Ọmọọba Harry àti Meghan Markle di tọkọtaya

Ọmọọba Harry ati Meghan Markle

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Archbishop Canterbury, Justin Welby ni ó so wọn pọ̀ ní ilé ìjọsìn St. George

Lẹ́yin gbogbo ètò, Ọmọọba Harry ati Meghan Markle ti di tọkọtaya báyì. Olórí ìjọ Anglican ti a mọ̀ sí Archbishop Canterbury, Justin Welby ni ó so wọn pọ̀ ní ilé ìjọsìn St. George ní Windsor.

Bí ìsìn náà ṣe parí ni àwọn mékéèjì ṣe jáde síta tí wọn sì fi enukonu ní iwájú gbogbo èro tí ó wà ní ita ilé ìjọ́sìn.

Ogunlọ́gọ̀ àlejò kákàkiri àgbáye ni ó wá sí ibi ìgbéyàwó náà.

Ìyá Meghan Markle, Doria Ragland, nìkan ni ẹbí ìyàwó tí ó wá si ibi igbéyàwó náà.

iya iyawo Doria Ragland

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iya Meghan Doria Ragland nikan ni ẹbí ìyàwó tí ó wá síbi ayẹyẹ náà.

Bíṣọ́ọ́bù aláwọ̀ dúdú kan láti orílẹ̀ede Amerika, Michael Curry ni ó wàásù níbi ìgbéyàwó náà.

Bíṣọ́ọ́bù Michael Curry

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bíṣọ́ọ́bù Michael Curry láti ìjọ Episcopal ti ilú Chicago wáàsú nípa ìfẹ́

Bí tọkọtaya náà ṣe jáde nínú ilé ìjọsìn ni ẹṣin gbé wọn lọ tí gbogbo àwọn ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ tí ó tò sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà sí bẹ̀rẹ̀ ju ọwọ́ sí wọn.

Ẹgbẹ̀ta alejò ni ó wá si ibi ìsìn igbéyàwó náà. Nínu wọn ni ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ òṣèré bìì ti Meghan Markle.

Àwọn aṣọ àti ẹ̀ṣọ́ ìyàwó

A gbọ́ pé arábinrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Waight Keller ní ó ṣe aṣọ ìyàwó labẹ́ àkósó ilé iṣẹ́ Givenchy ti orílẹ̀ede France.

Eyí tí ó wá jọni lójú jù ni wípẹ́ ẹ̀ṣọ́ orí ìyàwó, Ọbabinrin Elizabeth ni ó yáà lò. Wọn ní iyá iyá ọbabinrin náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Queen Mary, ni ó ní. Ọdún 1932 ni wọ́n ṣe ẹ̀ṣọ́ náà.

Ẹṣọ́ orí Meghan Markle

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọdún 1932 ni wọ́n ṣe ẹ̀ṣọ́ orí Meghan Markle tí Ọmọbabinrin Elizabeth yáa lò