Abdulrasheed Bawa Biography: Wo ohun 10 tó yẹ́ kó mọ̀ nípà Ọ̀gà EFCC, Abdulrasheed Bawa tí ààrẹ̀ Buhari yàn

Aarẹ Buhari ari alaga ajọ EFCC tuntun, Bawa

Oríṣun àwòrán, Presidency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si ni fi ero wọn han lori orukọ Abdulrasheed Bawa ti aaarẹ Buhari yan gẹgẹ bi adari ileeṣẹ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria.

Ni Ọjọ Iṣẹgun ni Ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria kọwe si ile igbimọ aṣofin lati buwọlu Abdulrasheed Bawa gẹgẹ bi alaga Ajọ EFCC tuntun.

Aarẹ Buhari ni ẹni ogoji ọdun ni arakunrin Bawa, ti o si ti ṣiṣẹ takuntakun gẹgẹ bi ọtẹlẹmuyẹ fun ajọ EFCC.

Àkọlé fídíò, Ọkọ mi bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ lágo kan kó tó wọ bàálù tó já, àmọ háà! - Ìyàwó Olasunkanmi Olawunmi

Wo ohun mẹwaa tó yẹ́ kó mọ̀ nípà Ọ̀gà EFCC, Abdulrasheed Bawa tí ààrẹ̀ Buhari yàn

  • Ẹni ogoji ọdun ni Abdulrasheed Bawa, ti yoo si jẹ ẹni to kere ju ti yoo dipo naa mu
  • Ọmọ bibi ilu Jega, ni ipinlẹ Kebbi ni o ti ṣẹ wa.
  • Bawa kẹkọ imọ nipa ṣiṣẹ iwadi iwa ajẹbanu to fimọ awọn ẹsun to jẹ mọ lilu owo ilu ni ponpo, lilu banki ni ponpo, lilu ọrọ aje ni ponpo ati 419
Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Bolanle Adekanmi kọ́ wa nípa oríṣíi Àròkọ Yorùbá tó wà
  • Bawa ti lọ ka iwe ni oke okun to fi mọ kaakiri awọn orilẹede lagbaye
  • O pẹlu awọn akẹkọọ akọkọ ti wọn gba si ileeṣẹ Ajọ EFCC na ni ọdun 2005
  • Bawa kawe gba oye B.Sc ni Economics pẹlu ẹkọ imọ oye ni 'International Affairs and Diplomacy'
  • Ọga agba EFCC naa yoo ma a gba iṣẹ lọwọ Mohammed Umar to di ipo mu lẹyin ti wọn kowe lo gbe ile rẹ fun Ibrahim Magu lori iwa ajẹbanu ni ọdun 2020
Àkọlé fídíò, Shasha Crisis in Ibadan: Gbọ́ ohun tó ṣokùnfà ìjà láàrin Aláboyún, soo bàtà àti Hausa alá
  • Bawa ni adari ileeṣẹ Ajọ EFCC naa ni ipinlẹ Eko, ki aarẹ Buhari to fi orukọ rẹ sọwọ fun ipo alaga ajọ naa
  • Bakan naa ni awọn iroyin ti a ko le e fi idi rẹ mulẹ sọ wi pe wọn ti fi ẹsun iwa ibajẹ ati iwa ajẹbanu kan Bawa nigba ti o wa ni ipo adari ajọ naa ni Port-Harcourt
  • Iroyin naa ni Bawa gba awọn ọkọ nla to gbe epo bẹntirl to gba lọwọ awọn to fi panpẹ ọba mu, to si taa fun awọn eniyan ni iye owo to kere si owo ti wọn n ta epo bẹntirol naa
Àkọlé fídíò, Lori iro: Ká ni àwọn Òbí mi gbà fún mí, èmi àti Sunny Ade á jọ máa 'Compete- Baba Lórí ir

Awọn akẹgbẹ rẹ labẹ rẹ pẹlu agbẹjọro Olaniyi Adekanla lo fi ẹsun naa kan an nigba ti wọn yan an gẹgẹ bi adari ileeṣẹ EFCC, ẹka ti ipinlẹ Eko

Titi di asiko yii, Bawa ni agbẹjọro ijọba to fi ẹsun iwa ibajẹ kan minisita fun ọrọ epo bẹntirol ni Naijiria, Diezani Alison-Madueke.

Ki lo kọkọ ṣẹlẹ?

Abdulrasheed Bawa ní kí ẹ fi jẹ alága EFCC - Buhari sí Ilé Aṣòfin Àgba

Ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria ti kọwe si ile igbimọ aṣofin lati buwọlu Abdulrasheed Bawa gẹgẹ bi alaga Ajọ EFCC tuntun.

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Buhari

Ileeṣẹ aarẹ fi eyi lede ni oju opo Twitter wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Wọn ni aarẹ Buhari lo fi lẹta ranṣẹ si aarẹ ile igbimọ aṣofin, Ahmad Ibrahim Lawan lati buwọlu arakunrin naa gẹgẹ bi aṣẹ ti oun ni labẹ ofin to de yiyan alaga ajọ EFCC.

Aarẹ Buhari ni ẹni ogoji ọdun ni arakunrin Bawa, ti o si ti ṣiṣẹ takuntakun gẹgẹ bi ọtẹlẹmuyẹ fun ajọ EFCC.

Ijọba ni o ni imọ nipa ṣiṣẹ iwadi iwa ajẹbanu to fimọ awọn ẹsun to jẹ mọ lilu owo ilu ni ponpo ati 419.

Bakan naa ni ijọba ni arakunrin Bawa ti kẹkọ gboye nipa iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, o si wa lara awọn to kọkọ kẹkọ wọle si iṣẹ ajọ EFCC ni ọdun 2005.

Bawa kawe gba oye B.Sc ni Economics pẹlu ẹkọ imọ oye ni 'International Affairs and Diplomacy.'