Ìgbéyàwó Harry àti Markle: Ẹni ńlá ní ń ṣe ohun ńlá

Aworan afinimọna fun igbeyawo Harry ati Merkle

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹfa awọn araalu ni yoo kopa nibi eto igbeyawo naa

Kaakiri agbaye ni okiki yoo ti kan ni ọjọ abamẹta ti Ọmọọba Harry ati Omidan Meghan Markle ba ṣe'gbeyawo wọn ni ilu Windsor nilẹ Gẹẹsi.

Lootọ ilu mọọka ni igbeyawo naa yoo jẹ, ṣugbọn awọn ohun kan wa ti o yẹ ki o mọ nipa igbeyawo yii.

"Mo gbe iwọ Rachel niyawo"

Ọmọọba Harry n ki awọn eeyan to wa baa dawọọ idunnu fun igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Thomas to jẹ baba Meghan Markle ko lee farahan nibi igbeyawo naa nitori ailera ara rẹ

Nigba ti asiko ati fi aya fun ọkọ ba to, ma ṣe foya nigba ti o ba gbọ, 'mo gbe iwọ Rachel niyawo' nitori Meghan ni ọpọ mọ orukọ iyawo si.

Orukọ akọkọ ti omidan Meghan n jẹ ni Rachel ṣugbọn ni ẹnu iṣẹ rẹ gẹgẹ bii gbajugbaja oṣiṣẹ mohunmaworan ni orilẹede Amẹrika, orukọ rẹ keji lo mu lọkunkundun ni jijẹ, ohun si ni ọpọ eniyan mọọ mọ.

"Mo gba iwọ Henry gẹgẹ bii ọkọ mi"

Awọn ero ati agbofinro ni Windsor

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Kaakiri agbaye ni okiki ti kan de nípa igbeyawo Ọmọọba Harry ati Omidan Meghan

"Henry" boo? Ni ibeere to ṣeese ko gba ẹnu awọn eeyan pupọ nitori Harry ni wọn mọ orukọ ọkọ iyawo ọjọ abamẹta si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ maa foya, apeja orukọ ọmọọba Harry ni Henry Charles Albert David ti ilu Wales, ṣugbọn orukọ ti gbogbo wa mọọ si ni Ọmọọba Harry.

O ṣeeṣe ki Ọmọọba Harry ati Omidan Markle o pa orukọ da lẹyin igbeyawo wọn

Aworan Harry ati Meghan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Orukọ oye tuntun, "Duke of Sussex" ni o ṣeeṣe ki wọn fun Ọmọọba Harry lẹyin igbeyawo yii

Gẹgẹ bii aṣa ilẹ Gẹẹsi, o ṣeeṣe ki orukọ ọkọ iyawo ati iyawo rẹ o yi pada lẹyin igbeyawo wọn.

Orukọ oye tuntun, "Duke of Sussex" ni o ṣeeṣe ki wọn fun Ọmọọba Harry nigbati iyawo rẹ, Meghan yoo di "Duchess of Sussex".

Awọn ọrẹ iyawo mẹwa pẹlu ọmọ iyawo lọkunrin ti ọjọ ori gbogbo wọn ko ju ọdun mẹjọ lọ ni yoo duro ti iyawo tuntun

Awọn eeyan to wa woran igbeyawo

Oríṣun àwòrán, OLI SCARFF

Àkọlé àwòrán, baba ọkọ ni yoo fi iyawo fun ọmọ rẹ dipo baba iyawo

Lara awọn wọnyii ni Ọmọọbakunrin Goerge ati Ọmọọbabinrin Chalotte yoo wa.

Baba ọkọ ni yoo fi iyawo fun ọkọ

Awọ̀n agbofinro n yan kaakiri

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, O ṣeeṣe ki orukọ ọkọ iyawo ati iyawo rẹ o yi pada lẹyin igbeyawo yii

Bẹẹni, ẹ maa jẹ ko ya yin lẹnu pe baba ọkọ ni yoo fi iyawo fun ọmọ rẹ dipo baba iyawo.

Ọgbẹni Thomas to jẹ baba Meghan Markle ko lee farahan nibi igbeyawo naa nitori ailera ara rẹ. Lootọ awọn eeyan kan daaro pe boya ki iya rẹ o gba ipo yii, ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ ijiroro ni wọn ni ki Ọbalọla, iyẹn ọmọọba Charles to jẹ baba ọkọ iyawo o mu iyawo wọ ileejọsin lati faa le awọn alufaa lọwọ.

Ẹgbẹfa ni awọn araalu ti wọn ti fun ni ore ọfẹ lati darapọ mọ igbeyawo naa

Awọn ero ni ilu Windsor

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìrọ́-kẹ̀kẹ̀ ìgbeyàwó Ọmọọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Harry àti ìyàwó rẹ̀, Meghan Markle ti gbalé kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Ẹgbẹfa awọn araalu ni yoo kopa nibi eto igbeyawo naa. Eyi si yatọ si awọn ọtọkulu kaakiri agbaye ti awọn pẹlu yoo peju sibi eto igbeyawo naa.