Barcelona vs PSG: Messi fi àbàrá kékeré gba ńlá lọ́wọ́ Mbappe ni Nou Camp

Barca PSG

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igba laa ni, ẹnikan o lo ile aye gbo.

Ohun lo difa fun ọdọmọde agbabọọlu PSG, Kylian Mbappe to rọ agbaọjẹ agbabọọlu Barcelona, Lionel Messi loye.

Goolu mẹta ọtọtọ ni Mbappe gba sawọn Barcelona nigba ti PSG pokọ iya fun Barcelona nile wọn ni ipele ẹlẹni-mẹrindinlogun idije UEFA Champions League lalẹ ọjọ Iṣẹgun.

Ṣe ẹ mọ pe akọda oro ko da bi adagbẹyin.

Messi lo kọkọ gba pẹnariti wọle PSG lai mọ pe o kọ lẹta si iya ni.

Ṣugbọn goolu mẹrin ni Mbappe ati Moise Kean fi da pada lẹyin ti wọn lu Barca mọlẹ bi aṣọ ofi pẹlu ami ayo mẹrin sí ẹyọkan.

Àkọlé fídíò, Lori iro: Ká ni àwọn Òbí mi gbà fún mí, èmi àti Sunny Ade á jọ máa 'Compete- Baba Lórí ir

Iti ọgẹdẹ ti ko to ohun ti a n yọ ada si ni PSG fi ọrọ Barcelona ṣe ni Nou Camp tori elege ara PSG, Neymar gan an ko lanfaani lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhún lẹyin to ti fi ẹsẹ ṣeṣe tẹlẹ.

O ṣeeṣe ki Neymar kopa ninu ipele keji ifẹsẹwọnṣẹ ọhun ti yoo waye logunjo, oṣu kẹta ọdun yìí niluu Paris.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Bolanle Adekanmi kọ́ wa nípa oríṣíi Àròkọ Yorùbá tó wà