End of a decade: Àwọn ìròyìn mẹ́wàá tó mí ilẹ̀ titi láàrin ọdún 2010-2019

Trump, Bring Back Our Girls, Meghan Markle

Oríṣun àwòrán, Other

Ọdun mẹwaa ninu igbe aye ẹdamọniyan kii ṣe awada.

Idi re e ti BBC Yoruba ṣe ni ki a jijọ ṣe iranti awọn iroyin to mi igboro titi laarin ọdun 2010-2019.

Ọpọ nkan lo ṣẹlẹ, nibẹ la ti ri eleyi to fọwọkan aw"n eeyan lẹmi ati awọn ti o ṣe awọn eeyan ni kayeefi.

Ni meni meji, diẹ ninu awọn eleyi ti a ri ka re.

Iku Gadaffi lọdun 2011

Muammar Al-Gaddafi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ogunjọ Oṣu Kẹwa ni awọn ajijagbara mu olori orileede Libya Muammar Gaddafi, ti wọn si pa.

Iku Gaddafi milẹ jiji latari bi ọpọ eeyan ti ṣe n fi oju olori ti ko dara wo.

Iku rẹ lo ṣebi ẹni ṣina oṣelu awarawa lorileede rẹ nigba naa.

Amọ loni ta n sọrọ yi, Libya ti di ilẹ ti kosi ifọkanbalẹ ti awọn ọmọ ilẹ naa ko si ti ribi ṣakoso ilẹ wọn bi o ti ṣe wu wọn lọkan.

Poopu Benedict XVI loun ko ṣe poopu mọ ni 2013

Pope Benedict XVI

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ko ṣẹlẹ ri lawọn eeyan n sọ nigba ti Poopu mimọ Benedict XVI kede pe o to gẹ, oun ko ṣe poopu mọ loṣu keji ọdun 2013.

Igba akọkọ ni yoo jẹ ti Poopu yoo fiṣẹ silẹ ni ẹgbẹ̀ta ọdun ti Poopo ti n jẹ.

Ṣugbọn lẹyin ikede rẹ lawọn eeyan ba tun bẹrẹ si ni ṣe pọpọṣinṣin ẹni ti yoo jẹ Poopu lẹyin rẹ.

Lẹyin o rẹyin, Poopu fi ikede sita pe ailera lo mu ki oun kọwe fi ipo silẹ

Iku Nelson Mandela, 2013

Nelson Mandela

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ilumọọka oloṣelu

Aarẹ South Afrika tẹlẹ Jacob Zuma lo kede iku aarẹ alawọdudu akọkọ South Afrika Nelson Mandela lori ileeṣẹ ẹrọ amounmaworan ilẹ naa.

Ohun ibanujẹ ni iku rẹ jẹ fawọn ọmọ ile naa ati awọn eeyan mii kakiri agbaye.

Zuma ṣapejuwe Nelson Mandela gẹgẹ bi Baba fun awọn eeyan South Afrika. Awọn eeyan gbe orin, fiimu ati eto orisirisi jade ti wọn fi yẹ Mandela si.

Ipolongo #BringBackOurGirls,2014

Michelle Obama

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ipolongo yi lawọn eeyan mu ni ọkunkundun lati ṣe awari awọn akẹkọbirin ile ẹkọ nilu Chibok tawọn ikọ Boko Haram ji gbe.

To fi mọ iyawo aarẹ Amẹrika nigba naa, Michelle Obama, jakejado agbaye lawọn eeyan n ṣe ipolongo pe ki wọn tu awọn akẹkọbinrin yi silẹ.

Wọn le ni igba ti Boko Haram ji gbe.

Loju opo ayelujara lawọn ilumọọka ati olori orileede ti n lọgun ki ijọba Naijiria wa wọrọkọ fi ṣada lori awọn ọmọ wọn yi.

Idibo aarẹ Naijiria,2015

Aworan Goodluck Jonathan ati Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Buhari lo jaweolubori gẹgẹ bi aarẹ ninu idibo to waye ni ọdun 2015

Lọdun 2015, ọgagun Muhammadu Buhari to ti fi igba kan jẹ olori orileede Naijiria yẹ aga nidi Aarẹ Goodluck Jonathan ninu idibo aarẹ to waye.

o le ni miliọnu meji le diẹ ibo ti Buhari fi jaweolubori ti o si di ọmọ ẹgbẹ alatako akọkọ ti yoo yẹgi nidi aarẹ to wa nipo .

Lẹyin ọdun mẹrindinlogun ti ẹgbẹ oṣelu PDP ti wa lori alefa, APC gba ijọba lọwọ wọn.

Donald Trump di aarẹ Amẹrika , 2016

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Donald Trump jẹ onisowo saaju ki o to di aarẹ Amẹrika

Bi igba ti ilẹ mi ni iroyin pe Donald J. Trump ti ẹgbẹ oṣelu Republican l'Amerika di aarẹ ti ṣe ri lara awọn eeyan lagbaye.

Pupọ eeyan ni ko ni igbagbọ pe o le di aarẹ, ṣugbọn o fi idi alatako rẹ Hilary Clinton ti ẹgbẹ oṣelu Democrat janlẹ ninu idibo to waye.

Iroyin gbajugbaja oniṣowo to pada wa di aarẹ yi lo gba ori afẹfẹ kaakiri agbaye lọdun 2016

Leicester gba ife ẹyẹ Premier League lọdun 2016

Igba akọkọ re ti Leicester yoo gba ife ẹyẹ Premiership

Aworan ẹgbẹ agbabọọlu Leicester

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Igba akọkọ re ti Leicester yoo gba ife ẹyẹ Premiership

Ọkan gbogi iroyin to mi igboro titi ni ti ẹgbẹ agbabọọlu Leicester ti wọn gba ife ẹyẹ Premiership ni oṣu kaarun un ọdun 2016.

Ọpọ eeyan ni ko tilẹ ro wi pe Leicester le pagọ ṣugbọn ẹgbẹ yi ṣe bẹ wọn kọ ile alarinrin.

Igbeyawo Meghan Markle 'Royal Wedding' 2018

Igbeyawo ọmọọba Hary ati Meghan Markle

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igba akọkọ re ti obinrin alawọdudu yoo jẹ oye ayaba Sussex.

Igbeyawo arabinrin Meghan Markle ati ọmọ ọba Harry milẹ titi.

Ni ọjọ igbeyawo wọn tii ṣe ọjọ kọkandinlogun oṣu kaarun, ogunlọgọ awọn eeyan lo n wo iran igbeyawo yi jakejado agbaye.

Loju opo ayelujara, o le ni milọnu mẹta eeyan to n fi ọrọ sita nipa rẹ lori Twitter.

Igbeyawo yi jẹ ọkan lara awọn iṣẹlẹ tawọn eeyan fi tidunu tayọ wo kaakiri agbaye.

Fiimu BlackPanther, 2018

Aworan awọn oṣere to kopa ninu fiimu Black Panther

Oríṣun àwòrán, Marvel Studios

''Wakanda Forever'' ni igbe to gbori atẹgun kaakiri agbaye lẹyin ti fiimu Black Panther jade sita lọdun 2018.

Ninu fiimu yi, awọn eeyan alawọdudu ni wọn kopa ninu rẹ pupọ, koda ẹni to dari fiimu naa alawọdudu nii.

Fiimu naa gba ami idanimọ Oscar lorisirisi ti o si jẹ fiimu ti eeyan alawọdudu dari rẹ to pawo julọ lagbaye.

Ghana year of return, 2019

Ijọba Ghana fi iwe ọmọ onilẹ da awọn to pada wa sile lọla

Oríṣun àwòrán, GHANA PRESIDENCY

Ọdun ipadabọ ni 2019 lorileede Ghana naa jẹ iṣẹlẹ kan to lamilaaka .

Awọn ọmọ ilẹ Afrika to wa nilẹ Amerika ti wọn si pada wa si ile ni eto yi yannana.

Pupọ awọn to ti n gbe lẹyin odi yi pada wa sile ni ayajọ irinwo ọdun ti wọn ko awọn eeyan lẹru lọ si ilẹ okere ti wọn si balẹ si ilu Jamestown ni Virginia l'Amẹrika.

Olaronke Alo lo ṣe akojọpọ iroyin yi.