fẹran rẹ nitori oniruuru ipa ti o ti ko ninu awọn ere itage yala apanilẹrin ni tabi eyi to da lori iwa ọdaran.

Lati igba ti o ti bẹrẹ iṣẹ rẹ, yoo ti le ni ọgọrun un fidio agbelewo ti o ti ṣe.

Ọpọ awọn obinrin ni o si maa n woo gẹgẹ bi arimalee lọ ọkunrin eleyii ti o farahan ninu awọn ti o n tẹ lee lori ikanni instagram rẹ.

Gabriel Afọlayan, Gfresh

Oríṣun àwòrán, Gabriel Afolayan

Àkọlé àwòrán, Gabriel Afọlayan, Gfresh

Gabriel Afọlayan, Gfresh

Ọkan lara awọn ọmọ agba oṣere tiata Yoruba ti o ti doloogbe, Adeyẹmi Josiah Afọlayan, ti ọpọ mọ ni Ade Love ni Gabriel, ti ọpọ mọ si Gfresh.

Ọmọ ilu Agbamu nipinlẹ Kwara ni awọn Afọlayan. Bi o ti n kọrin naa lo n ṣe ere tiata. Bakan naa lo n ṣe aṣoju awọn ipolowo ọja gidigidi.

Ki a ma si parọ, ọpọ omidan ladugbo ni o mọ pe ọmọ daa sibẹ. Ekọ nipa ere itage ni Gabriel ka ni fasiti ibadan.

Àkọlé fídíò, 2020: Oloye Awurela Ifaleke ti wúré ọdún ìgbéga fún kóówá
Kunle Afolayan

Oríṣun àwòrán, Kunle Afolayan

Àkọlé àwòrán, Kunle Afolayan

KunleAfọlayan.

Ko yanilẹnu rara pe Arẹmu ọmọ agba oṣere tiata Yoruba ti o ti doloogbe, Adeyẹmi Josiah Afọlayan, ti ọpọ mọ ni Ade Love naa wọ ọkan lara awọn oṣere tiata Yoruba lọkunrin ti oju wọn gunrege.

O jẹ ọkan lara awọn ti obinrin ko si lee fi oju kere nipa ti ẹwa.

Idi ni pe baba wọn pẹlu nigba aye rẹ kii ṣe oburẹwa rara.

Àkọlé fídíò, 'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'

Adari ere tiata ni iṣẹ ti Kunle gbaju mọ julọ.

Awọn iṣẹ gbogbo ti o si ti ṣe ni wọn maa n gbayi lorilẹ-ede yii ati loke okun.

Awọn iṣẹẹ rẹ bii October 1, CEO ati bẹẹ bẹẹ lọ ti gba amiẹyẹ lorilẹ-ede Naijiria ati loke okun.

Kunle Afolayan pẹlu awọn adanilaraya miran lọdọ Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

Àkọlé àwòrán, Kunle Afolayan pẹlu awọn adanilaraya miran lọdọ Aarẹ Buhari

Bẹẹni ko yanilẹnu nigba ti orukọ rẹ jẹyọ ninu awọn adanilaraya kaakiri orilẹede Naijiria ti aarẹ Muhammadu Buhari gba lalejo ni ọdun 2018.

Ẹrin ẹnu rẹ ati iduro rẹ jẹ eyi ti o lee mu ki abo fi akọ ti o n tẹle silẹ.

Bolanle Ninalowo

Oríṣun àwòrán, Ninalowo bolanle

Àkọlé àwòrán, Bolanle Ninalowo

Bolanle Ninalowo.

Ṣaṣa ni obinrin ti yoo ri Ọgbẹni Bọlanle Ninalowo ti ko ni ki Ọlọrun ku iṣẹ nitori ẹwa rẹ.

Iṣẹ iṣiro owo ni Ninalowo kọ ni faisiti lorilẹ-ede Amẹrika ti o si fi ṣe iṣẹ fun ni ile ifowopamọsi ki o to tẹle ohun ti ọkan rẹ fẹ, iyẹn iṣẹ ere ori itage.

Àkọlé fídíò, Wòlíì Kasali sọrọ nípa awuyewuye pé o lè ìyàwó rẹ̀ jáde nílé
Fẹmi Adebayọ

Oríṣun àwòrán, Femi Adebayo

Àkọlé àwòrán, Fẹmi Adebayọ

Fẹmi Adebayọ.

Ajogunba ni ere itage ṣiṣe fun Ọgbẹni Fẹmi Adebayọ.

Lara awọn eekan ati opomulero to gbe fidio ṣiṣe lede Yoruba goke ni baba rẹ, Adebayọ Salami, ti ọpọ eeyan mọ si 'Bello'.

Agbẹjọro ni iṣẹ ti Fẹmi kọ jade ni fasiti ki o to gba ọna iṣẹ tiata lọ.

Eledumare pari ẹwa si ara Fẹmi pẹlu, bẹẹni ko si obinrin ti yoo pade rẹ ti yoo ni oun ko ri eniyan rara.

Muyiwa Ademọla

Oríṣun àwòrán, Muyiwa Ademola

Àkọlé àwòrán, Muyiwa Ademọla

Muyiwa Ademọla.

Ẹgan ni hẹẹ pẹlu ẹwa ti Ọlọrun fun Muyiwa Ademọla. Fasiti ibadan ni oun pẹlu ti ṣetan, o si wa lara awọn eekan agbo oṣere tiata nilẹ Yoruba ati lorilẹede Naijiria lapapọ.

Eree 'Ori' ni ọdun 2004 lo pokiki Muyiwa, lati igba naa wa ni o si ti n lọ siwaju lai kaarẹ

Àkọlé fídíò, Asisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù