NURTW suspends MC Oluomo: Ìjọba Eko yóò fa àkóso gáréèjì ọkọ̀ èrò lé ìgbìmọ̀ kan lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, others
Ijọba ipinlẹ eko ti le awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ ero kuro ni awọn ibudokọ jakejado ipinlẹ naa.
Igbesẹ yii waye lẹyin ti awọn adari apapọ ni olu ile ẹgbẹ NURTW ni Naijiria, kede pe awọn ti da alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Musiliu Akinsanya, ti awọn eeyan mọ si MC Oluomo duro.
Ninu ikede to fi sita ni alẹ Ọjọbọ lori ayelujara Twitter, ijọba ipinlẹ Eko sọ pe oun n foju ba awọn iṣẹlẹ to n waye lẹnu ọjọ mẹta yii ninu ẹgbẹ NURTW, paapaa awọn ẹsun oriṣiriṣi ti wọn fi n kan ara wọn.
Kọmisanna fun eto iroyin ati ibanisọrọ, Gbenga Omotoso, sọ pe ojuṣe ijọba ni lati pese abo fun ẹmi ati dukia awọn olugbe ipinlẹ Eko, ati awọn alejo.
"Nitori naa lo se di dandan pe ka tete gbe igbesẹ pajawiri lati pa ina wahala to n rugbo bọ nitori ija awọn adari ẹgbẹ awakọ ero, ka si daabo bo araalu lọwọ ija igboro to ṣee ṣe ko waye.
Ọgbẹni Omotoso sọ pe ni ibamu pẹlu nkan to wa ninu ofin, ijọba ti da gbogbo iṣẹ NURTW duro ni gbogbo ibudokọ ati garaji to wa nipinlẹ Eko.
O ni ijọba yoo ṣe igbekalẹ igbimọ kan ti yoo gba iṣakoso awọn garaji ọkọ ni kiakia.
"Lara awọn ti yoo wa ninu igbimọ naa ni awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ NURTW.
Musiliu Akinsanya kede igbesẹ tuntun lẹyin ti awọn adari NURTW gba ipo lọwọ rẹ

Oríṣun àwòrán, others
Ṣaaju ikede ijọba Eko, ni alaga ti wọn gba ipo lọwọ rẹ, MC Oluomo kede pe oun ati ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Eko ti yapa kuro ni apapọ ẹgbẹ naa.
O ni igbesẹ oun atawọn ọmọlẹyin oun kaakiri idikọ to le ni igba nipinlẹ Eko naa waye lati lee gba alaafia laaye laarin oun, awọn ọmọ ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko ati awọn alaṣẹ ẹgbẹawakọ ero naa nilu Abuja.
To si ke si gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lati kuku ṣiṣẹ lori abala ikarun un iwe ijọba 'White paper' to jade lọdun 2004 pe ijọba ipinlẹ naa le gba iṣakoso awọn garaaji ati idikọ gbogbo.
Bakan naa lo ni ki ijọba fi ajọ iṣakoso idikọ, Park Management Committee lelẹ lati maa tukọ awọn idikọ gbogbo ni ipinlẹ naa.
Ẹsun wo ni awọn adari NURTW fi kan MC Oluomo?

Oríṣun àwòrán, others
Ninu ikede idaduro naa, wọn ni igbesẹ ọhun waye nitori bi MC Oluomo sẹ n tapa si ofin awọn adari, to n hu iwa tani yoo mu mi, to si tun n kọ ẹyin awọn ọmọ abẹ rẹ nipinlẹ Eko si awọn alaṣẹ loke.
Eyi n waye lasiko ti idarudapọ n waye laarin ẹgbẹ awakọ NURTW ati TOOAN to jẹ ẹgbẹ awọn to n wa kẹkẹ Maruwa nipinlẹ Eko.
Ninu lẹta ti wọn fi da MC Oluomo duro, eyi ti akọwe apapọ ẹgbẹ NURTW lorilẹ-ede Naijiria, Alhaji Kabiru Ado Yau fọwọ si tun fi ẹsun kan MC Oluọmọ pe kaka ko tẹle ofin ẹgbẹ lẹyin ipade ti wọn ba oun atawọn ọmọ igbimọ NURTW nipinlẹ Eko se lọjọ kẹsan an, oṣu Keji ọdun 2022, niṣe ni Oluọmọ "bẹrẹ si ni ko awọn tọọgi rẹ lọ dun mọhuru mọ alaga tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan fawọn oni kẹkẹ Marwa naa."
















