Mide Funmi Martins: Látìgbà tí mo ti mọ ọ̀tún yàtọ̀ sí òsì, Mide ò lè sọ pé mo ti rí òun sójú - Damilare

Oríṣun àwòrán, Mide Martins
Nigba ti ọmọ gaan ti gbogbo ọrọ yi da le lori wa kẹnu bọ ọrọ, kii ṣe ọrọ ti wọn ro fun eeyan latẹnudẹnu rara. Bayii ni Damilare ṣe sọrọ gẹlẹ:
"Mo maa n wo awọn fidio ifọrọwanilẹnuwo Mide Martins ti wọn ba beere mi ti a ni ẹjẹ oun ni mi ti oun si n tọju mi, amọṣa emi gbagbọ́ ninu nkan ti wọn kọ mi wipe ti asiko nkan o ba tii to, eeyan o le mu Ọlọrun ni dandan lati ṣe e".
Eyi to jẹ tuntun to ṣẹṣẹ jade ni pe:
"Ẹni to ma purọ lo ma sọ pe ẹlẹri oun ti ku"
Ẹgbọn iya Mide-Funmi Martins ti wọn n pe ni baba Deji toun naa jẹ ẹlẹri gbogbo nkan to n ṣẹlẹ kẹnu bọ ọrọ.
Gẹgẹ bi olorin Juju, Sir Shina Peters ti ọrọ yi mọ lẹsẹ naa ṣe ṣe, arakunrin naa dupẹ lọwọ ikanni iroyin ori ayelujara to kọkọ wu ọrọ naa sita amọ ki wa lo wa nidi ọrọ yii gangan?
Ẹgbọn oloogbe Funmi Martins ni bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ lo ti n fi oriṣiriṣi aworan oloogbe atawọn mii sita lati fi sọ ohun to wu wọn, o ni ko boju mu.
Torinaa loun gan ṣe sọrọ sita lati ri i pe igbiyanju awọn to n sọ ootọ lori ọrọ yii ko gbofo.
"Ọpọlọpọ nkan lo ti ṣẹlẹ sẹyin ti mi o si kọkọ fẹ da si ṣugbọn mo gbagbọ pe fidio temi yii yoo tan imọlẹ si ohun gbogbo".
O ni lootọ ni Damilare, ọmọ ti awọn eeyan n sọ pe o wa laarin Funmi Martins ati Sir Shina Peters n gbe ni ọdọ oun.
"Ẹni ti wọn ba n ri ọmọ lọdọ rẹ naa ni wọn a sọ pe o n gbe nile rẹ".
Lati ja irọ awọn araale, baba yii ni ki wọn pe Damilare jade ninu ile lati wa foju han awọn eeyan.
Baba naa tun fi ẹsẹ inu Bibeli kan gbe ọrọ rẹ lẹyin to fihan wipe lootọ ni awọn kan kọ Damilare silẹ.
"Bibeli naa sọ pe nigba ti baba ati iya rẹ ba kọ ẹ silẹ, emi yoo tẹwọ gba ọ". Torinaa lo ṣe ni oun lee pe Damilare ni ọmọ oun, ẹni ti Ọlọrun ko fi silẹ fun iya jẹ.
Baba Deji ni ọna jin nipa itan Damilare gẹgẹ bo ṣe ri "ṣugbọn lọjọ ti wọn bi i, o dabi ẹni pe nkan fẹ wọlẹ, ti baba ko si nile amọ emi naa ni mo gbe e dani".
O ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe oun ṣi wa laye, ọmọ ọhun naa si wa lakata oun ti wọn wọn bi ile.
O ni oun gbagbọ pe ọmọ ọdun mọkandinlogun ti toju bọ ti ko si lee wa nile oun titi lae torinaa oun fọwọ si i ki gbogbo ẹni to ba fẹ ṣeranlọwọ fun Damilare ni tootọ ṣe e fun un niwọn igba ti wọn ba ti gba ọna to tọ toripe ọmọ naa ti ni apo asuwọn owo tirẹ ti awọn fi orukọ rẹ ṣi.
"Koda o ni iṣẹ akanṣe tirẹ to n da ṣe gẹgẹ bii akitiyan lati jẹ eeyan laye, to si n ṣe oriire ninu rẹ".
Latigba ti mo ti gbọn, mi o tii ri Mide Martins soju koroju
O ni "torinaa ko le sọ fun mi pe lati igba ti mo ti mọ ọwọ ọtun yatọ si osi, pe mo ti ri i pẹlu oju mi mejeeji".
"O ti to ọdun mẹfa si meje sẹyin bayii ti mo ti ri wọn gbẹyin koda ọjọ ti mo ri wọn, nibi isinku iya-iya wa".
O ni Mide tilẹ dajọ pe awọn maa rira lọjọ kan, ṣugbọn mo ṣaa dupẹ lọwọ Ọlọrun.
Damilare ni oun rọ gbogbo awọn ti wọn ba fẹ ran oun lọwọ lati ma dẹkun rẹ toripe oun naa ni awọn iṣẹ kọọkan to n ṣe lati igba toun ti darapọ mọ ere Tiata ṣiṣe atipe oun n gbiyanju lati wọ ileewe giga fasiti amọ ko si owo.
Baba ti o n gbe lọdọ rẹ to jẹ ẹni ti wọn bi iya rẹ le ni nkan ti wọn n tọrọ fun lasiko yii kii ṣe pe wọn wa owo "pampers" abi owo ounjẹ.
"A ti tọju rẹ kọja gbogbo ipele yẹn, owo ati da duro funrarẹ gẹgẹ bi ọga ileeṣẹ ni ko si ṣe agbejade iṣẹ akanṣe to n ṣe ninu eyi to le fi ran ara rẹ lọ si fasiti lati ka eyi to ku".



















