Faiza Autistic Girl: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mó má n so lọ́wọ́, ẹsẹ̀ àti ẹnu kó ma baa pariwo- Ìyá Faizat

Ọkọ mi ni èmi ni mo sòkùnfa ǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Faiza lati inú oyún- Ìyá Faizat

Oríṣun àwòrán, Rasheedat Olatunji

"Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn ti gbà mi ni ìmọ̀ràn láti gbé òògùn fún ọmọ mi jẹ́ kó le bá lọ sinmi."

Èyí ni ọ̀rọ̀ ìyá Faiza tó bi ọmọ tó ni ìpèníjà ọpọ̀lọ.

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú ìlé ìṣẹ́ BBC News Yorùbá lásìkò tí a ṣe àbẹ̀wò síbẹ̀ ló sọ ǹkan ti ojú rẹ̀ ti rí láti ǹkan bi ọdún mọ́kànlélógún sẹyin.

Àkọlé fídíò, Ọkọ mi bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ lágo kan kó tó wọ bàálù tó já, àmọ háà! - Ìyàwó Olasunkanmi Olawunmi
Àkọlé fídíò, 'Tí mi ò bá rí ògùn rà fún ọmọ mi, á máa gé ara rẹ̀ jẹ tí ẹ̀jẹ̀ yóò máa ṣàn'

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ arábinrin Rasheedat Olatunji ni ilé ìwòsàn tó n wo àwọn alárùn ọ̀pọlọ ni wọ́n ti fi idi rẹ̀ múlẹ̀ pé Faiza ni ìpèníjà ọ̀pọ̀lọ "Asperger's syndrome" ní àsìkò tó wà ni ọmọ ọdun mẹjọ.

Olatunji ni kéte ti ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ni wàhálà dé nítori bàbá rẹ̀ tó ti di olóògbé nisinyi da ẹbi ọ̀rọ̀ náà le òun lórí.

Gẹ́gẹ́ bi ìyá Faiza ṣe sọ, kò pé púpọ̀ ni bábá rẹ̀ náà fi ayésilẹ̀ tó lọ, ẹrù ìtójú ọmọ náà si di ti òun nìkàn soso.

" Oríṣiriṣi ìgbà ni ojú mi ti ri àwọn ǹkan ìbànujẹ lórí ọmọ yìí, ṣe ti ọjọ ti àwọn onílé dàwá síta ni tàbí ọjọ́ tí àwọn onímọ́tò jáwa sílẹ̀ láárin ọ̀nà"

Arábìnrin Olatunji tún fi kun pé, spọ̀ ìgbà ni àwọn míràn a gba òun níyànjú láti gbé òògun fun ọmọ náà jẹ kí o bá le lọ sínmi.

Ó ní wọ́n a ma sọ fún òun pé, " o má si ni ayé ti wàá ṣe, wa ma tún ọkọ fẹ́, ṣe bi wa se máa di ọmọ yìí kiri rèé.

Ọkọ mi ni èmi ni mo sòkùnfa ǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Faiza lati inú oyún- Ìyá Faizat

Oríṣun àwòrán, Rasheedat

Ìyá Faizat fi kun pé tí òun kò bá rí owó ra òògún nítori iru iṣẹ́ ti òun ṣe tí kò ní àsìkò pàtó tó le mu owó wọlé, àìrówó ràn òògun tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹrinlá Nàírà(#14,000) lóṣoosu yìí ariwo ni yóò maa pa si gbogbo ile, fún ìdí èyí ọ̀pọ̀ àwọn oníle ló ti lé òun jáde.

"Iṣẹ́ àgbàṣe ni ká ba àwọn ènìyàn fọ ilé fọ ilẹ̀ tàbi nígbà mírà kí n tẹ̀lé àwọn ẹlẹ́ràn láti lọ maa yọ ìfun ẹràn no mo fí n tọjú òun àti àwọn àbúrò rẹ̀."

Ìyá Faizat ní títí tí o fi pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún yìí, kò lé ṣe ohunkóhun fun ara rẹ̀ tó fi mọ tó bá n ṣe ǹkan oṣù. Ó ní ni ọ̀pọ̀ ìgbà tí ó bá n ṣe ǹkan ṣun lẹyin "tí mo bá ràn lọ́wọ́ láti lo ilédi, ó le fàá yọ ti yọ."

"Lásìkò tí ó bá bbẹ̀rl nígbà míràn, má ni láti di lọ́wọ́-dìí lẹ́sẹ̀ àti ẹnu kí o má bá pariwo sí ará ilé, tí mo bá ṣe èyí tán, má wá bú sẹ́kun"

Arábinrin Olatunji tún fi àsìkò yìí rọ àwọn òbí tó bá ni irú ọmọ yiì'kí wan máa ni sùúrù, kí wan si ma ma dé wọ́n mọ́lé, kí wọ́n jk kí àwọn náà má jáde.