APC Nation Convention crisis: Àwọn gómìnà 'yahooyahoo'ní APC ló ń ti Buni láti da ojú ètò ìdìbò adarí ẹgbẹ́ bolẹ̀ - Gómìnà Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Rotimi akeredolu Aketi/ facebook
Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo ti sọ pe awọn gomina 'yahoo-yahoo' laarin awọn gomina to wa lẹgbẹ oṣelu APC ni wọn n gbiyanju lati da omi ẹgbẹ oṣelu naa ru.
Gomina Rotimi Akeredolu ninu ọrọ to sọ nipa bi nnkan ṣe n ri lagbo ẹgbẹ oṣelu naa lọwọlọwọ yii ṣalaye pe gbogbo ilakaka awọn to da ẹgbẹ oṣelu naa silẹ lawọn eeyan kan to pe ni arijẹnidimadaru ti wọn wa nipo ijọba n gbiyanju bayii lati doju rẹ bolẹ.
- Dókítà ní ọdún márùn-ún ló kù fún mi láyé, mo sì ti lò lára rẹ̀ - Òṣèré Kemi Afolabi
- Wọ́n ti gbé dẹ́rẹ́bà ọ̀kọ̀ BRT tí Bamise wọ̀ lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kirikiri
- Osinbajo, Atiku àti àwọn èèkàn ìlú mìí péjú síbi ìgbàdé Olubadan tuntun
- 'Sanwo-Olu kan ẹbí wa lábùkù, ijó ló kí mọ́lẹ̀ kàkà kó bá wà kẹ́dùn ikú Bamise'
- Ejò, alángbá 43 dédé yọjú lábẹ́ aṣọ onífàyàwọ́ ejo níbodè America, wo ohun tó kó pamọ̀ sábẹ́ asọ
Gomina Akeredolu ṣalaye peifẹsẹmulẹ awọn gomina kan lẹgbẹ oselu APC pe ko bajẹ laye olugbọn ko yẹ ko bajẹ laye awọn lo mu ki ẹgbẹ naa tete ṣẹri pada si ọna iṣejọba tiwantiwa nipa titẹle ilana ti Aarẹ Muhammadu Buhari la kalẹ fun ẹgbẹ naa fun ilana iṣejọba tiwantiwa laarin ẹgbẹ oṣelu naa lee tubọ fidimulẹ sii.
Ki lo mu igbimọ iṣakoso fidihẹ, CECPC wọle si APC?
Nigba ti wahala igbimọ adari ṣuyọ ni ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin ti wọn yọ alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu naa tẹlẹ, Adams Oshiomhole lawọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu naa pe jọ lati gbe igbimọ fidihẹ kalẹ lati ṣe akoso ẹgbẹ oṣelu naa titi di igba ti wọn yoo fi ṣe akanṣe ipade idibo yan awọn aṣoju ati adari ẹgbẹ oṣelu naa.
Wọn yan Gomina Buni lati jẹ alaga igbimọ naa, amọṣa gomina Akeredolu ni igbesẹ 'iditẹgbajọba alagbada' ti gomina Buni atawọn kan ninu igbimọ naa bẹrẹ si nii gbe lẹnu ọjọ mẹta yii tako ọna ti ẹgbẹ oṣelu naa la kalẹ lati rin ti ko si dun mọ ọpọ ninu rara.
Rotimi Akeredolu ni awọn gomina kan, ninu eyi ti oun wa ni wọn yẹ aga mọ Buni atawọn to ko sodi nidi nibi ti wọn ti n gbimọran ki ipade idi apapọ ẹgbẹ oṣelu naa o maa waye.








