2023 elections: Àwọn lọ́balọ́ba Ekiti ní Fayemi kójú òṣùnwọ̀n láti jẹ ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2023

Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kayode Fayemi

Ẹgbẹ lọbalọba ni ipinlẹ Ekiti ti buwọlu Gomina Kayode Fayemi fun idibo aarẹ ọdun 2023 ni orilẹede Naijiria.

Awọn ọba alaye ọhun fẹnu ko nibi ipade ti wọn ṣe ni Ado-Ekiti lọjọ kẹrinlelogun oṣu keji pe Fayemi lo to gbangba sun lọyẹ lati tukọ orilẹede Najiria.

Awọn ọba alaye sọ pe awọn yoo gbe igbimọ kan dide eyi ti yoo rọ Fayemi lati dije fun ipo aarẹ ninu idibo gbogbogbo ọdun 2023 ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ọkọ mi bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ lágo kan kó tó wọ bàálù tó já, àmọ háà! - Ìyàwó Olasunkanmi Olawunmi

Awọn lọbalọba Ekiti sọrọ yii di mimọ lẹyin ti wọn gbọrọ lẹnu ẹgbẹ kan ti akori rẹ n jẹ "Our Belief Project" ti Ọgbẹni Aloba Abejide ṣe agbatẹru rẹ.

Ọgbẹni Abejide lo kọkọ rọ awọn ọba alaye naa lati ba gomina ipinlẹ Ekiti sọrọ pe ko kede erongba rẹ lati dupo aarẹ lọdun 2023 ni kiakia.

Alaga awọn igbimọ lọbalọba ipinlẹ Ekiti, Alawe ti Ilawe-Ekiti, Ọba Adebanji Ajibade Alabi Afuntade Kinni sọ pe eeyan bi Fayemi ti ori rẹ pe ti o si ni okun lo le dari Naijiria bayii pẹlu oriṣiiriṣii iṣoro to n koju orilẹede yii bayii.

''Fayemi wa lara awọn to doju ija kọ awọn ologun lati rii pe Naijiria pada si ijọba awarawa.

Àkọlé fídíò, 50 Year old Ajayi Folashade: Mo ti kọ́kọ́ dán an wò ní 80s àmọ́, ó kàn ṣáà ń wù mi náà ni

Bakan naa Fayemi tun ti gboye ni fasiti lori ogun, nitorinaa oun lo le wa ojutu si eto abo to mẹhẹ ni Naijiria to ba le di aarẹ lọdunm 2023, Alawe lo sọ bẹẹ.

Oba Afuntade Kinni fikun ọrọ rẹ pe o ti to asiko ki ọmọbibi Ekiti naa jẹ aarẹ orilẹede Naijiria lẹyin ti wọn ti ran awọn ẹya mii lọwọlọwọ lati doke.

Alawe ni Sultan ilu Sokokto Abubakar S'aad ati Gomina Nasir El-Rufai ipinlẹ Kaduna gan an ti sọ tẹlẹ pe awọn ni igbagbọ ninu Fayemi.

Oba alaye naa rọ gbogbo awọn oloṣelu nipinlẹ Ekiti lati gbaruku ti Fayemi lọdun 2023.