Nudity in public: Ọkùnrin kan dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tó bọ́ sí ìgboro ní ìhòhò ọmọlúàbí

Oríṣun àwòrán, Metrolondres.migrau
Okunrin kan ti dero ile ẹjọ lẹyin ti wọn fẹsun kan pe o jade saarin ilu ni ihoho ọmọluabi.
Fidio kan ṣafihan ọkunrin naa to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn nibi to ti n sare laarin igboro Notting Hill, to wa ni iha Iwọ oorun London.
Ṣaaju ni awọn eeyan adugbo ti kọkọ pe ileeṣẹ ọlọpaa lẹyin ti wọn ri odidi gende ọhun nihoho, ni kete to foju ganni ọlọpaa tan lo ba ẹsẹ rẹ sọrọ.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, Pedro Lula, sọ fun awọn akọroyin pe, idi iṣẹ ni oun wa ti oun fi ri ọkunrin naa ti awọn ọlọpaa mẹta n le laarin titi, ti oun si fi ẹrọ ibaraẹnisọrọ oun ka iṣẹlẹ naa silẹ.
Fidio ọhun ṣafihan bi ọkunrin ọhun ṣe n salọ, ti ọlọpaa meji n le, ki ọlọpaa kẹta to darapọ mọ wọn.
Lẹyin o rẹyin, awọn ọlọpaa le ọkunrin naa ba, ti wọn si fi orukọ rẹ lede gẹgẹ bii Ross Springham.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Lẹyin naa ni wọn gbe lọ sile ẹjọ to wa ni Westmisnter, nibi to ti kawọ pọn rojọ niwaju adajọ, to si sọ pe oun gba pe oun jẹbi ẹsun rinrin nita gbangba ni ihoho.
Bo tilẹ jẹ pe oṣu to n bo ni wọn yoo ṣe idajọ rẹ, adajọ ti ni ko lọ sinmi latimọle fun igba diẹ titi ti wọn yoo fi ṣe idajọ rẹ.
- Wo obìrin méjì tó ń fi ìbásùn inú yìyín "Snow" ṣara rindin kí ọlọpàá tó ká wọn
- Ìdí mẹ́ẹ́rin tí sísùn ní ìhòhò lé gbà ṣe ara a rẹ l'óore
- Àwọn afẹ̀hónúhàn bọ́ra sí ìhòhò lórí pápá lòdì sí sísọ eré bọ́ọ̀lù di jẹunjẹun
- Ìjọba gbé ilé ijó oníhòhò tì pa lórí ẹ̀sùn títàpá sí ìlànà àti dẹ́kun coronavirus
- Ọkọ mi ni èmi ni mo sòkùnfa ǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Faizat lati inú oyún- Ìyá Faizat
Ọlọ́pàá Ogun ké pe ẹni tó ni Pavillion Hotel láti wá ṣàlàyé ìdí tí kámẹ́rà fi wà nínú yàrá
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni London sọ pe ootọ ni iwadii wọn fi han pe ọkunrin naa n rin laarin ilu ni ihoho.
O fi kun pe nnkan biii aago mẹjọ aarọ ni wọn gba ipe pajawiri nipa ọkunrin ọhun, nigba ti wọn de agbegbe naa, wọn ba bẹẹ lootọ ki wọn to fi ṣikun ofin mu.
















