Fulani herdsmen attack today: Àwọn Fulani láṣẹ láti gbé níbikíbi tó bá wù wọ́n ní Naijiria - Oluwo

Oluwo

Oríṣun àwòrán, oluwoofiwoland

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ pe ko bojumu bi awọn kan ṣe ni ki gbogbo awọn Hausa ati Fulani fi ilẹ Yoruba silẹ.

O ni nitori ọmọ Naijiria ni wọn, wọn si lẹtọọ lati gbe ni ibikibi to ba wu wọn ni Naijiria.

Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin lati ọwọ alukoro rẹ, Ali Ibrahim, Oluwo ni awọn Fulani ti kii ba n ṣe ọdaran le wa fi ilu Iwo ṣebugbe.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ilu Iwo ni awọn Fulani to ni iwa rere pọ si ju ni gbogbo ilẹ Yoruba.

O ni oun ti ṣeleri fun awọn agbẹ ilu Iwo pe ko ni si wahala kankan larin wọn ati awọn Fulani.

O tẹsiwaju pe ibaṣepọ oun atawọn Fulani naa dan mọran to bẹẹ ti oun maa n ṣabẹwo si wọn lorekore ti olori wọn si maa n jabọ bi iṣẹ wọn ṣe n lọ fun oun.

Oluwo

Oríṣun àwòrán, @oluwoofiwoland

Ọba alaye naa ṣalaye pe "igbagbọ temi ni pe ọmọ buruku ko ṣe le f'ẹkun pa jẹ, fun idi eyii, o yẹ ka fi oju ṣunukun wo ọrọ naa nitori awọn Fulani ti kii ṣe ọdaran."

"O yẹ ki ijọba fi oju awọn ọdaran Fulani lede, ki wọn si foju wina ofin, ṣugbọn ni temi gẹgẹ bii alaṣẹ lori ilu Iwo, mi o le maa ba awọn Fulani to wa ni ilu mi ja nitori ilu yii ni wọn bi awọn babanla wọn si."

Kabiesi naa tẹsiwaju pe alaafia ni awọn olugbe ilu Iwo ati awọn Fulani fi n gbe ati pe oun ti bẹrẹ igbesẹ lati jẹ ki awọn ọmọ awọn Fulani ọhun bẹrẹ si n lọ ile iwe ki ọjọ ọla awọn naa le dara.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Bolanle Adekanmi kọ́ wa nípa oríṣíi Àròkọ Yorùbá tó wà

Atẹjade naa pari pẹlu pe ti awọn eeyan kan ba da ija ẹlẹyamẹya iru eyii to waye laarin awọn Hutu ati Tutsi ni Rwanda silẹ ni Naijiria, ọwọ ijọba gan ko ni kaa.

Lẹyin naa lo ni gbogbo ọmọ Naijiria ni aṣẹ lati fi ibikibi to ba wu wọn ṣebugbe.

Àkọlé fídíò, Sasa crisis in Ibadan: Ìbànújẹ́ ńlá ni ìṣẹ̀lẹ̀ Sasa jẹ́ fún mi - Makinde