Invictus Obi: Ọmọ Nàìjíríà rẹ̀wọ̀n he l'Amerika lórí ẹ̀sùn jìbìtì $11m

Oríṣun àwòrán, @Invictus
Ọmọ Nàìjíríà Invictus Obi rẹ́wọ̀n ọdún mẹwàá he l'Amerika lórí ẹ̀sùn jìbìtì $11m
Ile ẹjọ kan nipinlẹ Virginia lorilẹ-ede Amẹrika ti dajọ ẹwọn ọdun mẹwaa fun ọmọ Naijiria kan, Obinwanne Okeke ti ọpọ mọ si Invictus Obi.
Ẹsun ìgbimọ pọ lati lu awọn eeyan ni jibiti ori ayelujara ni won kan Obi.
Adajọ Rebecca Beach Smith lo ṣe idajọ ọhún lẹyin to ṣọ pe Obi jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an pe o lu awọn kan ni jibiti owo to to miliọnu mọkanla owo dọla.
Agbẹjọro alatako, Raj Parekh fidi rẹ mulẹ pe Obi ẹni ọdun mẹtalelọgbọn lo ileeṣẹ kan ti oruko rẹ n jẹ Invictus Group to wa lorileede Naijiria lu ọpọ eeyan ni jibiti ori ayelujara.
Ile ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe laarin ọdun 2015 sí ọdun 2019 ni iṣẹlẹ naa waye.
Ile ẹjọ ṣalaye pe Obi at'awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ wa awọn iwe ẹri ọpọ eeyan ti won lu ni jibiti ri to fi mọ awọn ọmọ ilẹ Amẹrika kan to wa lẹkun ila oorun Virginia.
Ile ẹjọ ni Obi tun kopa ninu awọn ẹsun jibiti miran bii ṣiṣi oju opo ayelujara ayederu lati lu awọn eeyan ni jibiti.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa FBI sọ pe idajọ yii fihan pe ko si ibi ti ọwọja ileeṣẹ ọlọpaa naa ko de kaakiri agbaye.














