2020 Countdown: Àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ṣáájú Nàìjíríà wọ ọdún 2020

Aworan ibi ti wọn ti n ṣe ọdun 2020

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi ọdun 2020 ti ṣe ku wakati diẹ́ lọdọ tiwa ni Naijiria ati awọn apa ibomiran lagbaye, awọn kan ti n ki ara wọn ku ọdun tuntun.

O yayi lẹnu abi? Bẹẹ lo ri nitori pe lawọn orile-ede kan,oju ọjọ ko ri bi ti ọdọ tiwa ti wọn a si ma fi wakati meloo kan ṣaaju wa lojumọ kọọkan.

Lawọn orile-ede ta n sọ yi, orun n mu ti o si n wọ bi tiwa ṣugbọn iyatọ pe awọn lewaju wa ni ounka wakati lo jẹ ki wọn ti ki ọdun tuntun kaabọ ṣaaju wa.

Diẹ lara awọn orile-ede naa re ati aworan bi wọn ti ṣe ki ọdun 2020 kaabọ lọdọ wọn.

Sydney New South Wales Australia

Ni nkan bi aago mọkanla kọja iṣẹju mẹẹdogun, ọjọ Iṣẹgun tii ṣe ọjọ Kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, 2019 lọdọ ti wa ni wọn kii 2020 kaabọ ni Australia.

Yatọ si Sydney,awọn eeyan Alice Springs,Cairns,Adelaide wa lara awọn ilu to ti n ṣe pọpọṣinṣin ọdun 2020.

Aworan ibi ti wọn ti n ṣe ọdun 2020

Oríṣun àwòrán, Getty Images

New Zealand

Wellington,Auckland ati Chatam Island wa lara awọn ilu ti wọn ti dagbere fun 2019 ti wọn si ti ṣe kaabọ si 2020.

Aworan ibi ti wọn ti n ṣe ọdun 2020

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé fídíò, 2020: Oloye Awurela Ifaleke ti wúré ọdún ìgbéga fún kóówá
Aworan ibi ti won ti n se odun 2020

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lawọn apa kan lorileede Russia bi Pevek, Srednelolymsk, Anadyr, Magadan wọn ti wọ ọdun 2020 lati nkan bi ago kan abọ ọsan ni orile-ede wa Naijiria.

Ṣugbọn lọdọ wọn, lasiko ta n ṣe akojọpọ iroyin yi, ago kan oru ni wọn wa.

Awọn orile-ede miran ti wọn ti ki 2020 kaabọ ni:

  • Suva ni Fiji
  • Nukualofa ni Tonga
  • Apia ni Samoa
  • Homiara ni Solomon Islands

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'