Court ban on Oyo park Managers: Mukaila Auxilliary ní Àìṣàtìpó rí ló ń da 'Ejiogbe' láàmú, tó fi ń ta ko ìṣèjọba òun

Ibudoko ero kan ni ipinlẹ Ọyọ

Lọjọru ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ paṣẹ pe ki wọgile iṣẹ awọn alakoso ibudokọ nipinlẹ Ọyọ, PMS ti gomina Ṣeyi Makinde fi lọlẹ.

Gomina Makinde gbe iks naa kalẹ ni ọdun 2020 lẹyin to gbẹsẹ le ẹgbẹ awakọ ero, NURTW nipinlẹ Ọyọ

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, alaga igbimọ amuṣẹya lori gbigbowo ode lawọn idikọ gbogbo ni ipinlẹ Ọyọ, PMS, Alhaji Mukaila. ti ọpọ mọ si Auxilliary ti sọrọsoke.

Ọ ṣalaye pe eremọde lasan ni idajọ naa.

Ati pe aidoju kọ ina ti oun atawọn ọmọlẹyin oun ti dojukọ lẹnu iṣẹ ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero, Alhaji Abideen Olajide ti ọpọ mọ si Ejiogbe ko tii doju kọọ rara.

Alhaji Mukaila ṣalaye pe ijọba to wa lode ti gbe gbogbo igbesẹ to yẹ lati pẹtu si aawọ laarin ẹgbẹ awọn ọlọkọ ero ṣugbọn ti oloye Ejiogbe faake kọri.

O ni gbogbo aye lo mọ pe ijọba to ba wa lode lo n sọ ẹni ti wọn ba fẹ ko dari ẹgbẹ ọlọkọ ero.

O ni oun loun n ṣiṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba ni ipinlẹ Ọyọ nitori naa, 'asiko oun lo de yii'

Àkọlé fídíò, Oladele Ogbeyemi Albert: Irin tí mò ń lò máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀mí kí ń tó gbẹ́ wọn sóh

Auxilliary ni ẹnikẹni ninu awọn igun to n tako iṣejọba oun ni ẹgbẹ ọlọkọ ero lee darapọ mọ oun lati lee wa bi jijẹ mimu wọn yoo ṣe maa jade "ṣugbọn ko si idi fun ipinya nitori karinkapọ yiyẹ nii yẹ ni."

Ninu idajọ rẹ lori ẹjọ rẹ, Onidajọ M. A. Adegbola ṣalaye pe owo ti ko tọna ni awọn alakoso ti gomina Ṣeyi Makinde yan si ipo n gba lọwọ awọn awakọ.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe ijọba ibilẹ nikan lo lẹtọ lati yan iru awọn alakoso bẹẹ, ni ibamu pẹlu ofin orilẹ-ede yii.