Ìgbéyàwó Ọmọọba Harry àti Meghan Sparkle yóò wáyé ní Windsor

Ọmọọba Harry àti Meghan Sparkle

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan kaakiri agbaye ni yoo wo igbeyawo naa

Ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan kaakiri agbaye ni yoo wo igbeyawo laarin ọmọọba ilẹ Gẹẹsi, Harry ati omidan meghan Sparkle ni ilu Windsor.

Ọkẹ aimoye awọn eeyan lo da orun mọju lawọn opopona ilu Windsor lọna ati lee duro si ọgangan ibi ti iran yoo ti dun un wo lasiko ti igbeyawo naa baa n waye lọjọ abamẹta.

Awọn kẹkẹ ẹṣin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọsan gangan ni igbeyawo naa yoo waye ni ileejọsin St George's Chapel

Ọsan gangan ni igbeyawo naa yoo waye ni ileejọsin St George's Chapel to wa ni Windsor ki wọn to gunle irinajo ẹyẹ lori kẹkẹ ẹ'sin kaakiri ilu naa ni nkan bii aago kan ssan.

Ọmọọba Charles to jẹ baba ọkọ iyawo, Harry ni yoo tẹwọ gba iyawo lọ siwaju awọn alufaa lẹyin ti baba iyawo, arakunrin Thomas Markle ko lee farahan nibi igbeyawo naa nitori ailera rẹ.

Merghan ati iya rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọmọọba Harry àti omidan Sparkle yóò ṣe ìgbéyàwó

Ni oojọ, igbeyawo ku ọla, Ọmọọba Harry sọ f'awọn ero to peju si Windsor pe ko si ifoya fun oun lori igbeyawo naa, bakanna si ni omidan Markle pẹlu ni ṣẹṣẹ ni inu oun n dun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: