Olusegun Obasanjo: Tẹ bá mọ ìtumọ̀ Àlùjàńnà, ẹ kò ní fi ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré nílé ayé

Oríṣun àwòrán, Olusegun Obasanjo
Aarẹ ana, Oloye Olusegun Obasanjo ti salaye idi to se sa kuro nile keu nigba to wa ni kekere.
O ni ibẹru koboko ti wọn maa n fi na awọn ọmọ ile keu lo mu oun sa nigba naa.
Obasanjo lo salaye ọrọ yii nibi ayẹyẹ wiwe lawani fun Khalifah agba fun ijọ Tijaniyya tilẹ Yoruba, Edo pẹlu Delta, Salis Adenekan.
- Ẹ̀yin sàwáwù mi, ẹ fi àkóso òṣèlú sílẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ - Obasanjo
- Iná jó oko Obasanjo to wà ní ìpínlẹ Benue, Ẹbọra Òwu bínú, Ortom ni kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíá
- Naijiria nílò àwọn ‘Ọlọ̀tẹ̀’ tí yóò máa gbéna wojú ìjọba kó lè tẹ̀síwájú - Obasanjo
- Wo àwọn òṣèré tíátà tó ti fún Kemi Afolabi lẹ́bùn àtàwọn tó ń kíi lẹ́yìn tó kéde àìsàn rẹ̀
- Àlùfáà ìjọ gbé egbògi olóró “cocaine”, ó kó sí gbaga NDLEA
- Amotekun náwọ́ gán àwọn afurasí ìgárá ọlọ́ṣà mẹ́jọ l'Osun
- Ọwọ ọlọ́pàá tẹ afurasi ajínigbé méjì tí kò fí aráàlú lẹ́mi balẹ́ ní Abeokuta
"Nigba ti mo kere, mo ti maa n sọ itan yii nigba gbogbo, ibẹru koboko ni ko jẹ ki n duro kọ keu bo se yẹ.
Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Najiria to gba oye Ọmọwe ninu ẹkọ nipa ẹsin Kristiẹni wa fikun pe yatọ si boun se maa n sa nile keu, oun si le ranti ọpọ orin tawọn maa n kọ nibẹ.
Obasanjọ ẹni to ti da ileẹkọ bibeli ọjọ isinmi silẹ fawọn ọmọlẹyin Kristi, tun rọ ipejọpọ naa pe ki wọn sisẹ kara lati wọ Aljanna.
O ni ẹni to ba mọ itunmọ ibi ti wọn n pe ni Aljanna ko ni fi ọrọ ẹsin sere nile aye.

Ejò, alángbá 43 dédé yọjú lábẹ́ aṣọ onífàyàwọ́ ejo níbodè America, wo ohun tó kó pamọ̀ sábẹ́ asọ

Oríṣun àwòrán, CBD
Awọn onifayawọ a maa gbe orisirisi nkan gbọna ẹburu ki ọwọn awọn agbofinro ma ba tẹ wọn.
Amọ kini ka ti pe ti arakunrin kan to gbiyanju lati se fayawọ awọn ẹranko afayafa ejo ati alangba lọna ẹburu?
- Dókítà ní ọdún márùn-ún ló kù fún mi láyé, mo sì ti lò lára rẹ̀ - Òṣèré Kemi Afolabi
- 'Sanwo-Olu kan ẹbí wa lábùkù, ijó ló kí mọ́lẹ̀ kàkà kó bá wà kẹ́dùn ikú Bamise'
- Ìjọba ìpínlẹ Eko ti lé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ NURTW kúrò ní gáréèjì ọkọ̀
- Olubadan tuntun, Lekan Balogun yóò gbadé lòníì, wo bí ètò yóò ṣe lọ
- Lẹ́yìn tí wọ́n gba ipò alága NURTW lọ́wọ́ rẹ̀, MC Oluomo yapá kúró ní NURTW
- Chidinma Ojuwu tó ń jẹ́jọ́ ikú Usifo Ataga gbadé obìnrin tó rẹwà jùlọ lẹ́wọ̀n! Ìdí rèé?
Ki lohun to ri to fi fẹ ko awọn ẹranko wọnyi gba ẹnu ibode?
Ibeere ree to gba ẹnu awọn agbofinro nilẹ Amẹrika nigba ti ọwọ wọn tẹ onifayawọ kan to fẹ ko ejo ati alangba oniwo wọ ilẹ naa lati Mexico.
Nise lawọn osisẹ Illeesẹ asọbọde orileede Amẹrika ba awọn alangba ati ejo aimọye ninu asọ arakunrin naa nibi to gbe wọn pamọ si
Ni apa ibode ilẹ Amẹrika to wa ni San Yisdro lẹba isọda San Diego ni nkan bi ago mẹta oru ni ọwọ tẹ arakunrin naa.
A gbọ pe ọkọ 'Pick up' akẹru kan lo n wa lasiko ti wọn mu pe ko duro fun ayẹwo.
Awọn agbofinro lawọn ri alangba oniwo mẹtalelogoji ati ejo mẹsan an to fi sinu apo pilasitiki ti wọn gbe pamọ sinu jakẹti ati apo sokoto rẹ.
Tani afurasi naa?
Afurasi naa ti wọn lo jẹ ẹni ọgbọn ọdun ọmọ orileede Amẹrika ni wọn fẹsun kan pe o n se fayawọ awọn ẹrankọ inu igbo lọna aitọ.
Awọn asọbode sọ pe diẹ ninu awọn ẹranko wọn yi wa ninu ewu piparẹ ti wọn si ti wa fi wọn si iyasọtọ kuro nibi tawọn ẹranko mii wa.
Arakunrin Sidney Aki to jẹ ọga awọn asọbode ni agbegbe San Diego California sọ pe:
''Gbogbo ọna lawọn onifayawọ maa n wa lati fi ta ọja wọn tabi ninu isẹlẹ yi awọn ẹranko afayawọ ti wọn ji gbe kọja lẹnu ibode''
''Lọtẹ yi onifayawọ yi fẹ lo ọna alumọkọrọyi lati gbe awọn ẹranko wọnyi wọ ilẹ Amẹrika lati Mexico lalai bikita alaafia tabi ilera awọn ẹranko wọn yi.''


















