DG WTO: Wo àwọn ohun méje tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ngozi Okonjo-Iwealla àti ọkọ rẹ̀ Ikemba

Oríṣun àwòrán, Uzodinma Iwealla
Awọn eeyan ilu Ogwashi-Ukwu ni ipinlẹ Delta titi de ipinlẹ Abia atawọn mọlẹbi Ngzi Okonjo Iwealla gba ilu ati ijo nigba ti iroyin ipo tuntun gẹgẹ bi adari agba ajọ karakata lagbaye, WTO ti Ngozi ṣẹṣẹ wọle si jade sigboro.
Ni bayii, oniruuru awọn eeyan lo ti n yọju si ile ọkọ rẹ naa lati ba wọn dawọ idunnu.
O ya ẹ jẹ ki a gbe koko meje taye ko mọ nipa ọkọ Ọmọwe Ngozi Okonjo-Iwealla, Arakunrin Ikemba Iwealla yẹ wo:
Ta ni Olowo ori Ngozi Okonjo- Iwealla?
Ọmọwe Ikemba Iwealla jẹ ọmọ bibi ilu Umuahia ni ipinlẹ Abia.
Ikemba Iwealla lọ sileewe alakọbẹrẹ titi de girama rẹ ni Naijiria.
Dokita iṣegun to kọṣẹ iṣegun gboye ni fasiti Ibadan ki o to lọ sinruulu ni ileewosan alabọde to wa nilu Igbaja ni ipinlẹ Kwara ni Ikemba.
O kẹkọgboye nipa iṣegun iṣẹ abẹ alapapọ ati alakanṣe fun iṣan ara lawọn ileẹkọṣẹ iṣegun ni Manchester Royal Infirmary, Manchester atawọn ileewosan miran ni ilẹ Gẹẹsi.
Ẹlẹyinju aanu ni Dokita Ikemba, oun si ni alaga ajọ ẹlẹyinju aanu IKE Foundation fun Aisan Autism (IFA) nibi ti wọn ti n ran awọn eeyan to laisan Autism lọwọ.
Igbeyawo Dokita Ikemba Iweala ati Ọmọwe Ngozi Okonjo-Iwealla mu eso ọmọ mẹrin jade; ọmọbinrin kan, Oyinye Iwealla atawọn ọmọkunrin mẹta Uzodinma, Okechukwu ati Uchechi Iwealla.

Oríṣun àwòrán, other
Awọn ohun to yẹ ki ẹ mọ nipa Ngozi funrarẹ re e.
Ọmọ ilu Ogwashi-Ukwu ni ipinlẹ Delta.
Baba Ngozi, Ọjọgbọn Benjamin Kachukwu Okonjo ni oriade ilu Ogwuashi-Ukwu titi di ọjọ iku rẹ.
- Níléèwé girama GSS Kagara, àwọn agbébọn pa akẹ́kọ̀ọ́, jí ọ̀pọ̀ akẹ̀kọ̀ọ́ míràn àti olùkọ́ gbé ní Niger
- Ọmọ Nàìjíríà Invictus Obinwanne Okeke rẹ́wọ̀n ọdún mẹwàá he l'Amerika lórí ẹ̀sùn jìbìtì $11m
- Wo ohun 10 tó yẹ́ kó mọ̀ nípà Ọ̀gà EFCC, Abdulrasheed Bawa tí ààrẹ̀ Buhari yàn
- Wo bí wọ́n ṣe sàmì Ọjọ́rùú eérú tọdún 2021 ni àwon ibìkan

Oríṣun àwòrán, @AJEnglish
Wọ́n ti kéde Ngozi Okonjo Iweala gẹ́gẹ́ bíi alákóso WTO
Wọn ti fi ountẹ lu minisita eto iṣuna Naijiria tẹlẹ, Ngozi Okonjo-Iweala gẹgẹ bii adari ajọ olokoowo agbaye, WTO.
Ni bayii, Okonjo-Iweala ti di obinrin akọkọ, ati ọmọ bibi ilẹ adulawọ akọkọ ti yoo di ipo naa mu.
Saa rẹ gẹgẹ bii adari ajọ ọhun yoo bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kẹta, ọdun 2020, o si tun lẹtọ lati du ipo naa fun saa keji lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025.
- Wo ìdí tí orílẹ̀-èdè America ṣe tako ìyànsípò Okonjo-Iweala gẹ́gẹ́ bi olórí ajọ WTO
- Ọwọ́jà coronavirus yóò ṣì wà pẹ̀lú àgbáyé fún ìgbà pípẹ́- Ngozi Okonjo-Iweala
- Àwọn obìnrin mánigbàgbé sáà ìjọba tiwantiwa yìí
- Ìjọba Nàìjíríà tó yé kó pèsè aàbò ló kùnà lẹ́nú ojúṣe wọn- Mr Macaroni lẹ́yìn tó ti àtìmọ́lé dé
Alaga ajọ naa, David Walker, sọ fun awọn akọroyin pe iyansipo Okonjo-Iweala jẹ ohun manigbagbe ninu itan ajọ ọhun.
O ni "Lorukọ igbimọ gbogbogbo ajọ WTO, mo ki Ọmọwe Okonjo-Iweala ku oriire lori iyansipo rẹ, mo si kii kaabọ si aarin igbimọ yii."
Nigba to n sọrọ, adari tuntun naa sọ pe inu oun dun ati pe ohun iyi lo jẹ fun oun lati bẹrẹ si tukọ ajọ naa.
Lẹyin naa lo sọ pe oun yoo maa fojusọna lati ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn awọn ọmọ ẹgbẹ ajọ naa.
Kio lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Oni loni n jẹ ẹni a bẹ lọwẹ ni ọrọ Ngozi Okonjo- Iweala ati ipo alaṣẹ ati oludari ajọ WTO.
Ngozi Okonjo- Iweala ni yoo jẹ obinrin akọkọ ti wọn yoo yan sipo naa.
Oun ni yoo tun jẹ alawọ dudu akọkọ ti wọn yoo yan sipo naa.
- Ọbalayé tó kéré jùlọ nílẹ̀ Yorùbá, Oloyede Akinghare gbadé
- Iléẹjọ́ ti dájọ́ yíyẹgi fún Sodienye tó pa òṣìṣẹ́ Jumia kan
- Kílódé tí àwọn èèyàn ṣe ń gbé òkú pamọ̀ sílé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìlú yìí?
- Ìrọ́ ní ò, a o fí ìgbà kankan fí Olupelumi Fagboyegun, Ìbátan Akeredolu sí ẹ̀wọ̀n- Iléẹ́jọ́ ìpínlẹ̀ Ondo
- Àyè wà fún àwọn Fulani tí kíì ṣe ọ̀daràn láti wá fi ilú Iwo ṣebùgbé - Oluwo
Awọn igbimọ alaṣẹ ni yoo fẹnuko lori eyi nibi ipade naa ki wọn to kede pe ko maa bẹrẹ iṣẹ.
Ajo World Trade Organisation yii ni aarẹ ana America, Donald Trump ko ti kọkọ ṣatiléyin fun Ngozi Okonjo-Iweala.
Ipo tuntun yii ni o ni agbara pupọ lori eto okowo ati ọrọ aje gbogbo agbaye.
Yoo Myung-hee arabinrin lati ilẹ Souith Korea ti wọn jọ n dupo naa tẹlẹ lo yowo laipẹ kuro nibẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ọpọ awọn alatilẹyin lo ti n sọrọ nipa Ngozi Okonjo Iweala pe o ku oriire silẹ .
- Wo ǹkan márùn ún tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò fẹ́ ní 'Valentine' 2021
- Wo ohun tí Seyi Makinde, Akeredolu fẹ́ ṣe fún àwọn tí wàhálà ọjà Sasa kàn
- Ebola tún dé sílẹ̀ Adúláwọ̀, kí ní ṣíṣe?
- Ìjọba Nàìjíríà tó yé kó pèsè aàbò ló kùnà lẹ́nú ojúṣe wọn- Mr Macaroni lẹ́yìn tó ti àtìmọ́lé dé
- Ìjà tó wáyé ní Sasa ní Ibadan kìí ṣe ti ẹlẹ́yàmẹ̀yà- Agbẹnusọ ọlọ́pàá
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3















