Russia-Ukraine prices: Ogun tó n wáyé ní Ukraine ti ṣàkóbá fún owó epo dísù ní Naijiria

Ọkọ epo disu

Kii ṣe iroyin mọ pe ọwọngogo epo bẹtiro n waye ni Naijiria. Ṣugbọn nkan ti ko han si ọpọ ni pe epo disu paapaa wọn pupọ, koda ju bẹtiro lọ.

Lọwọlọwọ, iye ti wọn n ta lita epo disu kan to ẹẹdẹgbẹrin Naira.

Awọn to n ṣiṣẹ ni ẹka eporọbi sọ pe iṣoro naa ko ṣẹyin bi owo eporọbi ṣe n wọn si jakejado agbaye.

Iwadii fihan pe owo epo disu ti wọn si pẹlu ida aadọsan laarin ọdun kan. Lọdun to kọja, okoolerugba ati Naira mẹrin ni wọn ta lita disu kan.

Bi owo epo ṣe n wọnyi, ni awọn alẹnulọrọ gbagbọ pe o n waye nitori ogun to n waye laarin orilẹ-ede Russia ati Ukariane, ati bi ijọba Naijiria ṣe ti yọ owo iranwọ kuro lori epo.

Alhaji Bashir Dan Malam, olori awọn alagbata epo ni Ariwa Naijiria, sọ fun BBC pe o ti pẹ ti ijọba ti yọ owo iranwọ kuro lori epo disu.

O ṣalaye pe iye kan naa kọ ni awọn alagbata n ra epo wọn lati ibudo ifọpo to wa ni Port Harcourt, Warri ati Eko.

Ni Warri, ẹgbẹta Naira ni wọn n ta lita epo disu kan, ti wọn si ti n ta laarin ẹgbẹta Naira si okoolelẹgbta.

Àkọlé fídíò, Mo bá Obasanjo ṣiṣẹ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ológun àti nínú oko, ìdí tí ẹ̀mí rẹ̀ fi gùn rèé - Olórin Amona tete bo

Ni ero ẹlomiran to jẹ alaga ẹgbẹ awọn awakọ eporọbi, Sulaiman Adamu Dan-Zaki, o sọ pe ẹbi awọn alaṣẹ ni nkan to n ṣẹlẹ.

Dan-Zaki sọ pe ijọba ko ṣe ilana iye to yẹ ki wọn o ma ta disu, iye to wu oniṣowo kọọkan lo n ta a.

O ni botilẹ jẹ pe ijọba yọ owo iranwọ, o yẹ ko ṣe ilana ati amojuto bi awọn oniṣowo epo ṣe n ta, ti kaluku wọn si n ṣe eyi to wu lai bikita fun inira to n fun araalu.

Lati ibẹrẹ oṣu Keji ni ọwọn gogo epo ti n waye ni Naijiria lẹyin ti ajọ NNPC ko epo bẹtiro kan ti ko dara wọle, eyi to ba ọpọlọpọ ọkọ̀ araalu jẹ.

Yatọ si eyi, ọpọlọpọ ile ati awọn ileeṣẹ nla ati kekere to n lo epo disu fun iṣẹ oojọ wọn lo n ke irora bi owo rẹ ṣe n wọn si.

Jakejado agbaye ni owo eporọbi ti n wọn si, nitori ogun to n waye laarin orilẹ-ede Russia ati Ukraine.

Ipa kekere kọ ni ogun naa n ni lara irianjo ori omi fun gbigbe eporọbi kaakiri agbaye.

Lọjọ Iṣẹgun, 99.38 Dọla ni wọn ta agba eporọbi ti wọn ko ti i fọ̀ lọja agbaye. Owo yii lo ti i wọn ju laarin ọdun meje.